Isa Pantami: Ilé aṣòfin àgbà l'Abuja ní kò sí ẹ̀rí tó dájú láti yọ Pantami nípò mínísítà

Isa Pantami

Oríṣun àwòrán, Facebook/Isa Pantami

Ile aṣofin agba orilẹede Naijiria niluu Abuja ti sọ pe ko si ẹri to daju ti awọn le lo lati da minisita ẹrọ ibaraẹnisọrọ ati ọrọ aje, Isa Pantami duro lẹnu iṣẹ.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n ke pe ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari lati fun Pantami ni iwe gbele ẹ lori ẹsun pe o ṣe atilẹyin fun awọn ẹgbẹ agbesunmọmi.

Koda, fọnran ọrọ ti wọn ni Pantami sọ lati ṣe atilẹyin fawọn ẹgbẹ agbesunmọmi ti lu ori ayelujara pe.

Awọn kan tiẹ tun da ile aṣofin agba niluu Abuja lẹbi pe wọn ko ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ nigba ti wọn ṣe ayẹwo awọn orukọ awọn eeyan ti Buhari fi ranṣẹ sile fun ipo minisita.

Ṣugbọn nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, alaga igbimọ eto iroyin nile, Ọmọwe Ajibola Basiru sọ pe ile aṣofin ko lẹbi lori bi o ṣe buwọlu iyansipo Pantami gẹgẹ bi minisita.

Ọmọwe Basiru ṣalaye ko si ẹni to mu ẹjọ tabi ẹsun kankan wa lati tako iyansipo Pantami lasiko ti ile n ṣayẹwo awọn orukọ ti Buhari fi ṣowọ sawọn aṣofin.

''A ko ṣe ohun to lodin sofin, ko si ajọ eleto abo kankan to sọ ohun kan nipa Pantami to le mu wa maa buwọlu iyansipo rẹ lasiko ti a n ṣe ayẹwo rẹ to fi di asiko yii.

Awọn sẹnẹtọ ko lagbara lati yọ minisita nipo, a kan le ṣe ayẹwo lasan an ni pẹlu ohun ti a ba mọ nipa awọn ti aarẹ fẹ yan sipo minisita.

Aarẹ nikan lo lagbara lati yan minisita si ipo, oun naa lo si lagbara lati yọ minisita to ba yan si ipo kuro nipo.

A ko le titori ohun tawọn eeyan n sọ lori ayelujara lati gbe igbesẹ kan tabi omiran,'' Sẹnẹtọ Basiru ṣalaye.

Alaga igbimọ eto iroyin nile aṣofin agba sọ pe ko si ẹni to le tọka si ibi ti ofin ti sọ pe ile le yọ Pantami nipo ninu gbogbo awọn to n sọrọ lori ayelujara.

O ṣalaye pe Pantami ko tapa si ofin Naijiria lọna kọna, notiri idi eyi lawọn aṣofin ko le fi yọ nipo.