Lagos Yoruba Nation Rally: Femi Falana ní ètò tí Ọlọ́pàá ti ṣe sílẹ̀ ló fa ikú ọmọ ọdún mẹ́rìnlá náà

Femi Falana

Oríṣun àwòrán, Others

Agbẹjọro agba ati ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana ti sọrọ lori iṣẹlẹ to waye ni Ọjọta lasiko iwode Yoruba Nation to mu ẹmi ọmọ odun mẹrinla lọ lasiko iṣẹlẹ naa.

Femi Falana ni awọn ọlọpaa ko ṣeeṣi yin ibọn lu ọmọbinrin ti orukọ rẹ n jẹ Jumoke naa, amọ wọn ti ro ninu ara wọn tẹlẹ wi pe awọn yoo pa eniyan lasiko iwọde ọhun.

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ọta ibọn awọn kọ lo pa Jumoke nitori awọn ko yinbọn lasiko iwọde Yoruba Rally to waye ni ilu Eko.

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa òkú gbígbẹ́ tí wọ́n ṣì bá oyún nínú rẹ̀?

Falana lasiko to n ba ileeṣẹ iroyin Sunday Punch sọrọ ni ileeṣẹ ọlọpaa doju ofin orilẹede Naijiria bolẹ ni Section 83 (4), nitori awọn ọlọpaa lo yẹ ko pese aabo fun awọn araalu.

O ni awọn ọlọpaa yẹ ko pese aabo fun awọn to n ṣe iwọde ni ọwọọwọ lai si wahala, amọ niṣe ni ọlọpaa tu wọn ka ni ọna aitọ.

Agbẹjọrọ agba naa ni ileeṣẹ ọlọpaa n parọ ni pe awọn kọ lo pa ọmọ naa lati da abo bo ẹni to ṣiṣẹ ibi ọhun laarin wọn.

''Nitori awọn ọlọpaa le awọn oluwọde naa lọna aitọ fihan pe wọn mọọmọ pa ọmọ ọdun mẹrinla naa.''

''O ṣeni laanu bi awọn ọlọpaa ṣe sare sọ wi pe awọn kọ ni wọn ṣiṣẹ ibi naa lai ṣewadii''

Bakan naa ni Femi Falana wa ke si ijọba ipinlẹ Eko lati ṣe ayẹwo ni ileewosan, iru iku to pa ọmọbinrin ọdun mẹrinla naa ni ibi iwọde Yoruba Nation.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni inu ṣọọbu iya rẹ ni Jumọke wa ti ibọn ti lọ ba ani ikun to si ku lojiji.