Abuja-Kaduna road: Àwọn olùwọ́de dí òpópónà Abuja sí kaduna lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé

Oríṣun àwòrán, Twitter/AustynZOGS
Iroyin ti a n gbọ ni pe awọn olufẹhonuhan ti di ọna mọrosẹ ilu Abuja si Kaduna.
Awọn oluwọde naa yabo oju popo Kaduna si Abuja lati fi ẹhonu han lori iṣẹlẹ ijinigbe to n ṣẹlẹ loju popo naa ni gbogbo igba.
Awọn oluwọde naa sun ọpọ taya lagbegbe Gauraka Tafa.
- Genesis Global: Sáká lara Woli Israel Ogundipe dá, kìí ṣe àìlera ló mú kí wọn fi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n
- TAMPAN pàṣẹ pé 'director' kankan kò gbọdọ̀ pe Nkechi Blessing àti Adams Kehinde sí iṣẹ́ mọ́
- Wọn ò bí Baba Ijesha dáa kó sọ pé kò mọ mí rí - Agbẹjọ́rò Adesina Ogunlana
- Àfinra! Amotekun lé àwọn Fulani 137 tó gba inú igbó ìjọba lọ́nà àìtọ́ kúrò l'Ondo
- 'Ọkọ̀ ńlá méjì ló kó àwọn Fulani wọ Ajowa Akoko ní Ondo, àmọ́ a ti jọ ń sọ̀rọ̀ pé ...'
- Tinubu, Gbajabiamila, Sanwo-Olu gbárùkù tí fífòfin de dída ẹran káàkiri ìgboro
Eeyan mẹẹdogun ni iroyin sọ pe awọn ajinigbe ṣẹṣẹ gbe tan loju ọna ọhun.
Akọroyin kan tiẹ sọ pe awọn oluwọde tun danu sun awọn agọ ọlọpaa lasiko iwọde naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Oriṣiiriṣii fidio ifẹhonuhan ọhun lo lu oju ayelujara pa.
Eto abo ti mẹhẹ bayii kaakiri orilẹede Naijiria pẹlu iṣẹlẹ ijinigbe ati iṣekupani to n ṣẹlẹ.








