Lagos Yoruba Nation rally: Jumoke ń retí kí n ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀ ọdún 25 fún un ni wọ́n pa níbi ìwọ́de

Àkọlé fídíò, 'Ẹ má jẹ́ kí òkú ọmọ mi ráre o ìjọba! Ẹ gbée fún mi kí n lọ sin ín - Ìyá ọmọ ti wọ́n pa ní ìwọ́de Yoruba Nation

Bí mo ṣe rí èrò tó péjọ sí Pálọ̀ Daddy wa, mò ń gbàdúrà pé Ọlọ́run má jẹ́ kó jẹ́ èmi ni wọ́n ń bá ṣọ̀fọ̀

Ẹkun ko ṣee pamọra bi BBC Yoruba ṣe ṣe ibẹwo si idile ọmọ ti wọn pa nibi iwọde Yoruba Nation to waye ni agbegbe Ọjọta nipinlẹ Eko. Iya r ṣi n wa ẹkun mu ni.

Arabinrin Ifeoluwa Adeeko to jẹ iya Jumoke ọmọ ọdun mẹẹdọgbọgbọn ti wọn pa nibi iwọde Yoruba Nation to waye ni ilu Eko ni bi ọmọ yii ba lọ ba eeyan ṣiṣẹ to pa owo wale, ọwọ ọhun naa loun n papọ mọ ti ọwọ oun to fi n tọju awọn ọmọ.

Ọmọ ti wọn pa

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

O ni ago meje owurọ ni Jumoke ji jade kuro nile lati lọ si ṣọọbu lọjọ naa.

"Jumoke ni akọbi mi, ago meje lo ji jade nile lọjọ Satide ọhun, o n ta ọja lọwọ ni ibọn yẹn fi lọ ba a".

Iya Jumoke ni awọn lọ si agọ ọlọpaa lọjọ ti iṣẹlẹ yẹn ṣẹlẹ, wọn le awọn danu ni ti wọn ni awọn yoo da afẹfẹ taju taju si awọn lara.

"Awọn ọlọpaa sọ fun wa pe awọn gburo ibọn amọ awọn o mọ ibi ti ibọn yẹn ti wa, afi ti wọn ba yọ ọta ibọn ni wọn to le mọ bo ṣe jẹ".

Ọgbẹni Yekini Afolabi to jẹ ẹgbọn iya Jumoke ni awọn ti iṣẹlẹ yẹn ṣoju wọn sọ fun awọn pe wọn yinbọn baa ninu ṣọọbu ni.

"Igba ti nkan yn ṣẹlẹ ti awọn to rii to ṣubu fẹ pada wa gbe oku ẹ, igba ti wọn rii ti awọn Ọlọpaa tun n bọ ni wọn tu ka".

O ni irọ gbaa ati asọdun ni ohun ti ọlọpaa sọ pe ẹjẹ ti wọn ri lara ọmọ yẹn ti gbẹ pe wọn o fẹ ki ijba gbọ pe awọn pa eeyan lai ṣe pe ogun ṣẹlẹ.