Kenyan Woman: Aláboyún fi bílédìì gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀ ní Tanzania

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileesẹ ọlọpaa orilẹ-ede Tanzania ti fidirẹmulẹ pe, lootọ ni arabinrin alaboyun kan ṣe iṣẹ abẹ fun ara rẹ, lati gbe ọmọ inu rẹ jade.
Obinrin naa, ẹni ọgbọn ọdun, Joyce Kalinda ni wọn sọ pe, o sọ ara rẹ di onimọ iṣegun oyinbo ọsan gangan, to si gbẹbi ara rẹ.
N ṣe ni Joyce mu bileedi, to si fi la ara a rẹ ni ikun, ko to o gbe ọmọ tuntun naa jade.
- Ṣé Facebook, Instagram, WhatsApp tiyín náà ti dẹnukọlẹ̀? Ìdí tó fi ṣẹ́lẹ̀ rèé
- Pandora Papers tú àṣírí àwọn olóṣèlú jẹgúdújẹrá mẹ́wàá ní Naijiria
- Ajá dóòlà ọmọ tuntun tí ìyá rẹ̀ bò mọ́lẹ̀ láàyè
- Ìyanṣẹ́lódì míràn kò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ àyàfi tí Ijọba àpapọ̀ bá....- ASUU
- Ojú ọjọ́ gbìgbóná jànyinjànyin ti kọjá kèrémí káàkiri àgbáyé
- Yorùbá ẹ fura o! Ìwẹ̀fá ìjọba àpapọ̀ gbáà ní Fani-Kayode tó ń díbọ́n bí ọ̀kan lára wa
- Eré ìfẹ́ di eré ẹkún! Olólùfẹ́ méjì lẹ̀pọ̀ lásìkò tí wọ́n n bá ara wọn sùn nínú adágún odò
- Kokoko lara mí le, Mo kàn ń gba ìtọ́jú ni London ni- Tinubu
Ọjọbọ, ọgbọnjọ, oṣu Karun un, ọdun 2019, ni iṣẹlẹ yii waye ni ilu Kirando, to wa ni ẹkùn Rukwa l'orilẹ-ede Tanzania.
A gbọ pe wọn ti kọkọ gbe obinrin naa lọ sileewosan ilu Kirando fun itọju ko to o bimọ.
Amọ, ṣe lo sa kuro nileewosan, to si pada sile.
Igba to de ile lo ran ọmọ rẹ to kere julọ lati lọ ọ pe ẹgbọn oun kan wa, ni adugbo ti ko jinna si wọn.
Ni kete to si ku oun nikan sinu ile, lo mu bileedi, to la ikun ara rẹ, to si gbe ọmọ tuntun jade.
Igba ti ọmọ to ran niṣẹ pada de, lo ba iya rẹ ati ọmọ tuntun ninu ile, eyi lo si mu ko pariwo 'ẹ gba mi' si awọn alajọgbelepọ wọn fun iranlọwọ.
- N kò lẹ́bi pé ejò kó ₦36m owó àjọ JAMB mì -Philomina
- Ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá mú ààrẹ látí ìhà àríwá Niajiria ní ìdìbò ọdún 2023 yóò pòfo- Gomina Akeredolu
- Ọjọ́ tò burú jùlọ nínú ìrìnàjò oṣèlú mi ni ọjọ ti FFK darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Ojudu
- Sìgá mímu ń di èèwọ̀ oògùn ìlera pípé lagbaye
- Ó pakasọ! Wo ìdí tí àgbẹ̀ kan fi kọ ìyàwó rẹ̀ tó bí ìbẹta sílẹ̀
Wọn si pinnu lati gbe e pada sileewosan to ti sa kuro.
Ọmọ kẹjọ ti obinrin naa yoo bi niyii.
Igbesẹ arabinrin yii ti fa n ha-hin ni agbegbe naa.
















