Hijra Celebration: Akeugbagold ní Ànọ́bì kò ṣe àjọ̀dún Hijrah nígbà àyé rẹ̀ àmọ́ kò sí ẹ̀sẹ̀ níbẹ̀

Ninu awọn ajọdun to wa ninu ẹsin Islammu, meji pere lo pọn dandan, ti o si se pataki fun gbogbo olugbagbọ ododo.
Awọn ajọdun yii, gẹgẹ bi awọn onimọ ẹsin se sọ, ni Eid Adha,ọdun ileya ati Eid Fitr,ọdun itunu awẹ.
Amọ nibayi ti awọn ọmọlẹyin Islammu kan ni Naijiria ti n beere fun ọjọ isinmi fun ayajọ ibẹrẹ ọdun musulumi taa mọ si First Muharram, pupọ lo ti n beere pe se lootọ ni ọjọ yii yẹ fun ajọdun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ìgbésẹ̀ tuntun tí DSS ń gbé láti dojú béèlì àwọn ọmọlẹ́yìn Igboho méjìlà bolẹ̀
- Sunday Igboho kọ́ ló ń gbọ́ bùkàtà ẹ̀jọ́ rẹ̀, àwa àjìjàgbara ní - Banji Akitoye
- Ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ikú tó pa Jumoke Oyeleke lọ́jọ́ ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota
- Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí bọ́ nígbà tí ìjánu tírélà já, ó wó lu ọkọ̀ akérò taxi kan mọ́ inú kòtò n‘Ibadan
- Mo gbádùn bí wọ́n ṣe ń pè mí ní ''audio governor''- Seyi Makinde
- IPOB àti ìjọba ń lérí lórí òfin kónílé ó gbélé, ta ni yóò tẹríba fúnra wọn?
Ni ipinlẹ Oyo ati Osun, to fi mọ awọn ipinlẹ mii lapa ariwa Naijria, ijọba kede isinmi lẹnu isẹ fun ajọ́dun ibẹrẹ ọdun musulumi tii se First Muharram.
Ni onka oju ọrun, Muharram ni musulumi maa n pe osu akọkọ ni afiwe January ti awọn to n lo onka Gregorian Calendar.
Hijrah ti wọn so mọ ibẹrẹ ọdun yii ni isẹlẹ to waye nigba ti Anọbi Muhammad sa asala kuro ni Makkah to jẹ ilu rẹ lọ si Madinah.
Awọn to ni Anọbi ko se ajọdun Hijrah ni Point sugbọn...Akeugbagold
BBC Yoruba ba eekan onimọ ẹsin kan to fi ilu Ibadan se ibujoko, Sheik Taofeek Akeugbagold sọrọ lati yannana boya o tọ lati se ajọdun ọjọ Hijra abi ko tọna.
Ninu idahun rẹ, Sheikh Akeugbagold ni awọn to sọ pe ko ba ilana Islamu mu ati awọn to ni o baa mu, awọn mejeeji lo ri wi.
O ni lootọ ni pe Anọbi ko se Hijrah ati pe o ti lọ tan, ki awọn kan to se agbekalẹ ọdun naa.
''Umar, ọkan ninu awọn Sahabah lo sọ pe o yẹ ki awọn musulumi naa ni ọna ti wọn yoo maa fi se onka ọdun tiwọn.
''Saaju asiko yii tawọn musulumi yoo ba ranti ọdun, wọn a maa lo isẹlẹ to ba waye lati fi ranti ọdun naa bii apẹrẹ, ọdun ti omiyale sẹlẹ tabi ọdun ti iyan mu ni ilu.''
O ni nitori eyi, ''Lẹyin ọpọ ijiroro, Umar ni ki osu Muharram, ti Hijra to waye lasiko Anọbi bọ si, maa jẹ ibẹrẹ ọdun onka ti musulumi.''
Akeugbagold tun se lalaye pe, ẹkọ to wa nibi isipopada yii ni pe, o kọ awọn musulumi lẹkọ pe ti aye baa se n yi, ko saburu ki wọn lọ si ibomiran.
Akewugbagold tun fi kun ọrọ rẹ pe ni Saudi Arabia, awọn gan ko ya ọjọ sọtọ lọjọ isinmi fun ọjọ akọkọ Muharram sugbọn wọn a maa si ilẹkun Kaaba lọjọ yii lati se idanimọ ibẹrẹ ọdun tuntun mii.
O ni bi ijọba ti se fun awọn musulumi ni ọjọ yii gẹgẹ bi ọjọ isinmi lawọn ipinlẹ kọọkan dara nitori awọ́n eeyan Naijiria ko ribi jẹ anfaani ti awọn musulumi Saudi n jẹ lọdọ ijọba wọn.
''Ọwọ isinmi ti wọn fun wa yii da nitori yoo maa jẹ iranti fun wa. Se ẹ ri awọn Larubawa, wọn mọ pataki awọn onka osu yii.Wọn kii fii se ere.O ti mọ wọn lara''
''Ko si ẹsẹ ti wọn ba fun wa ni họlide Hijrah sugbọn Anọbi ko se laye rẹ. Apọnle ni fun awa musulumi. Ko si ninu Quran ati Hadith lootọ.''
Lakotan, Akeugbagold ni awọn musulumi dupẹ lọwọ awọn Gomina to ti ya ọjọ́ yii sọtọ, ati pe awọn n rọ́ awọn to ku lati se bẹẹ pẹlu.
Sheikh Akewugbagold tun sọ pe ''A fẹ ki wọn fi se apọnle Islammu fun wa. Yoo dun mọ wa ninu pupọ ti wọn ba se bẹẹ."





















