Nigria: Gbogbo ìpilẹ̀sẹ̀ ìṣoro Nàìjíríà ni àtúnyẹ̀wò òfin yóò mójútó - Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Femi Gbajabiamila/Facebook
Adari ile igbimọ aṣojuṣofin Naijiria, Femi Gbajabiamila ti ni igbesẹ ti awọn n gbe lọwọ lori atunṣe ofin Naijira n waye tori ati koju awọn iṣoro to ti wa tipẹ lara orilẹede Naijiria.
Gbajabiamila n sọrọ lasiko ipade apero awọn adari igbimọ laarin awọn aṣofin eyi to waye niluu Abuja lọjọ Ẹti nibi to ti pe fun ajọṣepọ laarin ile aṣofin agba atawọn ile aṣofin ipinlẹ lati jẹ ki atunṣe ofin ọdun 1999 naa ṣe aṣeyọri.
O ni awọn aṣofin ṣe pataki lara gbogbo iha ijọba orilẹede to ba n lo ilana ijọba awa-ara-wa.
- ''Ṣọ́ọ̀bù ìyá rẹ̀ ní Jumoke wá tí ìbọn ọlọ́pàá ti pa lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota''
- Àyẹ̀wò tí a ṣe fihàn pé kìí ṣe òkú tútú ni ọmọ tí wọ́n sọ pé a pa ní Ojota - Ọlọ́pàá Eko
- Kí ló mú Lai Mohammed pe gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara ni amúni-búni àṣìwọ̀ ọkọ? Ẹkúnrẹ́rẹ́ rèé
- Ìwádìí wa fihàn pé kìí ṣe òkú tútú ni ọmọ tí wọ́n sọ pé a pa ní Ojota, àwa sì kọ́ ló pa á - Ọlọ́pàá Eko
- Wo ohun tó yẹ kí o ṣe sí ojú abẹ́ rẹ, ''vagina'' lẹ́yìn ìbálòpọ̀
"Erongba gbogbo atunyẹwo ta n ṣee si iwe ofin orilẹede yii ni lati dojukọ awọn kudiẹ kudiẹ to ti wa lati ipilẹ iwe ofin Naijiria eyi to ti n gbọnwọ si titabuku iyi, alafia ati ilọrọ Naijira lagbaye".
Kete ti ile aṣofin agba ba ti pari iṣẹ tiwọn, Gbajabiamila ni wọn yoo fi ṣọwọ awọn ile aṣofin ipinlẹ ki awọn ni ipin ninu ayẹwo yii.
"Ilana ṣiṣe ayẹwo iwe ofin yii ko lee yọri si rere lai ba si ajọṣepọ to gunmọ laarin gbogbo awa taa wa nibi", ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Gbajabiamila, Lanre Lasisi fi sita lo ti sọ eyi.
Gbajabiamila ni awọ́n kan le ro pe ṣekuṣẹyẹ loun torii pe nipa bi iṣẹ oun ṣe ri, o ni ṣe pẹlu kikorajọ pẹlu gbogbo ẹni tọrọ kan lati da abo bo ẹtọ awọn ọmọ̀ Naijiria toripe awọn aṣofin naa ni aṣọ to kangun si eegun awọn araalu.
"Otitọ ni pe ni ilana iṣẹ wa, awọn aṣofin nikan lo gba iṣ labẹ ofin lati wa sibi iṣẹ lojoojumọ lati maa ja fun ifẹ awọn araalu to jẹ pe ni asiko yii o ṣe deede fun idagbasoke ilu".
O ni iyi nla ni eyi jẹ fun awọn inu oun si dun lati fihan pe awọn to koju osuwọn to si mọ pataki akoko yii lo n ṣe ayẹwo ofin naa.
Gbajabiamila jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe iha mẹta ni ijọba ni ti awọn jẹ ọkan pẹlu ẹka ofin ati ẹka awọn alaṣẹ, amọ ohun to n lọ lọw yii ti gbe iṣẹ awọn yọ.













