Climate change: Ìwádìí ní ó nira fún àwọn orílẹ̀èdè tó tòsì láti kópa lórí ọ̀rọ̀ àyíká

Climate change: Bí àwọn orílẹ̀-èdè ti ko lówó ṣé n tiraka láti bá ayípada ojú ọjọ́ yí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn orílẹ̀-èdè tí kò rọ́wọ́ họrí n tiraka lati daabo bo ara wọn, lodi si iroyin nipa ọrọ ayika oju ọjọ to n jade, gẹ́gẹ́ bi awọn onimọ ṣe sọ fun BBC.

Ile iṣẹ to n soju awọn orilẹede aadọrun sọ nipa igbiyanju wọn lati dẹkun ijamba to lee ṣẹlẹ, bii àwọn ajalu ibi, ti ayipada oju ọjọ ti mu wa, eyi to maa n ṣẹlẹ lojoojumọ.

Ajọ isọkan agbaye ni ọpọ awọn orilẹede ti ko tii to oju bọ́ to n gbiyanju lati ba igbayi lori ayipada oju ọjọ ti n pọ si, sugbọn ko si ẹri aridaju pe awọn igbesẹ yii mu adikun ba awọn ewu to wa nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A ni lati lo awọn ilana wa lori ayipada ọjọ tó n buru si nigba gbogbo.

Awọn ilana ti a gbe silẹ tẹlẹ to lati daabo bo awọn eniyan wa, gẹgẹ bi Sonam Wangdi, to jẹ alaga awọn orilẹede ti ko tii toju bọ nipa ayipada ayika labẹ ajọ isọkan agbaye se sọ.

Àkọlé fídíò, Female Car AC Repairer: Abimbola Adedigba ní àfojúsùn òun ni láti ní abúlé mẹkáníkì láìpẹ́

Ipe wọn yii wa, bi ajọ isọkan agbaye se n pinu lati gbe awọn iwadii wọn sita lọjọ aje, paapaa julọ nitori bi ayipada oju ọjọ ṣe n peleke si.

Awọn abajade ti awọn ile iṣẹ ti kii ṣe ti ijọba lori ọrọ ayipada oju ọjọ gbe jade, ni eyi yoo pese amojuto to ni imọ sayẹnsi ninu, lori awọn isoro asiko yii ati ti ọjọ iwaju.

Iwadii yii ni wọn fẹ ki o jẹ ilana ti awọn ti yoo gbe ofin bi nkan yoo se ri labẹ ajọ isọkan agbaye tẹle, nibi ipade ti yoo waye ni Glassgow ninu oṣu kọkanla ọdun yii.

Lati asiko ti awọn ile iṣẹ ti n peleke sii ni agbaye, ni aye ti n gbona si pẹlu 1.2C, bẹẹ si ni aye yoo ṣe maa gbona si ni ayafi ti awọn ijọba ni agbaye ba wa wọrọkọ fi sada, lati mu opin ba awọn eefin to n jade lawọn ile iṣẹ.

Wahala n waye ni Caribbean:

Climate change: Bí àwọn orílẹ̀-èdè ti ko lówó ṣé n tiraka láti bá ayípada ojú ọjọ́ yí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ọdun to kọja Caribbean ti se akọsilẹ ilọpo lọna ọgbọn ìjì tó yẹ ki o ja wọn, ti o fi mọ ìjì lile Hurricane mẹfa, àwọn ile iṣẹ to n moju to ọrọ ayika ni orilede naa ṣẹṣẹ n pada bọ sipo.

Ní orilede bi Antigua àti Baruda, awọn onimọ sọ pe ọpọ ile ni ko le farada awọn iji lile ti o ti ṣẹlẹ.

Awọn yeepẹ inu okun n pọ si letido Pacific:

Climate change: Bí àwọn orílẹ̀-èdè ti ko lówó ṣé n tiraka láti bá ayípada ojú ọjọ́ yí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ awọn etido orilẹede naa ni iji lile (Cyclone) mẹta laarin ọdun 2020 ati ninu osu kini ọdun 2021.

Lẹyin iji lile naa mẹta to waye ni awọn ilu mẹta ni iha ariwa orilede naa, ni wọn ti ri ti yeepẹ inu odo n modi yi wọn ka.

Iwadii sọ pe Cyclone ti n peleke si lati bi ogoji ọdun sẹyin sugbọn awọn yeepẹ to n mọ soke naa n pọ si sugbọn ko si ẹni to le fi idi rẹ mulẹ.

Ori Oke n pọ si ni Uganda

Climate change: Bí àwọn orílẹ̀-èdè ti ko lówó ṣé n tiraka láti bá ayípada ojú ọjọ́ yí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ní orilede Uganda, awọn ilu ni ẹkun Rwenzori ti n gbiyanju lati daabo bo ara wọn lọwọ ilẹ yiyẹ ati agbara, nipa gbigbẹ ilẹ ati gbigbin igi lati daabo bo ilẹ wọn.

Sugbọn sibẹ ko ti so eso rere.

" Ojojumọ ni ojo n rọ, ti oniruuru isẹlẹ omiyale, agbara ya sọọbu si n ba wọn ja, gbogbo àwọn igbiyanju wọn lo n gba lọ pẹlu, gẹgẹ bi Jackson Muhindo, ẹni to jẹ alabojuto ọ̀rọ̀ ayipada oju ọjọ fun Oxfam se sọ.

Climate change: Bí àwọn orílẹ̀-èdè ti ko lówó ṣé n tiraka láti bá ayípada ojú ọjọ́ yí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Labẹ ifẹnuko ajọ isọkan agbaye lori ayipada oju ọjọ, àjọ isọkan Yuroopu àti àwọn orilẹede mẹtalelogun mii to ti to oju bọ, ni wọn jẹjẹ pe awọn yoo ma ṣe agbekalẹ ọgọrun bilọnu dọla lọdọọdun, lati maa se awọn iṣẹ akanse lori ayipada oju ọjọ lawọn orilede ti ko tii tojuubọ.

Awọn iṣẹ akanṣe bii mimu adinku ba eefin awọn ile isẹ nla nla, lọna lati mu adinku ba awọn isoro ti ayipada oju ọjọ ba da silẹ lawujọ.

Lati ọdun 2020, ni wọn ti n gbe owo yii fun ajọ Green Climate Fund, ati awọn ile iṣẹ bẹẹ miiran.

Sugbọ́n ọpọ awọn orilẹede ti ko tii tojuubọ yii, ni wọn ko mu ileri kankan ṣẹ.