Latifat Tijani: Ìjọba Naijiria ń ṣèlérí láti mọ́ rírì mi àmọ́ láti 2016, pàbó ló ń já sí

Àkọlé fídíò, Latifat Tijani: Ìjọba Naijiria ń ṣèlérí láti mọ́ rírì mi àmọ́ láti 2016, pàbó ló ń já sí

Latifat Tijani jẹ akọni to n gbe irin fun orilẹede Naijiria ninu awọn idije fawọn agba ọjẹ elere idaraya lagbaye.

Ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Latifat ti wa, oun nikan soso si ni elere idaraya to mu ami ẹyẹ goolu wale laarin awn elere idaraya to jẹ akanda ẹda to soju orilẹede wa ninu idije ere idaraya Olympics fawọn akanda ẹda to waye ni Tokyo lọdun 2020.

Saaju ni Latifat ti kọkọ gba ami ẹyẹ fadaka fun orilẹede Naijiria lọdun 2016 ti inu awọn alasẹ ilẹ wa si dunnu si awọn igbesẹ akin ti akọni obinrin to jẹ akanda ẹda naa n gbe.

Amọ bo ti se bẹbẹ to yii, Latifat ko ri ohun rere kankan tọkasi lati safihan iyi ati ẹyẹ to n mu ba ilẹ baba rẹ.

Koda, inu ile ti Latifat n gbe ko wu oju ri rara, eyi to n mu ki ibinu awọn ọmọ Naijiria maa ru soke si ijọba pe se o yẹ ki iya maa jẹ iru eeyan bayii.

BBC Yoruba ba Latifat fọrọ jomitoro ọrọ, to si salaye pe ijọba ko tii se amusẹ gbogbo ileri ti wọn se fun oun lati ọdun 2016 titi di akoko yii bi o tilẹ jẹ pe wọn n se ileri pe awọn yoo se e.

O ni igbe aye oun lo n fi ojoojumọ buru si lojoojumọ, iwọnba ohun ti oun ri gba lọwọ gomina Amosun lọdun 2016 si ni oun fi sare se ile ti oun n gbe.

Amọ sibẹ sibẹ Latifat ni ifẹ nla ti oun ni si ere idaraya ko yinjẹ rara, ti oun si setan lati se bẹbẹ siwaju niwọn igba ti ijọba ba fun ohun lawọn ohun eelo to yẹ fun igbaradi awọn elere idaraya bii ti oun.