ENDSARS rememberance: Ó ṣe ni láàánú pé ìjọba kò kọ́ ẹ̀kọ́ kankan lára ìwọ́de ENDSARS - Bukola Saraki

Lai

Oríṣun àwòrán, @ScooperNG

Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti sọ pe ko si ẹ̀rí to daju pe lootọ ni wọn pa awọn oluwọde ni Lekki Tollgate ni ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.

Minisita fun eto iroyin ati àṣà, Lai Mohammed sọ fun awọn akọroyin nilu Abuja pe iwadii ti awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe, ati ti ajọ US Human Rights Practices jẹri pe lootọ ni ọrọ ti ileesẹ ologun sọ pe awọn ko yinbọn ni Lekki Tollgate.

O ni ipaniyan Lekki ni akọkọ iru rẹ l'agbaye, ti wọn ni ipaniyan ti waye, sugbọn ti "a ko ri ẹ̀jẹ̀ tabi oku eeyan kankan.

" Lẹyin ọdún kan, ko si ẹnikẹni to yọjú sita pe wọn pa ẹbi oun ni Lekki, laduru anfaani to wa fun wọn lati ṣe bẹ́ẹ̀."

Àkọlé fídíò, Irú omi àti oúnjẹ tí wọ́n ń fún Sunday Igboho, a ó mọ̀ọ́, à ń fura sí ohun tó ń lọ lọ́wọ́ látìmọ́lé Cotonou

Lai Mohammed sọ pe ijọba apapọ yoo sisẹ pẹlu awọn ijọba ipinlẹ, lati san owó itunu fun awọn to kagbako ifiyajẹni lọwọ ọlọpaa.

Bakan naa lo sọ pe igbimọ alasẹ Naijiria ti pàṣẹ fun awọn ipinlẹ lati fi àbọ̀ iwadii àwọn igbimọ ti wọn gbe kalẹ lori ọrọ #ENDSARS ránṣẹ, ki wọn le tete gbe awọn ọlọpaa to ba jẹbi lọ sile ẹjọ.

Yatọ si eyi, Lai tun sọ pe ijọba apapọ ti sọ fun awọn ileesẹ eto abo Naijiria pe ki wọn o ma a ṣe ayẹwo ilera ọpọlọ awọn ti wọn ba fẹ ẹ gba sisẹ, ati lẹyin ti wọn ba gba wọn tan lati le mọ boya wọn koju osunwọn lati lo ìbọn .

senetọ Bukọla Saraki

Oríṣun àwòrán, Nigeria senate

Ó ṣe ni láàánú pé ìjọba kò kọ́ ẹ̀kọ́ kankan lára ìwọ́de ENDSARS - Bukola Saraki

Aarẹ ile aṣofin agba Naijiria tẹlẹ, Bukola Saraki sọ pe ẹ̀kọ́ lo yẹ ki rogbodiyan to tẹle iwọde ENDSARS jẹ fun awọn olori Naijiria. Ninu ọrọ to kọ sori lati daro 'ipaniyan' to waye ni Lekki Tollgate, to pe ọdun kan loni, ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021, ni Saraki ti sọ bẹẹ. Saraki sọ pe o ṣe ni laanu pe ko ti i si ayipada kankan lori awọn iwa ti ko tọ ọ ti awọn oṣiṣẹ eleto aabo ń hu, eyi to fa iwọde to waye. O ni bẹẹ naa ni ijọba ko ti fi iya jẹ ẹnikẹni to lọwọ si awọn ipaniyan ati biba dukia jẹ, to waye lasiko naa.