Sunday Igboho: Afenifere Renewal Group ní láì sí ẹ̀rí, yóò nira láti gbàgbọ́ pé ilé Igboho ni DSS ti rí èròjà tó pàtẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/sunday Igboho
Eekan ẹgbẹ Afẹnifẹre Renewal group, Alagba Wale Oshun ti sọrọ soke lori ikọlu DSS si ile Sunday Igboho lọjọbọ.
Ẹgbẹ ARG ní ko si bi ajọ agbofinro DSS ṣe lee lero pe awọn ọmọ Yoruba atawọn ọmọ Naijiria yoo gba ọrọ rẹ gbọ pe ni ile Sunday Igboho ni wọn ti ri awọn ibọn atohun ija oloro ti wọn fi han nilu Abuja.
Ninu Ọrọ kan to ba BBC News Yoruba sọ, Oloye Wale Oshun ṣalaye pe, ajọ DSS gbọdọ mu ẹri to daju jade pe ni ile gbajumọ aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, ni wọn ti ri nnkan ijagun naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló dé tí DSS kó bàńtẹ́ òògùn, ba ilé Sunday Igboho jẹ́ lái fara pa?
- "DSS, níbo ni ₦2m àti owó Euro, Dollar àti Pound Sterling tẹ kó nílé mi wà? "
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
- Sunday Igboho ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí DSS pa
- Princess tún sọ òkò ọ̀rọ̀ sí Iya Rainbow lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- À ṣe ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko, bí ọlọ́pàá fẹ́, bó kọ̀ - Igun Sunday Igboho
Alagba Oshun tun ṣalaye pe laye olori orilẹede Naijiria tẹlẹ, Ọgagun agba Sani Abacha, bi awọn eeyan ṣe pariwo aibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan lasiko naa, sibẹ awọn agbofinro kii fi agidi wọ ile eeyan ti wọn fẹ mu.

Oríṣun àwòrán, DSS
O ni awọn agbofinro yoo kọkọ fi iwe pe onitọun, ki wọn to wa si ile rẹ fun ayẹwo 'bi o ba si nilo ki wọn mu u lọ fun ifọrọwanilẹnuwo, wọn a ṣe bẹẹ'.
O ni ajọ DSS gbọdọ ranti gẹgẹ bi ọmọ Naijiria, Sunday Igboho lanfani si awọn ẹtọ kan ti wọn gbọdọ tẹle, bi wọn ba fẹ wa si ile rẹ fun ohunkohun.
O fi kun un pe, ajọ DSS yoo nilo lati sọ ibi ti wọn ti ri awọn ohun ija oloro ti wọn ni awọn ko ni ile Igboho, afi ti wọn ba fa awọn ẹlẹri sita lati fi gbe ara wọn lẹsẹ pe, lootọ inu ile Igboho ni wọn ti ko wọn sita.
- "Sunday Igboho, Banji Akitoye, ẹ rìn jìnnà sójú pópó Eko fún ìwọ́de Yoruba Nation"
- Afenifere figbe bọnu pé ìkọlù sí òmìnira àti ẹ̀tọ́ láti sọ̀rọ̀ ti padà dé
- Ìbọn àti nǹkan ìjagun ni Igboho kó pamọ sílé ló jẹ kí á yabo ilé rẹ̀ - DSS
- Gani Adams tutọ́ sókè fójú gbà lórí ìkọlu sílé Sunday Igboho
- Níbo ní Sunday Igboho wà lẹ́yìn ìkọlù síle rẹ̀? Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà ń bèèrè














