Queen Salawa Abeni Waka Queen àti ohun mẹ́wàá tíó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/salawa abeni
Queen Salawa Abeni bẹrẹ iṣẹ orin gẹgẹ bi iṣẹ aje lati igba to ti wa ni ọdun mẹwaa, o kan lọ ba ọkan lara awọn asaaju ninu iṣẹ gbigbe orin jade nilu Eko o si bẹbẹ pe ko jẹ ki oun kọ orin ki wọn ri nkan ti oun le se.
Sugbọn wọn ko fun un ni anfaani nitori wọn foju ọmọkekere wo o ati pe ko si nnkan to ni laari kan ti o le se.
Ko pẹ si asiko naa ni agbaọjẹ abanigbe orin jade yii ba a nibi kan ni agbegbe Ẹpẹ nibi ti o ti n fi orin da awọn eniyan laraya ti ero si pe biba sibẹ.
Lọgan lo gbe e lọ lati gba orin rẹ silẹ, lati igba yii ni wọn ti bẹrẹ si ni tọ sọna gẹgẹ bi ọkan ninu awọn gbajugbaja olorin to lamilaaka ni Naijiria.
Lasiko kan sẹyin ni Waka Queen ṣe aisan, ọpọ lo si ti ro pe aisan ọhun ni yoo mu opin ba gbajugbaja naa, ṣugbọn, o ru u la.
Pẹlu iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria ati ijọba ipinlẹ Eko, Tinubu, Fashola ati Ambode ni Salawa ni Ọlọrun lo fun oun, o bọ lọwọ aisan rọparọsẹ to kọlu u to si ti n ṣe daada lati igba naa.

Oríṣun àwòrán, Instagram/salawa abeni
Lẹyin eyi lo tun ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesi aye rẹ ninu iṣẹ orin.
Awọn nnkan mẹwaa ti o yẹ ki o mọ nipa Salawa Abeni ree, akikanju obinrin to nigbagbọ ninu ara rẹ pe oun le ṣe daada pẹlu atilẹyin awọn obi rẹ.
1. Salawa Abeni bẹrẹ orin kikọ lati ọmọ ọdun mẹsan sugbọn o sọ di iṣẹ aṣela lati wa ounjẹ oojọ ni igba to pe ọmọ ọdun mẹwaa.
2. O gbe awo orin akọkọ jade ni ọdun 1976 to pe akọle rẹ ni General Muritala Ramat Muhammed labẹ asia Leader Records.
3. Oun ni obinrin akọkọ to gbe orin jade to si ta kasẹẹti to le ni miliọnu kan ni Naijiria, orin akọkọ to se jade ni pẹlu.
4. Nigba ti o wa ni ọdun mẹrindilogun, Salawa Abeni da ẹgbẹ orin kalẹ to pe ni The Waka Modernisers lọdun 1977.

Oríṣun àwòrán, Instagram/salawa abeni
5. Leader Records lo wa lati ọdun 1976 si ọdun 1985, o si ṣe agbekalẹ orin mẹrinla laarin asiko naa.
6. O figba kan fẹ gbajugbaja olorin, Alhaji Killington Ayinla ti gbogbo eniyan mọ si Kollington ti wọn si bi awọn ọmọ lara wọn ni Sheriff ati Okikiola. Bakan naa lo padanu ọmọ kan ri, eyi to bi fun Lati Adepoju.
7. O darapọ mọ rẹkọọdu Kollington lasiko ti wọn n fẹ ara wọn laarin ọdun 1986 titi di 1994 nigba ti wọn tuka.
8. Labẹ Kollinton Records, awo orin mẹwaa lo gbe jade.
9. Ọdun 1992 ni Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi fun ni oye Waka Queen orin.

Oríṣun àwòrán, Instagram/salawa abeni
10. Ọkan ninu ọmọ ti Salawa bi fun Kollington Ayinla, Sheriff tọpasẹ awọn obi rẹ bi oun naa ṣe n kọ orin taka sufe pẹlu orukọ Big Sheriff.
Oun ati Waka Queen ṣe atunkọ orin rẹ Gentle Lady ni mi.













