Pandora Papers: Ìwádìí ìjìnlẹ̀ tú àṣírí ọ̀rọ̀ àwọn alágbára ní àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Asiri ti tú pe ẹbí aarẹ orilẹ-ede Kenya, Uhuru Kenyatta, ni awọn ileesẹ ikọkọ ni ilẹ̀ okeere, lati ọpọlọpọ ọdún sẹyin.
Ẹbi Kenyatta lo ti n dari orilẹ-ede naa lati igba ti wọn ti gba ominira.
Àṣírí to tu yii ko sẹyin àbọ̀ iwadii bonkẹlẹ kan, Pandora Papers - to jẹ asiri nipa akọsilẹ bi miliọnu mejila to tú nípa ọ̀rọ̀ ati okoowo idakọnkọ, ti àwọn olori orile-ede ni agbaye, awọn oloṣelu ati awọn 'billionaire' n ṣe.
- Àwọn dókítà tí fagilé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ, sùgbọ́n...
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba ẹ darapọ̀ mọ́ wa látí tako ìjọba Naijiria lórí àtìmọ́lé Nnamdi Kanu - IPOB
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀yà kan wà ní Africa, tó jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nípa sí sọ nkan ọmọkùnrin di nla ní ìlànà ìbílẹ̀?
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun wó iléẹ̀kọ́ Nazareth High School, Imeko tó wó pa ọmọ orùkan
- Òjò alágbára rọ̀ ní Ikare-Akoko, ilé àádọ́jọ bá a lọ, èèyàn kan tún kú
- Iná ìjọba gbé àwọn olújọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi, ẹ̀mí mẹ́rìn lọ si!
Agbarijọpọ àwọn akọroyin nilu Washington DC lo wa nidi iwadii naa.
O si le ni ẹgbẹ̀ta akọroyin lati orilẹ-ede mẹtadinlọgọfa to wadii awọn ọ̀rọ̀ ti awọn alagbara l'agbaye ko pamọ.
Ileesẹ iroyin BBC Panorama ati Guardian lo dari iwadii naa ni orilẹ-ede UK.
Ileesẹ ilẹ okeere mẹtala ni wọn ka mọ́ Ọgbẹni Kenyatta ati mọlẹbi rẹ mẹfa.
Àmọ́, wọn ko ti i fesi si ẹsun naa.
Awọn idokowo ẹbi Kenyatta ti asiri wọn tu ni ileesẹ kan to ni ìpín idokowo to to ọgbọn miliọnu owo Dọla.
Asiri yii tu nipasẹ akọsilẹ ni ileesẹ amofin ati awọn ileesẹ mii mẹrinla ni Panama, British Virgin Islands, ati awọn ileesẹ mii to n gba owo ori.
Owurọ kutu ọjọ Aiku si ni wọn gbe abajade iwadii naa sita nipasẹ International Consortium of Investigative Journalists (ICIJ), Finance Uncovered, Finance Uncovered, Africa Uncensored ati awọn ileesẹ iroyin mii.
Botilẹjẹ pe ko si akọsilẹ nipa iye ọ̀rọ̀ ti ẹbi Kenyatta ni, àmọ́ wọn ni okoowo ni ẹka igbokegbodo ọkọ, eto adojutofo, ile itura, iṣẹ ọgbin, ilẹ, ati ileesẹ iroyin ni Kenya.
Lọdun 2018, Ọgbẹni Kenyatta sọ fun BBC Hardtalk pe ko si asiri nipa dukia ẹbi oun ti awọn araalu ko mọ
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
- Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ikọlu wáyé láwọn ọgbà ẹwọn Nàìjíríà
- Ẹ wo àwọn adarí ìjọ ní Naijiria tó tako abẹ́rẹ́ àjẹ́sára Covid-19 àti àwọn tó faramọ
- Wo ǹkan mẹ́ta tó n jẹ́ kí abẹ́ obìnrin má a rùn...
- Ta ni Whitemoney tó gba N90 miliọnu nínú ìdíje BBNaija 2021?
Botilẹjẹ pe ko si nkan to buru ninu ki eeyan ni ileesẹ ni ìpamọ́, sugbọn wọn n lo lara awọn ileesẹ naa lati ko owo jẹ, ko owo pamọ silẹ okeere, ati fi boju ki wọn o ma ba a san owo ori.
Awọn olori orilẹ-ede miran ti wọn tun dárúkọ wọn ninu Pandora Papers ni Ọba Jordan, Abdullah II, Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi nigba kan, Tony Blair, Aarẹ orilẹ-ede Gabon, Ali Bongo Ondimba, ati Aarẹ orilẹ-ede Congo-Brazzaville, Denis Sassou-Nguesso.
- Ọwọ́ sìkún ọlọ́pàá tẹ Bolanle afurasí adigunjalè làyájọ́ òmìnira Nàìjíríà
- "Who wants to be a Milionaire'' tí pada sí orí afẹ́fẹ́! ẹyin olólùfẹ́ rẹ̀, ẹ kú oríire!
- Iná ìjọba gbé àwọn olújọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi, ẹ̀mí mẹ́rìn lọ si!
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun wó iléẹ̀kọ́ Nazareth High School, Imeko tó wó pa ọmọ orùkan
















