Bethel Baptist School Kaduna Kidnap: Agbébọn tún jí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Baptist kan gbé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin ti jade pe awọn agbebọn kan ti yabo ile ẹkọ Bethel Baptist School to jẹ ile ẹkọ aladani kan ti ijọ Onitẹbọmi ni Kaduna ti wọn si ji awọn akẹkọọ aimọye gbe.
Alaga ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Kristẹni lorilẹede Naijiria ẹka ti ipinlẹ Kaduna, Alufa Joseph Hayap sọ fun BBC pe iye awọn ọmọ to wa ni ile ẹkọ naa to ọgọsan ṣugbọn pe iye awọn ti wọn lee ri ka bayii jẹ ogun pere.
Ileewe ọhun ni iroyin ni o wa lagbegbe Maraban Rido ni ijọba ibilẹ Chikun nipinlẹ Kaduna.
Iroyin sọ pe awọn agbebọn dede ya wọ inu ile ẹkọ naa to wa lopoponaa Kaduna si Kachia lowurọ ọjọ Aje ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn sinu afẹfẹ ki wọn to ji awọn akẹkọọ naa gbe.
Mo ti yọ'wọ́ lọ́rọ̀ òṣèlú Nàìjíríà, tẹ́ẹ bá ń gbọ́ pé Obasanjo dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀, "ẹyẹẹ̀ mi kọ́"!
A gbọ pe awọn kan lara wọn ribi sa mọ wọn lọwọ ti wọn si ko awọn toku lọ si ibi ti nikẹni ko mọ.
Alufa Joseph ni ko tii ye boya awọn aadọjọ to ku ni wọn jigbe tabi awọn kan salọ mọ awọn ajinigbe lọwọ.
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, awọn Ọlọpaa ko tii sọ ohunkohun.
Iṣẹlẹ yii n waye lẹyin wakati melo kan ti awọn ajinigbe ṣẹṣẹ ji awọn ọmọ ikoko, nọọsi atawọn oṣiṣẹ alaabo gbe ni ileegbe họsibitu ti wọn ti n wo ikọ fée ati arọ san niluu Zaria nipinlẹ Kaduna kan naa.
Jijinigbe pawo ti wa di ohun to wọpọ kaakiri orilẹede Naijiria paapaa pẹlu bi wọn ṣe n doju le awọn ile ẹkọ.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin yii wa fun un yin bo ba ṣe n lọ.













