Fulani herdsmen: A lé wọn kúrò l'Ondo nítorí wọn kò lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n wá ṣe - Amotekun

Amotekun

Oríṣun àwòrán, @OndoFirstBorn

Ikọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti le awọn Fulani bi i mẹtadinlogoje kuro ninu igbo ti wọn gba lọna aitọ nipinlẹ naa, ti wọn si da olukuluku pada si ipinlẹ to ti wa

Inu Igbo Elegbeka ni opopona marosẹ Benin si Owo ni wọn ti ko wọn.

Adari awọn Amọtẹkun nipinlẹ Ondo Adetunji Adeleye lo fidi ọrọ yii mulẹ.

Àkọlé fídíò, 'Iṣẹ wá burẹkẹ síi tórí Covid-19, owó ńlá ló wà nínú dídáná sun òkú, ìsìnkú Zoom, Live streaming'

O ni o fẹ si awọn leti pe awon kan ti gba inu Igbo ìjọba ni Elegbeka, lẹba Ifọn, nijọba ibilẹ Ose ni ipinlẹ naa, eyii si lo mu awọn gbe igbesẹ.

Adeleye fi kun pe awọn ko awọn eniyan naa wa si olu ile iṣẹ Amọtẹkun niluu Akure lati fi ọrọ wa wọn lẹnuwo, ọpọ wọn lo sọ pe awọn wa lati iha ariwa Naijiria sugbọn wọn ko le sọ pato nnkan ti wọn wa ṣe ni Ipinlẹ Ondo.

Gẹgẹ bi Adeleye ṣe sọ, o dabi ẹni pe awọn kan n padi apo pọ mọ awọn ajoji naa lati maa gbe inu Igbo ọhun lọna aitọ

O ni awọn ti da gbogbo awọn to wọle lọna aitọ naa pada si ibi ti wọn ti wa.

Laipẹ yii ni awọn ọmọ ikọ Amọtẹkun yii kan naa sin awọn mejilelogoji kan lati Kano ati Jigawa jade kuro ni ipinlẹ Ondo, lẹyin ti wọn ri wọn ni ilu Okitipupa.

Ikọ Amọtẹkun Ondo wa fi gbogbo awọn eniyan ipinlẹ lọkan balẹ pe aabo to daju wa fun gbogbo wọn ati nkan ini wọn.

Àkọlé fídíò, Tóò bá fẹ́ràn àti máa pọ́n ọ̀rọ̀ tàbí èèyàn lé, ẹ̀kọ́ ráńpẹ́ yìí yóò wúlò fún ọ

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ìdí tí a fi lé àwọn Fulani 42 tó ya bo agbègbè Okitipupa padà sí ìpínlẹ̀ wọn - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo

Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Ijọba ipinlẹ Ondo ti ṣalaye idi to fi da awọn ọkunrin mejilelogoji to jẹ ara oke ọya pada si ipinlẹ wọn.

Nibi ipade awọn akọroyin kan to waye niluu Akure ni adari ikọ Amotekun ipinlẹ naa, Adetunji Adeleye ti sọ pe awọn eeyan naa le ṣakoba fun eto abo ipinlẹ ọhun lo jẹ ki wọn le wọn kuro ni ipinlẹ naa.

Ṣaaju ni awọn eeyan agbegbe Okitipupa ti kọkọ ke gbajare si ijọba pe awọn gende ọhun to jẹ Fulani ya bo agbegbe wọn, eyi to da ibẹrubojo sọkan awọn araalu.

Ni kete ti awọn oṣiṣẹ ikọ Amotekun gbọ pe awọn Fulani kan ti gunlẹ si agbegbe Okitipupa ni wọn tẹkọ lọ si ilu naa.

Lẹyin ti wọn fi pampẹ ofin mu wọn tan ni wọn ko wọn sinu ọkọ akero ti wọn si gbe wọn lọ si ẹyin ibode ipinlẹ Ondo, ti wọn si ni ki wọn pada si ipinlẹ wọn.

Amotekun

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Nigba to n ba awọn akọroyi sọrọ, Adeleye ni awọn Fulani naa sọ pe ileeṣẹ kan ti kii ṣe ti ijọba ni awọn n ba ṣiṣẹ, ajọ naa lo si ko awọn wa.

Àkọlé fídíò, 'Bàbá, orúkọ yín rèé nínú ìwé òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì Nàìjíríà tó ti kú, kí 'ló ṣẹ́lẹ̀?'

O ni "Lati bii ọjọ mẹta sẹyin ni a ti n gbọ pe awọn Fulani n ya bo ipinlẹ Ondo, iwadii wa si fi han pe agbegbe Okitipupa ni wọn n gbà wọle, idi ree ti a fi ṣe ọfintoto wọn ti a si ri pe iwaju baraki awọn ologun ni wọn korajọ si."

"Nigba ti a ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun wọn, a ri pe wọn ko le ṣalaye ohun pato ti wọn wa ṣe ni ipinlẹ Ondo, pupọ ninu wọn si jẹ Fulani lati ipinlẹ Kano ati Jigawa."

Adeleye tẹsiwaju pe "Wọn ko le ṣalaye ohun ti wọn wa ṣe ni ipinlẹ Ondo ati bi wọn ṣe de ipinlẹ Ondo gan, nigba to ya wọn ni idanilẹkọọ ni awọn wa ṣe ṣugbọn wọn ko le ṣalaye ileeṣẹ to n ṣagbatẹru idanilẹkọọ ọhun."

Adari ikọ Maotekun naa tẹsiwaju pe ewu n bẹ loko longẹ ipinlẹ Ondo ti wọn ba fi wọn silẹ, eredi ree ti wọn fi da awọn eeyan naa pada si ipinlẹ wọn.

Lẹyin naa lo ṣeleri pe awọn ileeṣẹ eto abo ipinlẹ ọhun yoo tẹsiwaju lati maa daabo bo awọn eeyan ipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n fipá bá mi lòpọ̀ toyúntoyún títí tí mo pàdánú ọmọ náà, wọ́n jù mi sílẹ̀ níhòhò'