Jumoke‘s Death Trial: Ìyá olóògbé ní kíjọba gbé òkú ọmọ òun fún sílẹ̀ láti sín lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ̀

Mọlẹbi Jumoke Oyeleke, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn to jade laye lasiko iwọde Yoruba Nation lagbegbe Ojota nilu Eko ti gbe ileesẹ ọlọpaa lọ sile ẹjọ lori iku ọmọbinrin naa.
Bẹẹ ba gbagbe, ariyanjiyan ti n waye saaju lori iku to pa Jumoke ni ọjọ Satide, ọjọ kẹta osu Keje ọdun 2021.
Saaju ni ileesẹ ọlọpaa ti ni oun ko mọ nipa ọta ibọn ti wọn lo pa Jumoke, ti wọn si ni oku rẹ ti gan, kawọn eeyan kan to gbe wa si agbegbe Ojota, ti iwọde naa ti n waye.
- Ta a ló yìnbọn pa Jumoke, ọmọ ọdún 14 nítòsí ibi ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota?
- Ìwádìí wa fihàn pé kìí ṣe òkú tùtù ni ọmọ tí wọ́n sọ pé a pa ní Ojota, àwa sì kọ́ ló pa á - Ọlọ́pàá Eko
- Ìyàtọ̀ wà láàrin èsì àyẹ̀wò ikú Jumoke àti ohun tí ọlọ́pàá sọ
- Ìjọba Eko jáwọ́ nínú ẹ̀sùn tó fi kan Ọba Ogboni pé ó pààyàn ní ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó yóò ṣe ìwádìí òhun tó ṣ'okùnfà ikú Jumoke tí ọtá ìbọn bá ní Ojota
Amọ ayẹwo awọn onisegun fi han pe ọta ibọn lo ba Jumoke to fi jẹ ipe Ọlọrun lọjọ naa.
Idi ree ti mọlẹbi oloogbe naa fi pe ẹjọ lati mọ ẹni to pa ọmọ wọn gan, ijiya to tọ si labẹ ofin ati ẹtọ to tọ si mọlẹbi to padanu ọmọ wọn naa.
Igbẹjọ ọhun si lo waye ni Kootu kinni, ile ẹjọ Majisireti ilu Eko to wa ladugbo Ogba.
Nigba to n salaye bi iku ọmọ rẹ se waye fun BBC Yoruba lẹyin igbẹjọ naa, iya oloogbe naa, Ifeoluwa Oyeleke ni oun ko gbọ rara pe wọn fẹ se iwọde kankan ni ọjọ ti ìṣẹ̀lẹ̀ yii waye.
O ni oun ni awọn nnkan ti oun fẹ́ se nilẹ ni ọjọ́ ti iṣẹlẹ yii sẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho kọ́ ló ń gbọ́ bùkàtà ẹ̀jọ́ rẹ̀, àwa àjìjàgbara ní - Banji Akitoye
- Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí bọ́ nígbà tí ìjánu tírélà já, ó wó lu ọkọ̀ akérò taxi kan mọ́ inú kòtò n‘Ibadan
- Mo gbádùn bí wọ́n ṣe ń pè mí ní ''audio governor''- Seyi Makinde
- IPOB àti ìjọba ń lérí lórí òfin kónílé ó gbélé, ta ni yóò tẹríba fúnra wọn?
- Ta ni èṣù láàrin ìjọ Ọlọ́run àti Hushpuppi? - Daddy Freeze bèèrè
- Ajínigbé yìnbọn pa ọkọ, jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ l'Ekiti
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìbálòpọ̀ lásìkò nǹkan oṣù lè ṣekúpa ọkùnrin?
- Babaláwo fi ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe òògùn owó, ṣe ètùtù owó fún ara rẹ̀
- Ohun tó ṣe ìdíwọ́ rèé táwọn alátìlẹ́yìn Sunday Igboho méjìlá kò fi kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n - Agbẹjọ́rò
"Mo lọ si ibi isẹ, Jumoke, tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn naa si maa n lọ si ibi isẹ ti wọn ti n ta Ice Cream ni oju dọsini amọ ni aago meje abọ awọn eniyan n pe mi pe nibo ni mo wa, ki n tete maa bọ.
Nigba ti mo dele, mo ri gbogbo eniyan ti wọn joko si palọ bọọda mi, wọn sa sọ fun mi pe ibọn pa Jumoke.
Lẹyin naa ni wọn ni ki n jẹ ki a lọ si agọ ọlọpaa Area H ni Ogudu, boya wọn yoo gbe oku rẹ fun wa, amọ bi ojo se n rọ to awọn ọlọpaa ko gba ki a wọle."
Ifeoluwa tẹsiwaju pe, nigba ti awọn ọlọpaa gba lẹyin o rẹyin pe ki awọn wọle, ọga ọlọpaa ibẹ ni lóòtọ́ọ́ oun gburo ibọn sugbon ko ye oun ibi ti ibọn ti wa.
O ni ọga ọlọpaa naa wa fi ọwọ sọya pe awon yoo se iwadii lati mọ ibi ti iro ibọn ti n dun, to si gba adirẹsi awọn pe ki awọn ma lọ.
Ile ẹjọ ti wa sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ Kẹfa osu Kẹsan ọdun to n bọ fun itẹsiwaju igbẹjọ ọhun.
Iya Jumoke fikun pe lọjọ naa, awọn ọlọpaa tun pada wa wo awọn sugbon lati igba naa, awọn ko gbọ ohunkohun mọ asiko yii.
Awọn eeyan ko yọju sile ẹjọ lati wa jẹrii nipa bi Jumoke se ku tori ibẹru ọlọpaa - Agbẹjọro
Wayi o, iya Jumoke ti ke si ijọba atawọn osisẹ ọlọpaa lati fi oku ọmọ rẹ silẹ fun ko le tete lọ sin bo se yẹ.
Obinrin naa to n fi omije sọrọ lori iku ọmọ rẹ ni, ọpọ ti isẹlẹ naa soju rẹ ni ko mọ pe ẹjọ naa ti n bẹrẹ, to si fọwọ gbaya pe oun yoo tubọ ko ẹlẹ́ri wa sile ẹjọ gẹgẹ bi adajọ ti salaye.
Ninu alaye agbẹjọro to n gbọ ẹjọ naa, Amofin Taiwo Olawanle ni ile ẹjọ ti fi ọrọ wa eeyan mẹta lẹnu wo, pẹlu ọga Jumoke ati ọkunrin to wa nibẹ nigba ti isẹlẹ naa waye.
"Ile ẹjọ ni awọn ẹlẹri to sọrọ lonii gbọdọ fi ọwọ si iwe pe lootọ ni ọrọ naa se oju wọn koro.
Lootọ ni ọpọ eeyan n bẹru lati jade wa sile ẹjọ wa jẹri, paapaa nitori bi awọn ọlọpaa se ko eeyan mọkandinlaadọta, ti wọn si ni ọkan lara wọn lo pa Jumoke, ti onitoun ko si ni ibọn lọwọ lati fi pa eeyan.
Eyi gan lo mu ki ọpọ eeyan maa sa lati wa jẹri nile ẹjọ, ki ọwọ̀ ọlọpaa ma baa ba wọn.
Nigba toun naa n ba BBC Yoruba sọrọ,a buro Mama Jumoke to tẹ le ẹgbọn rẹ wa sile ẹjọ ni idajọ ododo ni nnkan soso ti awọn n beere fun lori iku to pa Jumoke laipe ọjọ.
Bkan lo ni awọn n fẹ ki ijọba tọju iya Jumoke, ki wn si fun ni ẹtọ to ba tọ si.



















