Lai Mohammed on banditry: Kìí ṣe pé ìjọba ń fi ọwọ́ jẹ́jẹ́ mú àwọn jàndùkú

Lai

Oríṣun àwòrán, @thebridgenewsng

Ijọba àpapọ̀ ti ni bi oko ọrọ ṣe ń wá níbi lọhun pé ìjọba ń tẹ ẹ jẹjẹ ninu bi wọn ṣe ń koju awọn janduku ko boju mu rara o si le ṣi eeyan lọ́nà.

Minisita fún ìròyìn àti àṣà, Lai Mohammed lo fi eyi lede ni ọjọ Isegun nigba to n sọ̀rọ̀ lori eto owuro lori amohunmaworan NTA pé iwa ọ̀daràn ni janduku tí kò si ní nkankan ṣe pẹlu ẹsin.

Lai Mohammed ni ọna ti ijọba àpapọ̀ n gba gbogun ti awọn janduku apani nipasẹ lilo awọn ológun kii se lati fi iyato tó wà laarin awọn janduku atawọn agbesunmomi hàn rara.

"Mo lero pe orúkọ lasan la fi n ṣe ìyàtọ̀, ọ̀daràn ni ọ̀daràn n jẹ, iru ọwọ kan la si n gbe fi koju wọn".

Lai Mohammed ni eleyi gaan lo mu ki ọrọ táwọn eeyan ń sọ sì ijọba ká wọn lára pe wọn ń dẹ ọwọ bo ba ti kan awọn agbebon yàtọ̀ sí àwọn agbesunmomi.

"Irọ patapata gbaa ni eleyi, Iroyin ofege sì ni pẹlu ti awọn alaidaa eeyan kan n gbe kiri".

Lai ni ko tilẹ̀ mú ọgbọn wa ki àwọn ológun maa fi ọwọ ti ko le mu awọn agbebon to jẹ pe wọn ń pa Ọlọpaa àti sọja.

Àkọlé fídíò, Adepoju Abdulsalamm ẹni ọdun 18 tó n fi kẹ̀kẹ́ dára fi kiri ẹja tó fi n tà wàràwàrà

Ó fi kun un pé àti ori ilẹ̀ àti inú afẹ́fẹ́ ko ni faaye ìyàtọ̀ silẹ nínú bí àwọn ológun ṣe ń koju àwọn agbebon àtàwọn janduku. Lai Mohammed ni pẹlu igbesẹ ti awọn ń gbe lọwọlọwọ, awọn ń borí.

O ni awọn gomina naa ti kọ ẹ̀kọ́ latara ohun to n sẹlẹ latẹyin wa ti wọn si ti gba pe awọn o ni bá awọn agbesunmomi duna dura dípò bẹẹ kí wọn gbá tẹle wọn lai da wọn si.

Bákan naa lo ni bibẹgi dina lilo itakun ayélujára àti títa epo ninu kẹẹgi láwọn ìlú tó wà lágbègbè ibodè Naijiria ń so èso rere gidi gan.

Kódà ó ní to fi mọ òfin "ẹ má wa kẹkẹ" láwọn ọjà kan àti fifagile awọn ibùdókọ kan náà ń so èso rere.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN