Prison Break in Nigeria: Ka nípa iye ìgbà tí ikọlu wáyé láwọn ọgbà ẹwọn Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @others
Ikọlu sawọn ọgba ẹwọn Naijiria ko jẹ tuntun.
Bi iṣẹlẹ yi ṣe n waye ni lemọlemọ jẹ ohun to n kọ awọn ọpọ lominu.
Lootọ ijọba a maa sọ pe awọn ko ni foju ẹlẹ wo awọn to ba ṣe ikọlu si ọgba ẹwọn sugbọn ko jọ pe awọn araabi ka ihalẹ yi kun.
- Ohun marun t'ejo n jẹ
- Àrà kengé! Alábòyun ṣe iṣẹ́ abẹ pẹ̀lú abẹfẹ́lẹ́, ó gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀
- "Ó yẹ kí ìjọba máa fún wa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wa lára"
- Ẹ máa gbàá nìṣò, àwa Gómìnà ìhà Gúúsù f'ọwọ́ sí kí ìpínlẹ̀ má gba VAT
- Judasi ìran Oduduwa ni Femi Fani-Kayode pẹ̀lú bó ṣe darapọ̀ APC- Sheikh Gumi
- Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn kankan ní orúkọ mi- Sunday Igboho
Ikọlu kan waye laipẹ yi ni ọgba ẹwọn to wa ni Kabba nipinlẹ Kogi nibi ti awọn okere tan ẹlẹwọn ojilerugba sa mọ awọn alaṣẹ lọwọ.
Ikọlu yi la gbọ pe awọn agbebọn ṣe si ọgba ẹwọn naa.
Yatọ si ikọlu yi, ẹ jẹ ka wo awọn miran to ti waye ṣaaju ni Naijiria.
Ikọlu si ọgba ẹwọn Bauchi
Ikọlu yi waye lọjọ Keje oṣu Kẹsan ọdun 2010 nigba tawọn agbebọn aadọta kọlu ọgba ẹwọn to wa ni Bauchi.
Wọn fura si pe awọn ọmọ ikọ agbesunmọmi Boko Haram lo ṣe ikọlu yi.
Awọn ẹlẹwọn 721 lo ribi salọ, wọn pa marun un ninu wọn ti mẹfa si farapa.
Ikọlu ọgba ẹwọn Ogun
Ni ọjọ Kẹrin oṣu kini ọdun 2013 iroyin gbode pe awọn kan ṣe ikọlu si ọgba ẹwọn Sagamu Minimun Prisons.
A ko ri aridaju awọn to wa nidi isẹlẹ yi amọ awọn ẹlẹwọn ogun ribi salọ ti ọpọ oṣiṣẹ ẹlẹwọn si farapa.
Ikọlu si ọgba ẹwọn Ondo.
Awọn afurasi adigunjale ni wọn fura si pe o wa nidi ikọlu yi.
Lọgbọnjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2013 si lo waye.
Ninu ikọlu ọgba ẹwọn Olokuta Medium Security Prison to wa ni Akure, awọn aadọta agbebọn lo ṣe iṣe aburu yi.
O kere tan awọn ẹlẹwọn 175 lo ribi salọ.Eeyan meji ku ti ẹnikan si fara pa.
Ọgba ẹwọn Eko naa faragba ikọlu.
Lọjọ Kẹwaa, oṣu kẹwaa, 2014 ni Eko faragba ikọlu si ọgba ẹwọn to wa Kirikiri.
Awọn ẹlẹwọn ogun lo ba ikọlu yi lọ ti awọn farapa si to ọgọrin.
O ṣeni laanu pe awọn mejila ribi salọ ninu wọn.
Ikọlu ọgba ẹwọn Kogi
Ninu oṣu kọkanla, ni ikọlu waye si ọgba ẹwọn ijọba apapọ to wa ni Kotonkarfe ni ipinlẹ Kogi.
Afurasi ọmọ ikọ Boko Haram ni wọn lo ṣe iṣẹ yi.
Awọn ẹlẹwọn mẹrinlelogoje lo sa mọ awọn agbofinro lọwọ nigba ti wọn si ri ọkan pa ninu wọn.
- Iléeṣẹ́ ìjọba, ẹ yé ra ọkọ̀ tòkunbọ̀ fàyàwọ́ mọ́- Ajọ Customs kìlọ̀
- Ọkùnrin tó lẹ ''Super Glue'' mọ́ ǹkan ọkùnrin rẹ̀ láti rọ́pò ''condom'' ti dèrò ọ̀run
- Wo iye ìgbà tí bàálù ìjagun ti já tó sì ṣekú pa àwọn ènìyàn ní Nàìjíríà
- Mi ò sọ pé àwọn tó ń pè fún Yorùbá Nation kò yàtọ̀ sí Boko Haram o- Gbajabiamila ṣàlàyé
- ''APC yóò fún Goodluck Jonathan ní ànfàní láti dupò ààrẹ lọ́dún 2023 tó bá darapọ̀ mọ́ wa''
- ''Ìjọba, ẹ má da àwa tó ń ṣagbátẹrù Yorùbá Nation pọ̀ mọ́ IPOB''
Ikọlu ọgba ẹwọn Ekiti
Ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kọkanla ni ikọlu waye ni ọgba ẹwọn ijọba apapọ to wa ni Ado Ekiti.
Oṣiṣẹ ọgba ẹwọn kan ba iṣẹlẹ yi lọ.
Ni meni meji wọn ka ẹlẹwọn ọọdunrun le mọkanlelogoji to sa lọ.
Ikọlu ọgba ẹwọn Minna
Ọjọ Kẹfa, oṣu Kejila ni awọn adigunjale kọlu ọgba ẹwọn yi to wa ni Minna olu ilu ipinlẹ Niger.
Wọn pa agbofinro kan,awọn ẹlẹwọn ọtalenigba le mẹwaa si ribi sa lọ
- ''Ìjọba, ẹ má da àwa tó ń ṣagbátẹrù Yorùbá Nation pọ̀ mọ́ IPOB''
- A ti gbálé ati gbáta, kò sí ǹkankan lọ́wọ́ wa mọ́ ni a ṣe kígbe síta- Adebisi Aisha, Ọmọ Iyabo Oko
- Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn kankan ní orúkọ mi- Sunday Igboho
- Judasi ìran Oduduwa ni Femi Fani-Kayode pẹ̀lú bó ṣe darapọ̀ APC- Sheikh Gumi
Ikọlu ọgba ẹwọn Kuje
Ni olu ilu Naijiria Abuja ni ikọlu yi ti waye ni ọgba ẹwọn to wa ni Kuje lọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, 2016.
Awọn ogbologbo ẹlẹwọn meji Solomon Amodu ati Maxwell Ajukwu ribi fo igana salọ.
Saaju ni ọjọ kọkandinlọgbọn, osu Kẹjọ, ọdun 2016 yi kanna ni awọn kan gbiyanju lati kọlu ọgba ẹwọn Kuje.
Edo
Lọjọ Kọkandilogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 awọn kan to sa sabẹ pe awọn n se iwọde ENDSARS
Kogun ja ọgba ẹwọn to wa ni Benin.
Bẹẹ naa ni wọn yabo ọgba ẹwọn to wa ni Oko.
Lapapọ, ẹlẹwọn ẹgbẹrun meji din mẹsan lo salọ lawọn ọgba ẹwọn wọn yi
Ikọlu ọgba ẹwọn Owerri
Lọjọ karun un, osu Kẹrin, ọdun 2021, awọn kan ti wọn fura si pe wọn jẹ ọmọ ikọ alaabo ilẹ Igbo, Eastern Security Network(ESN) se ikọlu si ọgba ẹwọn to wa ni Owerri.
Ado oloro ni wọn lo lasiko ikọlu yi.
O le ẹgbẹrun kan aabọ ẹlẹwọn to ribi sa ninu ikọlu yi.





















