Yoruba Nation: Ìrìn padà tẹ fún ìrìn, àwọn aláwo siwájú ìwọ́de láti kojú ọlọ́pàá l‘Eko

Iwọde Yoruba Nation Rally to kọkọ ṣebi ẹni pe ko ni waye nilu Eko ti pada gbera sọ bayi
Ṣugbọn awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun ti fi omi ati afẹfẹ tajutaju tu awọn oluwọde naa ka.
Akọroyin wa to jabọ lati ibi iwọde naa nilu Eko sọ pe lọwọ aarọ ti oun debẹ niṣe lawọnb ọlọpaa kun iwaju aaye inaju Gani Fawehinmi ti ko si si oluwọde ni tosi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ta a ló yìnbọn pa Jumoke, ọmọ ọdún 14 nítòsí ibi ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota?
- Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa Saheed Adigun (Adogan) tó kú nílé Sunday Igboho
- Sunday Igboho ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí DSS pa
- "DSS yin ọta ìbọn 48 sí Adogan, kò sì kú, ni wọn bá fi ọmọ odó fọ lórí"
- "DSS tó kọlu ilé Sunday Igboho dàbí pé wọ́n gbé ‘Map’ ilé náà lọ́wọ́ ni"
- Ìlérí ta ni yóò ṣẹ láàrin àwọ̀n olùwọ̀de Yoruba Nation àti ọlọ́pàá?
- Nnamdi Kanu áti IPOB burú ju Boko Haram, agbébọn lọ - Nasir El-Rufai
- DSS kò mú mi lọ́dọ̀ Guru Maharaji, èmi rèé n‘Ibadan, ẹ sinmi àhesọ ọ̀rọ̀ - Sunday Igboho
- Bí ìjọba Buhari bá yege láti pa mí ni, yóò ní ‘Unknown Gunmen’ ló wá pa mí - Sunday Igboho
Nigba ti yoo fi di nkan bi ago mọkanla ni Kọmisana ọlọpaa ipinlẹ Eko Hakeem Odumosu wa lati ba awọn akọroyin sọrọ.

Bi o ṣe n ba awọn akọroyin sọrọ ni awọn oluwọde naa ba ṣadede ṣi wa, ti wọn si bẹrẹ si ni kọrin lorisirisi pe iya pọ to n jẹ awọn ni Naijiria.
Ariwo Yoruba Nation, Ooṣa ati bẹẹ bẹẹ lọ si lo gbode nibi iwọde naa ti waye, ti awọn oluwọde si n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba kuro lara ni Naijiria.

Ki a to wi ka to fọ, awọn ọlọpaa ti gbe ọkọ nla wọn lati maa fi yin omi si awọn oluwọde ti wọn si tun wọn ka.
Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn oluwọde kan ti wọn si gbe wọn si inu ọkọ wọn ti wọn gbe wa.
Bakan naa ni iron ibọn n dun lakọ lakọ


















