Ibadan Customs raid: Àṣẹ ti jáde kí Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè dá gbogbo ìrẹsì tí wọ́n kó padà

Oríṣun àwòrán, others
Igbimọ alabẹṣekele to n ri si ẹtọmọniyan nile igbimọ aṣofin orilẹede yii ti kesi ileeṣẹ aṣọbode lati da awọn apo irẹsi ati owo ti iroyin sọ wi pe awọn oṣiṣẹ ajọ naa ko ni awọn ilẹ itaja kan ni Ọja'ba ilu Ibadan pada.
Lopin ọṣẹ ti o kọja ni iroyin gbode kan wi pe awọn oṣiṣẹ aṣọbode yawọ ọja naa ti wọn si fi tirela mẹjọ ko apo iresi ati owo ti wọn ri ni awọn ṣọọbu kan lọ.
Igbesẹ naa si waye lẹyin ọsẹ diẹ ti wọn ko ọpọlọpọ irẹsi lọ l'oru mọju ninu ọja Bodija nilu Ibadan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé o mọ àwọn òrìṣà ìṣẹ̀mbáyé méje tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú?
- Ikú tó fẹ́ pa Opeyemi Ayeola ṣí i ní fìlà, ló bá ń kọrin ẹ fọ̀rọ̀ mi kọ́gbọ́n
- Nǹkan pàtàkì mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Salawa Abeni bí ó ṣe pé ọgọ́ta ọdún.
- Ayé ń pè wá ní 'Yeyebrity' torí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, nǹkan bà wá lágbo tíátà Yoruba"
- Wo àwọn olówó ayé tí ìgbéyàwó wọn ti wó lulẹ̀
- Ìyá àláwo tó di àjíhìnrere òjijì fi àwọn òrìṣà rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà
- Eré orí ìtàgé kọ́ ni pé Baba Ijesha ń tẹ ọmọ lára, ẹ yé gbè sẹ́yìn mi lọ́nà àìtọ́ - Yomi Fabiyi
Iṣẹlẹ yii lo mu ki Sẹnetọ Teslim Folarin to n ṣoju aarin gbungbun Ọyọ nile igbimọ aṣofin ti Sẹnetọ Kola Balogun fi ẹhonu han lori iwa ti ileeṣẹ aṣọbode n hu.
L'ọjọ Iṣẹgun ni aarẹ ile igbimọ aṣofin Ọmọwe Ahmad Lawan tọka ẹsun ti igbimọ alabẹṣekele naa fi kan ileeṣẹ aṣọbode lori i titapa si ẹtọmọniyan, ti o si koro oju si igbesẹ naa gẹgẹ bi i ohun ti ko jẹ itẹwọgba.
Lẹyin eleyii ni igbimọ naa paṣẹ fun alakoso ileeṣẹ aṣọbode, Hameed Ali ti oluranlọwọ rẹ, Garba Mohammed ṣoju fun lati ri i daju wi pe gbogbo nnkan ti wọn ko lo di dida pada laarin ọṣẹ meji.
Bakan naa ni igbimọ naa paṣẹ wi pe ki gbogbo ṣọọbu ti wọn ti pa di ṣiṣi pada, gẹgẹ bi wọn ṣe n da awọn owo ti wọn ko lọ pada.
Awọn aṣoju igbimọ naa pa ẹnu pọ sọ wi pe igbesẹ ileeṣẹ aṣọbode ko bojumu pẹlu alaye wi pe o tako ilana antẹlẹ ajọ naa ti aarẹ tẹlẹri, Oloye Olusegun Obasanjo buwọlu ni ọdun 2007.
Ilana antẹlẹ naa fi idi ẹ mulẹ wi pe ogoji kilomita ni ayika ibode ni awọn oṣiṣẹ ajọ naa ti ni ẹtọ lati gbẹsẹ le ẹru ofin.
Bí Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè ṣe fi tírélà kó ìrẹsì lọ lóru mọ́jú ní Ọjà'ba nílú Ibadan
Ni nnkan bi i aago meji oru ọjọ Abamẹta ni awọn oṣiṣẹ aṣọbode orilẹede Naijiria yawọ Ọja'ba nilu Ibadan ti wọn si fi tirela ko ọpọlọpọ apo irẹsi lọ.
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin oṣu kan ti wọn yawọ ọja Bodija l'oru ti wọn si ko ọpọlọpọ apo irẹsi lọ.
- Bukky Black sọ òkò ọ̀rọ̀ si Iyabo Ojo lori ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Gómìnà Kwara àtàwọn ṣọ́jà wọ ibùba ajínigbépawó, ọwọ́ tẹ ọ̀pọ̀ afurasí
- Àwọn ọlọ́pàá ti fi ṣìkún òfin mú 25 nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa tó ń ṣe ìwọ́de l'Abeokuta - Ilana Omo Oodua
- A kò bá ti lé Baba Ijesha àmọ́ kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, a kò sì fọwọ́ sí ìwà tó hù - Mr Latin
Alukoro ileeṣẹ aṣọbode ni agbegbe Ọyọ ati Ọṣun, Kayode Wey fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣugbọn o ṣe alaye wi pe ẹka ileeṣẹ naa to jẹ ti ijọba apapọ, "Federal Operation Unit (FOU) Zone A" lo yawọ ọja naa.O fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn oṣiṣẹ yii kan naa lo ko irẹsi ni ọja Bodija.
Ẹni ti o jẹ alukoro fun ilẹẹṣẹ aṣọbode fun ijọba apapọ, FOU, Arakunrin Theophilus Duniya naa fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ lori ẹrọ ibanisọrọ, Duniya ni ileeṣẹ aṣọbode ni agbara lati gbe igbesẹ naa, paapaa julọ nitori pe ijọba ti gbẹsẹ le kiko irẹsi wọ Naijiria lati ilẹ okere ki ipẹsẹ rẹsi le gberu si i labẹnu.

O fi kun ọrọ rẹ pe ẹru ofin ni irẹsi ti ẹnikẹni ba ko wọle lati ilẹ okere. Eyii lo si fun ile iṣẹ aṣọbode ni agbara lati yawọ ibikibi ki wọn si ko ẹru ofin jade.Lara awọn ontaja ti wọn ko ọja wọn lọ gbarata wi pe lati ọwọ awọn ẹya Hausa ni awọn ti ra pupọ awọn irẹsi ti awọn n ta n'Ibadan.
Wọn ni bi igba ti ileeṣẹ aṣọbode kan doju le wọn ni awọn ọja wọn ti wọn n ko ni lemọlemọ. Wọn fi kun ọrọ wọn wi pe iru igbesẹ bẹẹ ki i waye ni ilẹ Hausa ti wọn ti n ko irẹsi naa wọle.Wọn parọwa si ijọba lati ja fun gbeja wọn ja lori ọrọ naa.













