EFCC Chairman: Adarí àjọ EFCC wà ni àláfíà, kò sí nǹkan tó ṣe , yóò padà sí ẹnu iṣẹ̀ rẹ̀ ni àìpẹ́- Agbẹnusọ EFCC

Agbẹnusọ àjọ EFCC Wilson Uwujaren ti ṣàlàyé nǹkan tí ó ṣẹll sí ọ̀gá àjọ náà lósàn òní

Oríṣun àwòrán, Effc

Ọ̀sán ọjọ́ àlàmísì ni ni ìròyìn kan pé adari àjọ tọ n gbọgun ti ìwà jẹgudújẹra Abdulrasheed Bawa lo jọ bi ẹni pé òyì kọ́ lásìkò tó n sọrọ̀ níbi ìpàdé kan ni Aso Rock.

Ìròyìn sọ pé, wọ́n pèé síbi ètò kan ni Aso Rock sùgbọ́n lásíkò tí wọ́n pèé sórí gbàgede ló bẹ̀rl ọ̀rọ̀ rẹ tí o ní láti sọ, sùgbọ́n ni kété tó sọ̀rọ̀ tá tí ó sì pàdà sí àa[yé rẹ̀ ló subú sórí àga rẹ̀.

Kíá náà ni àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ sáré rọ̀gbà yíi ka.

Àkọlé fídíò, Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

Ẹ̀wẹ̀, àjọ tó n gbogun ti ìwà jẹgúdújẹrá (EFCC) náà tí fí àtẹ̀jáde kan síta pé, ayọ̀ àti aláíà ní ọ̀ga àwọn wà

Bákan náà ni wọ́n fi kun nínú àtẹ̀jáde tí adári ètò ìròyìn àti ọ̀rọ̀ tó n lọ Wilson Uwujaren fi ọwọ́ sí lo tan imọlẹ ọ̀rọ̀ náà nípa ipò tí Bawa wa ní ìlú Abuja.

Àtẹjáde náà sọ báyìí pé, : Ara ọ̀gá àwọn le koko ko si wàhálà kankan

Ó ni, ó ṣe pàtàkì láti tan imọlẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lónìí, ọjọ́ kẹrindílógun, oṣù kẹsan, ọdún 2021 ni ilé ìjọba ni Abuja.

Uwujaren ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lásìkò tó n sọ̀rọ̀ ìkíni níbi ètò ayẹyẹ ọjọ́ idánimọ (National Identity Day), àsìkò yìí ló jọ bi éni pé, o rẹ̀ẹ́ díẹ̀, o sì lọ la'ti jòkó sí ààyè rẹ̀.

"Wọ́n ti ṣe ìtajú tó yẹ fún , yóò sì padà sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ láìpẹ́."