Best way to clean vagina after sex: Wo ohun tó yẹ kí o ṣe sí ojú abẹ́ rẹ lẹ́yìn ìbálòpọ̀

Vagina: "How to keep you vagina healthy after sex"

Oríṣun àwòrán, EMMA RUSSELL

O dara lati jẹ ki oju ara rẹ gẹgẹ bi obinrin wa ni mimọ, paapa awọn ti wọn fẹran ibalopọ ti wọn si n ṣee ni gbogbo igba.

Ajọ Eleto Ilera ni Ilẹ Gẹẹsi, NHS UK ni awọn kokoro ti a foju ri ati awọn eleyii ti a ko foju ri to fi mọ aarun ni o le wọ oju ara obinrin lasiko ibalopọ.

Awọn kokoro aifojuri yii ni ohun pada wa di arun si ara eniyan bii chlamydia, gonorrhoea, genital herpes, genital warts, syphilis ati arun HIV.

Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

O le da abo bo ara rẹ lasiko ibalopọ nipa lilo rọba idaabobo, amọ awọn ọna miran ree lati da abo bo ara rẹ.

Lo si baluwẹ lẹyin ibalopọ

Vagina

O dara lati maa lọ si baluwẹ lati lọ tọ lẹyin ibalopọ, nitori eleyii yoo fọ awọn kokoro aifojuri to ti lee wọle sinu ara lasiko ibalopọ jade.

Ti o ko ba lọ si baluwẹ lẹyin ibalopọ, o lee fa awọn arun to n ba ile itọ ja.

Fọ oju ara rẹ daradara

Kete ti o ba ti ni ibalopọ tan, rii daju wi pe oju abẹ rẹ wa ni mimọ nitori o dara bẹẹ.

Bi o ṣe dara lati lọ si baluwẹ lati tọ lẹyin ibalopọ naa ni o dara lati lati fọ oju abẹ ni agbegbe Vulva, lai fi agbara kaka fọ ọ.

Ẹ lo omi lati fi fọ oju ara lati yọ oru, ẹda ati awọn nkan mii kuro ni oju ara.

Amọ, ti ẹ ba fẹ fi oṣẹ fọ oju ara, ẹ rii pe eleyii ti ko le ni ara lara, ki ẹ si fọ ọ diẹdiẹ.

Àkọlé fídíò, 'Oko ni mo wà lọ́nà "Express" Ilesha tí àwọn agbébọn yìnbọn bá ẹnu mi tí mò fi dà báyìí'

Ranti lati fọ oju abẹ lati iwaju lọ si ẹyin

Vagina: "How to keep you vagina healthy after sex"

Oríṣun àwòrán, BSIP

Ni igba kigba ti o ba n fọ oju ara rẹ rii daju pe oun fọ ọ lati iwaju lọ si ọwọ ẹyin ki o baa le mọ daradara.

Eyi ni lati dena kokoro aifojuri to ba wa ni agbegbe rectum ko ma wọ vagina rẹ.

Ti o ba n fọ oju abẹ rẹ lati ẹyin si iwaju o le mu ki kokoro afojuri korajọ papọ si agbegbe rectum to si le fa aisan si ara ati oju ara.

Ṣọra fun lilo ọṣẹ to lagbara lati fi fọ oju ara

Awọn obinrin miran ma n lo oṣẹ to lagbara bii soda, ọti lile lati fi fọ oju ara.

Amọ ileeṣẹ eto ilera ni eleyii lewu pupọ nitori o le le awọn kokoro asaraloore to yẹ ko wa nibẹ tẹlẹ, eleyii ti awọn obinrin nilo.

Oju ara ni awọn kokoro aifojuri sibẹ, amọ wọn wa nibẹ lati da abo bo oju ara ni.

Ko si aridaju pe fifọ oju ara pẹlu oṣẹ to lee pa kokoro aifojuri tabi arun, amọ o lee fa aisan si ara.

Ẹ sọra fun fifi ohun elo oloorun si abẹ tabi 'wipes' oloorun.

Ileeṣẹ eto ilera NHS ni gbogbo awọn ohun elo oloorun yii ni o ma n ba eroja oju ara to wa nibẹ jẹ.

Ohun ti o nilo ni lati lo omi lati fi fọ oju ara rẹ.

Ọjọgbọn to mọ nipa ibalopọ ni ti eedua ba fẹ jẹ ki oju ara maa run bii ohun oloorun didun roses ati Lavender, a ti da oju abẹ lati maa run bẹẹ.

Mọ oju ara rẹ, iyẹn vagina daradara

Agbegbe oju abẹ gangan ni Vagina to rọ to si gun, ohun ni o ma n mu igbadun wa lasiko ibalopọ

Bakan naa ni vagina ọhun so ile ọmọ, iyẹn uterus to wa ni inu wa si ita.

Vagina ọhun ni o ma n gba nkan ọmọkunrin sara lasiko ibalọpọ.

Bẹẹ si ni ibẹ ni ọmọ ma n gba jade lasiko irọbi ati ibimọ.