Lagos Yoruba Nation Rally: Ta a ló yìnbọn pa Jumoke, ọmọ ọdún 14 nítòsí ibi ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota?

Oríṣun àwòrán, facebook/ koiki media
Iroyin kan to tẹ BBC Yoruba lọwọ ni pe ọta ibọn ti pa ọmọdebinrin kan ni agbegbe Ọjọta nilu Eko.
Ninu fidio kan to tẹ BBC lọwọ, lati ri ti wọn tẹ oku ọmọbinrin naa silẹ, ti ẹjẹ si bo ara rẹ lọwọ ikun si isalẹ ara rẹ.
Ninu fidio naa niṣe ni eero pe yi oku ọmọ naa ka, ti wọn si fi aṣọ bo .
Bakan naa ni ọkunrin kan to ṣeeṣe ko jẹ pe oun lo ya fidio naa n pariwo pe nibi ti ọmọdebinrin naa ti n ko ọja jade ninu ṣọọbu obi rẹ ni ọta ibọn ti fo wa a ba.
Pẹlu nkan taa ri ninu fọnran fidio naa, o ṣebi ẹni pe lagbegbe Freedom Park ni adugbo Ojọta nilu Eko ni iṣẹlẹ yi ti waye.
Awọn eeyan sọ ninu fidio naa pe ọmọ ọdun mẹrinla ni ọmọdebinrin naa.
Bakan naa ni iwe iroyin abẹle The Punch sọ pe ikun ni ọta ibọn naa wọle si ni ara rẹ, eyi to pa a loju ẹsẹ.
Ṣugbọn titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, a ko le fi idi orisun ọta ibọn naa mulẹ, boya lati ọdọ awọn oṣiṣẹ alaabo lo ti wa ni tabi ibomii.
















