Nigeria bound travelers : Ọjọ́ mẹta sí asiko ìrìnàjò rẹ sí Nàìjíríà ni o gbọdọ̀ ṣe àyẹ̀wò Covid19

Abẹrẹ ajẹsara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orile-ede Naijiria ti din asiko ti esi ayẹwo Covid le gbe ọ da, ti o ba fẹ rinrin ajo si Naijiria lati ọjọ mẹrin si ọjọ mẹta.

Eyi tumọ si pe ti o ba fẹ rin irinajo si Nàìjíríà, to ba ku ọjọ mẹta lati gbera ni o to le ṣe ayẹwo aarun Covid-19.

Ṣaaju asiko yii, ọjọ mẹrin ni o maa n jẹ, Ṣugbọn o ti di ọjọ mẹta ninu atejade tí jọba fi sita lọjọ Aiku.

Akọwe agba fun Ijọba apapọ Naijiria, Boss Mustapha wipe ayewo PCR to ba ti ju ọjọ mẹta lọ ki eniyan to rin irin ajo wa si Naijiria ko ni jẹ itẹwọgba mọ.

Akọwe Ijọba to tun jẹ alaga igbimọ amusẹse lori Covid-19 tun sọ pe ọmọ Naijiria to ti sabẹwo si India, Brazil, Italy tabi Orile-ede kan to n fi oju wina aarun Covid-19 lọpọ bayii tabi ti iku Covid pọ nibẹ yoo ni lati ṣe ayẹwo Covid-19 wọn to ba ku ọla ti wọn yoo rinrin ajo.

O kede pe ijiya ẹsẹ fáànì owo $3,500 lori arinrinajo kọọkan fun ile ìṣe ọkọ ofurufu to ba ru ofin naa, wọn ko si ni gba ẹni tii kii se ọmọ Naijiria laaye lati wọ orile-ede yii rara.

"A rọ awọn ọmọ Naijiria lati yago fun irinajo ti ko se pataki lọ si oko okun, paapaa julọ awọn orileede ti aarun Covid-19 n peleke si nibẹ.

Àkọlé fídíò, 'Bàbá, orúkọ yín rèé nínú ìwé òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì Nàìjíríà tó ti kú, kí 'ló ṣẹ́lẹ̀?'

"Awọn ọmọ Naijiria ati awọn alejo to ni iwe igbelu sugbọn to ti rin irin ajo lọ si Brazil India tabi Turkey laarin ọjọ mẹrinla sẹyin ki wọn to wa si Naijiria yoo duro du iyasọtọ fun ọjọ meje ni ibi ti ijọba fọwọsi ni kete ti wọn ba ti wọ orileede yii, ọlọdani si ni yoo san owo to rọ mọ.

"Ẹnikẹni to ba wọ orileede Naijiria lati ibikíbi gbọdọ wa ni igbele ọjọ meje ti o ba de ibi ti o n lọ, bakan naa ni o gbọdọ ṣe ayẹwo Covid19 lẹyin ọjọ keje ni awọn ile ayẹwo ti ijọba fọwọsi."

Akọwe ijọba ni awọn gbe igbesẹ yii lati da abo bo orileede yii nitori bi aarun naa se n peleke si ti o si fa iku ọwọọwọ ni awọn orileede kan.