Ogun School Collapse: Ìjọba Ogun wó iléẹ̀kọ́ Nazareth High School, Imeko tó wó pa ọmọ orùkan

Ijoba ipinlẹ Ogun ti wo awọn kilaasi to wo pa akẹkọọ ni ileẹkọ Nazareth High School, Imeko ni ijọba ibilẹ Imeko Afon.
Ileẹkọ naa ti ko duro daadaa mọ ni lara rẹ wo lu awọn akẹkọọ ni ileewe naa.
Akẹkọọ kan ku, ti meji si farapa ko to di pe ijọba ipinlẹ Ogun gbe igbesẹ lati wo ileẹkọ naa palẹ.
Iya to n tọju ọmọ to gbẹmi mi ninu iṣẹlẹ ijamba ileẹkọ to wo naa ni ọmọ oru kan, ti ko ni baba tabi iya ni ọmọ naa.
Iya agba naa ni ọmọ ọmu ni Muinat wa ti iya rẹ ti jade ni aye.
Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun paṣẹ ki wọn ṣe atunkọ awọn ileẹkọ naa ati awọn miran ni ipinlẹ naa ti ko ba bojumu mọ ki iru ijamba to waye naa ma tun waye mọ.
Awọn eekan ni ijọba ipinlẹ Ogun lo pejọ si ibẹ lati ri pe awọn oṣiṣẹ to n wo ileẹkọ naa ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ.
''Iṣẹ ti ijọba ṣe lati wo ileẹkọ naa palẹ ni lati doola ẹmi awọn akẹkọọ ati awọn ara agbegbe naa''
- Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu
- Òjò alágbára rọ̀ ní Ikare-Akoko, ilé àádọ́jọ bá a lọ, èèyàn kan tún kú
- Iná ìjọba gbé àwọn olújọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi, ẹ̀mí mẹ́rìn lọ si!
- "Who wants to be a Milionaire'' tí pada sí orí afẹ́fẹ́! ẹyin olólùfẹ́ rẹ̀, ẹ kú oríire!
- Ta ni Whitemoney tó gba N90 miliọnu nínú ìdíje BBNaija 2021?
''A ri pe awọn ogiri kilaasi to ku ko ni agbara mọ, ni a fi wo gbogbo rẹ ko ma tun lo wo le awọn akẹkọọ yii lori.''
''Ti a ba fi awọn ogiri to ku silẹ, o le fa ijamba miran ni ọjọ iwaju, amọ a gbọdọ tun kọ.''
Ijọba ipinlẹ Ogun fikun un pe awọn ileẹkọ, ile iwosan ati awọn ileeṣẹ ijọba miran ti awọn woye pe o le fa iru ijamba bẹẹ ni awọn yoo wo palẹ, ti awọn yoo si tun kọ.

















