ASUU Strike 2021: Ìyanṣẹ́lódì míràn kò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ àyàfi tí Ijọba àpapọ̀ bá....- ASUU

ASUU

Oríṣun àwòrán, @Others

Ẹgbẹ awọ̣n olukọ Fasiti ni Naijiria, ASUU ti kilọ wi pe o ṣeeṣe ki awọn bẹrẹ iyanṣelodi miran laipẹ.

Eyi ko ṣẹyin aimu adehun ti ijọba apapọ ṣe pẹlu awọn ẹgbẹ olukọ ṣẹ lati nkan bi osu mẹwaa sẹyin.

Oṣu kejila, ọdun 2020 ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU wọgile iyanṣẹlodi ti wọn gunle lẹyin ti ijoḅa apapọ ṣeleri lati ṣe agbeyẹwo gbogbo ibeere wọn ḷowọ ijọba.

Adari ẹka ẹgbẹ ASUU ni Benin, Ọjọgbọn Fred Esumeh lo sọ ọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sorọ wi pe o ṣeese ki iyanṣẹlodi miran bẹrẹ ni awọn ileewe fasiti kaakiri ni Naijiria nitori aibikita ijọba apapọ.

Esumeh ti ko sọ igba ti iyanṣẹlodi naa ma gberasọ sọ wi pe awọn n duro de abajade ipade pẹlu awọn adaari gbogboogbo ninu ẹgbẹ ASUU lati mọ igbesẹ ti awọn yoo gbe.

Àkọlé fídíò, Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

Ọdun 2020 ni Osu Kẹta ni awọn olukọ fasiti gunle iyansẹlodi nitori igbesẹ ijọba apapọ lori asunwon owo awọn oṣiṣẹ, to fi mọ awọn abuku to wa kaakiri awọn fasiti ni Naijiria.

Amọ, ẹgbẹ ASUU ni titi di asiko yii ijọba ko tii gbe igbese kankan lati parọ asuwọn owo IPPIS ṛe pẹlu asuwọn ibi ikọwopamọsi fun awọn Fasiti, ti wọn pe oruko rẹ ni ''University Transparency and Accountability Solution ''.

Wọn ni ijọba apapọ mọọmọ se ifaṣẹyin nipa mimu ileri wọn ṣe nipa asunwọn owo University Transparency and Accountability Solution naa.

Bakan naa ni ijọba kọ lati san awọn ọmọ ajẹmọnu fun ẹka eto ẹkọ ni fasiti naa.

Àkọlé fídíò, Jẹ́ ká lọ sílu mi: Kò sí ìtàn Ibadan láìsí Efunsetan, Òkè méje, Bower's Tower àtàwọn ǹkan

Kikọ lati fi iye owo to to ogoji bilionu naira silẹ lati fi tun awọn fasiti gbogbolowo ṣe.

Ẹwẹ, ẹgbẹ ASUU nipinlẹ Plateau ti fẹsun kan ijọba ipinlẹ naa labẹ aṣẹ ijọba gomina Simon Lalong jẹ awọn olukọ ni gbese ̣ni osu mẹrin odun 2020.

Àkọlé fídíò, Suicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

Bakan naa ni ijọba kuna lati gbe igbesẹ lori kikọ awọn ile igbe, iyẹn staff quarters fun awọn olukọ ni awọn ileewe fasiti, ni ipinlẹ naa.