Insecurity: Ẹgbẹ́ àwọn ìjọ Penticostal darapọ̀ mọ́ àwọn tó ń jà fún òfin tuntun

Wale Oke

Ẹgbẹ awọn ijọ Penticostal ni Naijiria ti darapọ mọ igun awọn to n pe fun ofin tuntun fun orilẹede Naijiria.

Ẹgbẹ naa ni awọn kọ ṣiṣe agbeyẹwo ofin to ti wa nilẹ tẹlẹ eyi ti ile igbimọ aṣofin n pe fun fun lọwọlọwọ.

Ọrọ yii jade ninu atẹjade ti aarẹ ẹgbẹ Penticostal Fellowship of Nigeria (PFN), Biṣọọbu Francis Wale Oke ati olugbaninimọran ofin ẹgbẹ naa to jẹ amofin agba Naijiria, Funmi Quadri fọwọ si lọjọ Abamẹta.

Àkọlé fídíò, Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja

PFN ni awọn ọmọ Naijiria n pariwo atunto wọn si tun ni ṣiṣe agbeyẹwo ofin to ti wa tẹlẹ ko lee mu atunto ba Naijiria".

Atẹjade naa ka bayii pe, "ẹgbẹ PFN gbọ nipa agbeyẹwo iwe ofin eyi to n lọ lọwọ nile igbimọ aṣofin agba Naijiria ati ipade itagbangba ti ile aṣofin tun dajọ pe yoo waye lọjọ kẹrindinlọgbọn ati ọj kẹtadinlgbọn ọdun 2021 kaakiri ẹkun mẹfẹẹfa Naijiria".

Fun idi eyi, ẹgbẹ naa ni ofin ti Naijiria n lo lọwọ yii lo da bii ohun to gba ijọba isẹyii mu tako awọn eeyan, o si ni kọnu n kọhọ ninu.

Wale Oke and Buhari

Oríṣun àwòrán, Garba Shehu/TheNationNews

Àsìkò ti tó kí wọ́n yọ Buhari lórí oyè kí àlááfíà lè padà sí Naijiria - PFN, Kukah, Ighodalo

Awọn eekan ilu kan ti bu ẹnu ẹtẹ lu iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari lori eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.

Lara awọn to sọrọ naa ni Aarẹ Pentecostal Fellowship of Nigeria, PFN, alufa Wale Oke, to sọ pe Aarẹ ti kuna lati daabo bo awọn araalu ati pe asiko ti to ki wọn yọ ọ bii jiga ki alaafia le pada si Naijiria.

Wale Oke to jẹ alufa ijọ Sword of the Spirit Ministries to wa niluu Ibadan lo sọ ọrọ naa lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru nile ijọsin rẹ.

Ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ Aarẹ ọhun, Kayode Oladeji fi lede, o ni iṣọ oru naa waye ni fasiti ti ijọ naa da silẹ, iyẹn Precious Cornerstone University to wa niluu Ibadan.

Oke sọ pe pẹlu awọn iṣekupani to n waye lojojumọ, Naijiria ti dabi ọkan lara awọn orilẹ-ede ti ogun ti ogun abẹle n ba finra.

O ni "O yẹ ki wọn yọ Aarẹ kuro loir oye to ba jẹ ohun to le mu alaafia ba Naijiria niyẹn, lawọn ọdun 1960s, Naijiria ja ogun abẹle eyii to waye ni iha ila-oorun ilẹ yii."

"O jẹ ohun ibanujẹ pe lode oni, gbogbo ibi ni Najiria ni ogun ba finra pẹlu oniruru iṣekupani ati itajẹsile to n waye kaakiri ilẹ yii."

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n fipá bá mi lòpọ̀ toyúntoyún títí tí mo pàdánú ọmọ náà, wọ́n jù mi sílẹ̀ níhòhò'

Alufa naa tẹsiwaju pe awọn kọlọrọsi kan ji awọn akẹkọọ gbe ti wọn si bere owo itusilẹ to n lọ bii 800 miliọnu, wọn pa lara awọn akẹkọọ naa, ijọba Buhari ko si ri nnkankan ṣe si.

O tẹsiwaju pe "Wọn n ji awọn akẹkọọ gbe ti ko si si nnkankan ti ijọba n ṣe si, awọn kan si sọ pe ijọba to wa lode yii ko tii kuna ninu ojuṣe rẹ."

Wale Oke and Buhari

Oríṣun àwòrán, Garba Shehu/TheNationNews

"Ṣe nnkan ti wọn n sọ ni pe a ko lè lé ijọba to ba ojuṣe rẹ ku kuro lori oye ni?"

Ẹwẹ, Biṣọọbu ijọ katoliki ẹkun Sokoto, Mathew Kukah naa da si ọrọ naa nigba to n sọrọ nibi eto kan ti ijọ Covenant Christian Centre ṣagbatẹru rẹ pe inira ati eto abo to mẹhẹ lo n mu ẹmi awọn ọmọ Naijiria lọ.

O ni "Ojojumọ lawọn eeyan n ku ni Naijiria ijọba ko si kọbi ara si ju pe ki wọn lọ maa ki ẹbi awọn ti ẹmi wọn sọnu."

Kukah sọ pe atẹjade ti ileeṣẹ Aarẹ maa n fi lede ni gbogbo igba ti ajalu ba ṣẹlẹ ni Naijiria ko da nnkan fun awọn eeyan ilu.

Bakan naa ni pasitọ to wa lori ijọ Trinity House, Ituah Ighodalo bu ẹnu ẹtẹ lu Aarẹ fun bi ko ṣe kọbi ara si idojukọ awọn ọmọ Naijiria.

Ighodalo lo sọ ọrọ naa lasiko to n sọrọ nibi eto kan ti Africa Leadership Group ṣagbatẹru rẹ niluu Eko.

Alufaa naa ni "Ẹ jẹ ki n sọ fun yin ni kedere pe, ori tabili Aarẹ Muhammadu Buhari ni gbogbo iṣoro Naijiria wa, o si lagbara lati yanju awọn iṣoro naa to ba fẹ lati ṣe bẹẹ."

"Emi o mọ idi to ṣe kọ lati wa ojutu si awọn iṣoro ti a n dojukọ nilẹ yii, paapaa fun ẹni to ti fi igba kan ri jẹ ọga agba nileeṣẹ ologun, niṣe lo n ṣe bi pe ọrọ naa ko kan rara."

Ighodalo pari ọrọ rẹ pe ayipada kankan le ma de ba Naijiria ti awọn eeyan ilu ba kọ lati paarọ awọn to wa ni iṣakoso ijọba.