SARS Panel Report: Sanwoolu ṣèlérí pé gbogbo nkán tó bá wa nínú àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ Endsars ní aráàlú yóò mọ

Oríṣun àwòrán, Facebook/Babajide Sanwo-olu
Bi gbogbo araalu ṣe n foju sọna de abajade iwadii igbimọ ENDSARS ti ijọba gbe kalẹ Gomina Babajide Sanwoolu ti sọ pe awọn ko ni d'aṣọ bo esi iwadii naa.
O ni boya o gbe ijọba tabi ko gbe awọn, gẹlẹ bi igbimọ ba ti ṣe daba ni awọn yoo gbe si eti igbọ araalu.
Sanwo-olu sọ pe abajade yi yoo jẹ ki ijọba le fagbara kun igbiyanju mimu irẹpọ wa ati ki iru rẹ ma ṣe waye mọ.
Lọjọbọ ni Gomina fi ọrọ yi lede lẹyin ti awọn ọdọ ṣe iwọde iranti ọdun kan ti ikọlu waye laarin awọn oluwọde ati ọmọ ogun Naijria ni Lekki Toll Gate.
Gomina sọ pe ohun tawọn tori rẹ ṣe agbekalẹ igbimọ yi ni lati tan imọlẹ si ẹsun iwakiwa tawọn ọlọpaa SARS n hu si araalu.
''Igbimọ pari iṣẹ wọn ni ọjọ mẹta sẹyin (Ọjọ Aje) ti wọn si ni ka fun awọn lasiko lati ṣe akojọpọ abajade iwadii wọn''.
A ko mọ nkan to wa ninu abajade wọn ṣugbọn ijọba wa ko ni da'sọ bo o. Awa kii ṣe iru ijọba bẹẹ''.
Gomina tun sọrọ nipa awọn ọdọ kan ti agbofinromu lọjọ iwọde iranti ọdun kan ENDSARS.
O ni oun ti paṣẹ ki wọn tu gbogbo ẹni ti wọn mu lasiko iwọde ti wọn ṣe pẹlu ọkọ silẹ ayafi ẹnikan ti wọn ba nkan ija oloro lọwọ rẹ.
Lasiko iwọde yii, awọn agbofinro dun koko mọ awọn oluwọde kan ati akọroyin ti eleyi ṣi ṣebi ẹni ta epo si aṣọ aala iranti ti wọn gbero pe ajọdun yi yoo jẹ.
Ọkan lara awọn ọdọ to ba wọn kopa gẹgẹ bi ọmọ igbimọ yii fi to BBC leti pe lootọ lawọn ti pari iwadii ati pe abajade ko ni jade si eti igbọ araalu.
Ẹwẹ igbimọ naa ti kọkọ kede owo gba ma binu irinwo miliọnu Naira le mẹwaa fawọn kan to yọju lati sọ bi ọlọpaa SARS ṣe hu iwa aida sawọn.
Igbimọ ipinlẹ Eko yatọ si awọn ti ipinlẹ miran nitori pe o ko iwadii ọrọ SARS ati ikọlu to waye ni Lekki Toll Gate logunjọ oṣu Kẹwa ọdun 2020 papọ.
















