Climate Change: Wo ìpalára tí ojú ọjọ́ gbígbóná ń ní lára èèyàn

Ni ọdun 1980 si 2009, igba mẹrinla laarin ọdun ni oju ọjọ gbigbona to 50C ma n waye,amọ o ti da igba mẹrindinlọgbọn
Iwadii ti fihan pe oju ọjọ to n gbona lagbaye ti n goke si kaakiri orilẹede lagbaye.
Oju ọjọ to kọja 50C(122F) ti peleke si ni ida meji ju ti igba aye atijọ ni nkan bi ọdun 1980.
Bakan naa ni oju ọjọ gbigbona yii ti wa n ṣẹlẹ kaakiri awọn orilẹede lagbaye ju ti tẹlẹ lọ.
- Níbo ní àwọn èèyàn tí ń jẹ tata yìí nítorí ìyàn tó mú?
- Ẹ wo àwọn àwòrán BBC tó lààmì laaka lọ́sẹ̀ yìí.
- Wo iye ìgbà tí bàálù ìjagun ti já tó sì ṣekú pa àwọn ènìyàn ní Nàìjíríà
- Wo ojú àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń dá bírà rere ní àgbáyé
- Bí àwọn orílẹ̀-èdè ti ko lówó ṣé n tiraka láti bá ayípada ojú ọjọ́ yí rèé
- Buhari ní Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́sẹ̀ ìmúṣẹ àdéhùn Paris 2020
Ni ọdun 1980 si 2009, igba mẹrinla laarin ọdun ni oju ọjọ gbigbona to 50C ma n waye.
Amọ ni bayii, igba mẹrindinlọgbọn ninu ọdun kan ni oju ọjọ gbigbona jainjain ti ru soke si lati ọdun 2010 si ọdun 2019.
Bakan naa ni o ma n to ọsẹ meji nigba miran ti oju ọjọ gbigbona fi ma n wa ni 45C tabi ju bẹẹ lọ laarin ọdun.

Onimọ nipa ọrọ oju ọjọ ni fasiti Oxford ni ilu London, Dr Friederikw Otto ni oju ọjọ gbigbona yii ko ṣẹyin awọn ohun elo ti wọn fi n ṣe epo bẹntirol ti wọn n lo ninu ọkọ lo fa eyi.
Otto ni gbogbo agbaye lo wa ninu ewu oju ọjọ gbgbona to kọja keremi, paapaa lawọn orilẹede to wa ni gbungun agbaye at agbegbe Gulf pẹlu.

Ninu ọdun yii, orilẹ-ede Italy ni oju ọjọ gbigbona to to 48.8C, nigba ti Canada ni oju ojo to to 49.6C, to si ṣeeṣe ki awọn orilẹede miran ni ju bẹẹ lọ.
Awọn onimọ gba awọn to n ṣe epo bẹntirol nimọran lati mura ni kiakia lati fi opin si nitori ọrọ naa kan gbogbo agbaye.
- Kí ló ń fa ìjàmbá omíyale ní Naijiria?
- Ààrẹ Joe Biden tí gba àwọn ọmọ Naijiria láàyé látí wá sàtìpó ní Amẹrika
- US election 2020: Bi kò tilẹ̀ wọlé, ẹ wo ayípadà tí Ààrẹ Trump mú bá awọn orilẹede ní àgbáyé
- Buhari ní Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́sẹ̀ ìmúṣẹ àdéhùn Paris 2020
- Báwo ni Joe Biden yóò ṣe mú ìyípadà bá òfin tí Trump fi de orílẹ̀èdè àgbáyé?
Ipa wo ni oju ojo gbigbona yoo ni lara eniyan?
•Iwadii ileeṣẹ BBC fihan wipe oju ojo gbigbona le e fa ijamba fun agọ ara eniyan ati ọpọlọpọ ailera.
•ṣeeṣe ki awọn eniyan ni aisan ooru lati inu wa nitori oju ọjọ to gbona riri.
•Bakan naa ni oju ọjọ gbigbona n fa ki iyan mu ati awọn ina nla nla ni awọn agbegbe ti ko tii ṣẹlẹ ri.
•Awọn agbẹ naa yoo ni ipalara nitori ko ni si bi nkan ọgbin yoo ṣe dagba soke tabi gberu si nitori ilẹ gbigbẹ ati asalẹ.












