Lagos Yoruba Nations Rally: Iléeṣẹ́ ''Coroner'' ní Èkó ṣetán láti ṣ'àyẹwò lórí òkú Jumoke kí wọ́n lè mọ̀ òhun tó sekú pa á

Oríṣun àwòrán, Facebook/Lagos State Government
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe awọn yoo bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ to mu ẹmi ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹrinla kan lasiko iwọde Yoruba Nation Rally ladugbo Ọjọta lọ.
Arabinrin taa n wi yi, Monsurat Jumoke Oyeleke, ni ọta ibọn ba ti ko si si ẹni to le sọ pato ẹni to yinbọn.
Ninu atẹjade kan ni ikede ọrọ yii wa eyi ti Moyosore Onigbanjo to jẹ kọmisana feto idajọ buwọlu.
Moyosore ni awọn ti gbọ iroyin nipa iku arabinrin yii tawọn si ti ni ki wọn bẹrẹ iwadii iku rẹ.
O ni labẹ ofin to n dari ọrọ iwadii ohun to ṣokunfa iku eeyan, iwadii yi yoo mu esi jade ti wọn yioosi yẹ oku wo finifini.
Pupọ eeyan lo ti n lọgun ki ijọba ma ṣe jẹ ki wọn doju ọrọ ru lori iku Jumoke.
Awọn ẹgbẹ Oodua wa lara awọn to n ke gbajare yi to fi mọ awọn obi Jumoke ti wọn ni ki iku ọmọ awọn ma ṣe lọ bẹ.

Ọlọ́pàá ''Area H'' ní bí a bá pẹ́ jù níwájú àgọ́ àwọn, ìbọn làwọn yóò fi fọ́ wa lẹ́sẹ̀ -Iya Jumoke
Ko si nkankan ti mo fẹ ju ki awọn agbẹjọrọ wa bami ja ki iku ọmọ mi ma ja sasan.
Ọrọ to jade lẹnu iya to bi ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrinla to kagbako iku lọwọ ọta ibọn ni agbegbe Ojota, nilu Eko ree.
Arabinrin Ifeoluwa Adeeko ṣalaye ọrọ yi nigba to n ba ileeṣẹ iwe iroyin Naijiria Punch sọrọ lọjọ Aiku.
- Àwọn ọmọ ìkókó níléèwòsàn kàgbákò agbébọn! Wọ́n jí wọn gbé pẹ̀lú nọ́ọ̀sì
- Ta a ló yìnbọn pa Jumoke, ọmọ ọdún 14 nítòsí ibi ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota?
- Sunday Igboho kọ̀wé sí ìjọba àpapọ̀, o ní dandan kí wọn sàn owó gbà má bínú ₦500m
- Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho dé síbi ìwọ́dé Yoruba Nation l‘Eko?
- Bí Igboho kò bá jáde, àwa yóò jáde fúnra wá, ìyà pọ̀ - Oluwọde Yoruba Nation
Abiyamọ yi sọ pe titi di bi oun ṣe n sọrọ, awọn ko ti ri oku ọmọ oun ati pe ọgbẹ ọkan nla ni iku Monsurat Jumoke Oyeleke jẹ fun oun.
''O ni aburo mẹta. Ọmọ to si maa n gbiyanju ni Jumoke jẹ. Ibiṣẹ ni mo wa ni Ikeja ti wọn fi ni ki n maa bọ wa sile''
Ninu ifọrwanilẹnuwo yi, arabinrin Ifeoluwa ni awọn gbiyanju wa oku ọmọ oun lọ si agọ ọlọpaa H Division ni Ogudu ṣugbọn wọn ni awọn ko le ri oku rẹ.

Oríṣun àwòrán, Punch Newspapers
''Ọlọpaa 'Area H' ni bi a ba pẹju niwaju agọ awọn, ibọn lawọn yoo fi fọ wa lẹsẹ. A duro siwaju agọ wọn titi ti ẹgbọn mi fi ba wọn sọrọ ti wọn wa pada ni ka wọle''
Ẹgbọn iya Jumoke,Yekini Afolabi toun naa ba ileeṣẹ iroyin Punch sọrọ ṣalaye pe 'Area Commander' ọlọpaa Area H ni lootọ loun gbọ nipa iṣẹlẹ Jumoke.
O sọ pe o ni awọn yoo ṣe iwadii lori ọta ibọn ti wọn ba yọ ninu Jumoke lati mọ ibi to ti wa.
Arakunrin Yekini sọ pe ọga ọlọpaa naa pada yọju si awọn lati wa ba mọlẹbi kẹdun ti wọn si ni awọn yoo ṣe iwadii iku rẹ.
Wiwa awọn ọlọpaa yi ṣebi ẹni tako ọrọ ti alukoro ọlọpaa ti ṣaaju gbe jade pe ko si ọlọpaa kankan to yinbọn nibi iwọde Ojota.
Koda o ni oku Jumoke kii ṣe oku tutu ati pe awọn kan lo gbe wa si agbegbe naa ko ba le da bi pe awọn ọlọpaa lo yinbọn pa.
Iya Jumoke wa ke gbajare si awọn ọmọ Naijiria la ti ma ṣe jẹ ki wọn doju ọrọ yi ru.
O ni ''A o leeyan bẹẹ laa ni owo ṣugbọn Ọlọrun leeyan taa ni. A o f ki wọn fi iya yi jẹ wa gbẹ. Ẹ ṣaanu wa''

Oríṣun àwòrán, Koiki Media
'Ṣọ́ọ̀bù ìyá rẹ̀ ní Jumoke wá tí ìbọn ọlọ́pàá ti pa á lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota'
Awọn to pejọ si ibi ti iṣẹlẹ iku ọmọ ọdun mẹrinla, Jumoke to lọ lasiko iwọde Yoruba Nation nipinlẹ Eko ti ni jẹjẹ ọmọ naa lo wa ni ibi itaja iya rẹ ti ibọn ti lọ pa a.
Agbẹnusọ fun Igboho, Olayomi Koiki lo kede bẹẹ loju opo Facebook rẹ.
Koiki ni ọmọ naa joko si inu sọọbu iya rẹ to si n wo bii iwọde ṣe n lọ nigba ti ọlọpaa bẹrẹ si ni yin ibọn.
- Àyẹ̀wò tí a ṣe fihàn pé kìí ṣe òkú tútú ni ọmọ tí wọ́n sọ pé a pa ní Ojota - Ọlọ́pàá Eko
- Ìwádìí wa fihàn pé kìí ṣe òkú tútú ni ọmọ tí wọ́n sọ pé a pa ní Ojota, àwa sì kọ́ ló pa á - Ọlọ́pàá Eko
- "DSS yin ọta ìbọn 48 sí Adogan, kò sì kú, ni wọn bá fi ọmọ odó fọ lórí"
- Bí Igboho kò bá jáde, àwa yóò jáde fúnra wá, ìyà pọ̀ - Oluwọde Yoruba Nation
- Gbogbo ìpilẹ̀sẹ̀ ìṣoro Nàìjíríà ni àtúnyẹ̀wò òfin ta ń ṣe yìí yóò mójútó - Gbajabiamila
O ni o ṣeni laanu pe orilẹede Naijiria ti da ẹmi ọmọde naa legbodo.
Ọsan ọjọ Satide ni iroyin jade pe ọta ibọn ọlọpaa lo pa ọmọbinrin naa lasiko to n ko ọja sita ninu ṣọọbu iya rẹ, ni Ojota, nitosi ibi ti iwọde Yoruba Nation ti waye.
Amọ, Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti fesi si iroyin to n lọ pe ọta ibọn wọn lo pa Jumoke, ọmọ ọdun mẹrinla ni Ojota l'Eko lasiko iwọde Yoruba Nation.
Ninu atẹjade to fi sita, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa naa, Muyiwa Odejobi sọ pe ayederu iroyin patapata ni iroyin naa, ati pe o jẹ ọna lati da ibẹru ati wahala silẹ lọkan awọn eeyan rere to n gbe ni ipinlẹ Eko ati Naijiria lapapọ ni.

Oríṣun àwòrán, facebook/ koiki media
Bakan naa lo sọ pe iwadii yoo bẹrẹ ni kiakia lati mọ nkan to ṣokunfa iku ọmọdebinrin naa tori ni tiwọn wọn ni oku ọhun kii ṣe oku tutu.
Wọn wa rọ awọn eniyan ipinlẹ Eko, lati ma a ba igbokegbodo wọn lọ lai bẹru.














