EndSARS: Àwọn ọ̀dọ́ tẹ̀ ẹ́ pa, àmọ́ wo ìkílọ̀ Ìjọba àpapọ̀, Ọlọ̀pàá àti Gómìnà Sanwoolu

Awọ́n oluwọde ni Lekki Toll Gate

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti ki awọn ọdọ to n gbero lati ṣe iwọde ni ẹnu ibode Lekki nilọ pe ki wọn ma dan an wo.

Minisita iroyin, Lai Mohammed to ṣekilọ yii kẹnu bọ ọrọ nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ l'Ọjọbọ niluu Abuja to si ni awọn ọmọ Naijiria lẹtọ lati ṣewọde amọ iwa ipa lorukọ iwọde lawọn ko ni gba.

Mohammed ni pẹlu irori, o ṣeeṣe ki awọn janduku ja iwde ti awn kan n gberoo ko waye lọjọ Satide ọjọ kẹtala ọdun 2021 ni ibode Lekki.

Amọ ṣe ni awọn ọdọ naa labẹ akoso #EndSARS kọjalẹ ti wọn ni dandan ni awọn yoo ṣe iwọde ọhun.

Ẹwẹ, ẹgbẹ mii labẹ akoso #DefendLagos naa ti sọ ṣaaju wipe awọn naa yoo ṣe iwọde tiwọn lodi si ti awọn oni EndSARS.

Ijọba apapọ Naijiria naa ti wa kilọ fun awọn to wa labẹ akoso #OccupyLekkiprotest pe ki wọn dẹyin lẹyin nkan ti wọn fẹ ṣe.

Àkọlé fídíò, 50 Year old Ajayi Folashade: Mo ti kọ́kọ́ dán an wò ní 80s àmọ́, ó kàn ṣáà ń wù mi náà ni
Awọ́n oluwọde ni Lekki Toll Gate

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa, ijọba ipinlẹ Eko tun kilọ fun awọn ti igun #Occupy Lekkiprotest ki wọn jawọ pe awọn ko ni gba ki wọn sa sabẹ iwọde lati da ilu ru.

Ijọba Eko tun ni awọn ko ni faaye gba biba nkan ini ati dida ẹmi awọn eeyan legbodo mọ nipinlẹ naa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọrọ iwọde EndSARS gangan bẹrẹ ninu oṣu kẹwa ọdun 2020 niwaju olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko.

Lọjọ keji ọjọ yii ni iwọde naa tan de awọn ilu mii ni Naijiria bii Abuja, Benin, Abeokuta, Port Harcourt.

Ọjọ ti ọrọ bọ sori gangan to di eyi ti ẹnikẹni lagbaye ko lee gbagbe ni ogunjọ oṣu kẹwa ọdun 2020 nigba ti iṣi awọn ọmọ ogun sọja sṣina ibọn bolẹ si awọn oluwọde ni ibode Lekki ti iroyin si gbode kan pe wọn pa ọpọlọpọ eniyan.

Ohun to wa wu apa keji yii jade ni igba ti igbimọ to n gbẹjọ aṣemaṣe awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Eko paṣẹ pe ile iṣẹ to ni Lekki toll gatae lanfani lati pada gbajọba ibẹ, lawọn ọdọ ba tun yari.