Military plane crash: Ọkọ̀ òfurufú tó kó ọmọogun méjìléláàdọ́rùn ún tó fẹ lọ́ kojú àwọn alakatakiti ẹsín já lulẹ̀

Aworan ina ati efi nibi ti baalu naa ja lulẹ si

Oríṣun àwòrán, REUTERS/BOGS MUHAJIRAN

Ọkọ baalu akero ileeṣẹ ọmọ ologun orileede Phillipines kan to ko ero mejilelaadọrun ti ja lulẹ lagbegbe Guusu ilẹ naa.

Oku eeyan mẹtadinlogun ni wọn ti ri nibi to ja lulẹ si ni erekusu Jolo ṣugbọn eeyan ogoji moribọ ninu ijamba naa ti wọn si ti gbe wọn lọ si ile iwosan.

Ọkọ baalu naa to jẹ irufẹ C130 Hercules la gbọ pe o n gbiyanju lati balẹ si papakọ ofurufu Jolo nigba ti o sare kọja oju titi.

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa òkú gbígbẹ́ tí wọ́n ṣì bá oyún nínú rẹ̀?

Akọwe ileeṣẹ ologun Delfin Lorenzana lorileede naa lo ṣalaye ọrọ yi.

Niṣe ni eefi ati ina n ṣẹyọ lọkankan ibi ti baalu naa ti ja lulẹ.

Ileeṣẹ iroyin lorileede ọhun ṣafihan awọn aworan ibi to ja lulẹ si ti ina si n jo lagbegbe kan ti igi pọ si to sunmọ awọn ile kan.

Awọn ọmọ ologun lati Cagayan de Oro ti ko jina pupọ si Jolo ni baalu naa ko lasiko to fi ja lulẹ ni nkan bi ago mọkanla aabọ owurọ lagbegbe naa.

Ọgagun Sobejana sọ fun awọn akọropyin pe ''O sare kọja oju popo nigba to fẹ balẹ. Wọn gbiyanju lati da pada ṣugbọn pabo lo ja si''

Awọn ọmọ ogun yi wa lara awọn ti wọn ko lati lọ koju awọn alakatakiti ẹsin Islamu bi ikọ Abu Sayyaf.

Aworan afihan ibi ti orileede Phillipines wa

Awọn alaṣẹ ilẹ naa sọ pe ko si apẹrẹ pe wọn ṣe ikọlu si baalunaa ati pe iwadii yoo bẹrẹ kete ti wọn pari eto idoola awọn to wa ninu rẹ tan.

Pupọ ninu awọn to wa ninu baalu naa gẹgẹ bi AFP ṣe jabọ ṣẹṣẹ pari idanilẹkọ ijẹ ọmọ ogun niulẹ naa.