TB Joshua Burial: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní kí ìjọ SCOAN tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò ìṣínkù Wòlí TB Joshua tí yóò bẹ̀rẹ̀ lónìí

TB Joshua

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

Ijọba ipinlẹ Eko ti buwọlu eto isinku adari ijọ Synagogue Church of All Nations (SCOAN), Woli TB Joshua to jade laye.

Eyi ko ṣẹyin bii ijọ naa ṣe n reti ọpọlọpọ eniyan kaakiri agbaye ti wọn yoo ma awa si ibi isinku naa lati oni lọ.

Kọmiṣọnna fun eto ilẹra nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi to saaju awọn to ṣe abẹwọ sibẹ ni idi ti awọn fi lọ sibẹ ni lati ri pe wọn tẹlẹ ilana to de arun Coronavirus.

Abayomi ni awọn n gbiyanju lati ri pe ọwọja ikẹta aarun Coronavirus to n kaakiri awọn orilẹede paapaa India, ko ja de Naijiria.

TB Joshua

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

O ni awọn ko fẹ ki arun Coronavirus to ti n rele ni Naijiria tun ru gẹgẹ si oke si nitori iye awọn eniyan to n bọ lati okeere wa si Naijiria.

''A tun fi asiko yii ba ẹbi ati ara oloogbe TB Joshua kẹdun ipapoda ẹni ire to lọ, paapaa ni asiko yii.''

TB Joshua

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

''Ohun ti a mọ ni pe orisirisi ọwọja aarun Coronavirus lo n ja kaakiri ni agbaye bayii, amọ a ko fẹ ko wọ ilu Eko.''

''Lẹyin iku T.B Joshua ni gomina ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki a ṣe abẹwo to yẹ si ile ijọsin naa nitori eniyan nla lo kọja lọ, ti ọpọlọpọ eniyan yoo si pejọ sibẹ.''

TB Joshua

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

''Nibayii, gbogbo ẹni to ba n bọ gbọdọ wa ni ipamọ fun ọjọ meje, lẹyin naa ni wọn to le darapọ mọ ayẹyẹ kankan.''

Bakan naa ni kọmisọnna ohun ni gbogbo eto lo ti wa lati ri pe ẹnu ibode Naijiria gbogbo lo wa ni ilana idẹkun arun Coronavirus.

Ẹ mú "Candle" wá síbi ètò ìsínkú Wòlíì TB Joshua tí yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́la - Ìjọ Synagogue

Gẹgẹ bi eto isinku gbajugbaja Wolii agbaye ni ati ati oludari ijọ Synagogue Church of All Nations, Temitope Joshua yoo ṣe bẹrẹ lọsẹ yii, ijọ naa ti kéde ohun to yẹ ni ṣiṣe fun awọn ti yoo wa nibi eto isinku naa.

TB Joshua

Oríṣun àwòrán, TB Joshua/instagram

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe isin akọkọ ti yoo waye, kii ṣe gbogbo eniyan ni yoo lanfani lati wa nibẹ tori wọn ko ṣe aye silẹ fun gbogbogbo amọ awn ti ko ba si nibẹ lee ba awọn pe lori ayelujara tabi lorii tẹlifisan wọn.

Ninu fidio ti wọn fi sita lori ayelujara ijọ SCOAN lowurọ oni yii kan naa ni wọn ti ki awọn eniyan nilọ pe ki wọn ṣọra fun awọn ọdaran to n dibọn bii ileeṣẹ tẹlifisan Emmanuel tabi ijọ SCOAN lati maa beere owo lọwọ wọn fun eto isin ikẹyin Woli TB Joshua.

Atẹjade eto isinku TB Joshua

Oríṣun àwòrán, TB Joshua/instagram

"Ole paraku ni iru awọn bẹẹ! Ẹ ma jẹ ki ẹnikẹni tan yin jẹ, Ọlọ run mọ bo ṣe n sọrọ si ọkan awọn eeyan lati na ọwọ si ohun ti a nilo. A o ran ẹnikẹni, a ko si ni ran ẹnikẹni lai lai".

Ileeṣẹ naa ni awọn ni ọna ti awọn fi n kan si awọn onigbọwọ awọn nipasẹ Emmanuel TV to jẹ agbẹnusọ awọn.

Lẹyin eyi ni wọn kede ilana bi eto isinku ti yoo bẹrẹ lọla yoo ṣe lọ laarin ọla ọjọ karun titi di ọjọ kọkanla oṣu keje eyi ti wọn n pe akori rẹ ni "kii ṣe temi, bikoṣe ifẹ Ọlọrun".

TB Joshua lori oke

Oríṣun àwòrán, TB Joshua/instagram

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa òkú gbígbẹ́ tí wọ́n ṣì bá oyún nínú rẹ̀?

Ninu ikede naa ni wọn ti ni eto idagbere nipa titan abẹla yoo waye ni ọjọ Aje ọjọ karun oṣu keje. Wọn kede pe ki awọn to n bọ ma gbagbe ati mu abẹla wọn dani.

Koda wọn ni "gbogbo ẹni ti ko ba le wa sibi eto naa, o lee tan abẹla ninu ile rẹ gẹgẹ bi ami didarapọ mọ wa lati inu ile lati bu iyi fun iranṣẹ Ọlọrun oloogbe TB Joshua".

Lọjọ keji eyi ni wọn isin orin idagbere lataarọ yoo waye ninu ijọ SCOAN to wa ni Eko ninu eyi ti ẹ o ti lanfani lati jẹri nipa ohun rere ti Ọlọrun ti lo Wolii naa lati ṣe ninu aye yin.

Isin ti wọn ni aaye rẹ wa ni ṣiṣi fun gbogbo awọn eeyan amọ pẹlu aaye ijoko to lonka ni eyi ti yoo waye l'Ọjọbọ ati ọjọ Ẹti.

Bi ko ba gbagbe, laip ti ikede iku Wolii Temitope jade ni Ọba ilu ibi rẹ, Arigidi-Akoko ti sọ fun ẹbi pe awọn n f ki wọn wa bu iyi fun ilu awọn nipa sinsin oku rẹ si Arigidi amọ ij pada kede ninu ijọ wn to wa ni Eko ni yoo ti waye.

Nibayii, ijọ Synagogue Church of All Nations ti kede iyawo oloogbe gẹgẹ bi adari tuntun.