Nana Agradaa: Ìyá aláwo sogún-dogójì tó di oníwàásù ọ̀sàn gangan

Nana Agradaa

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán, Nana Agradaa sọ pe Ajihinrere Patricia Oduro Koranteng ni orukọ oun tuntun

Ere ni, awada ni, ko jẹ ri bẹẹ ni ọpọlọpọ eeyan n sọ lẹyin ti gbajugbaja Iya alawo kan to gbojugboya, kede pe oun ko ṣoogun mọ, ti oun si ti gbe agogo igbala bayii.

Mama Alawo naa, to jẹ gbajugbaja lorilẹ-ede Ghana, Nana Agradaa lo kede ayipada naa, lẹyin ti awọn ọlọpaa gba beeli rẹ ni ọsẹ to kọja.

Ẹsun ti wọn fi kan Agradaa ni pe o ni ileeṣẹ amohunmaworan meji ti ko ni iwe aṣẹ ijọba.

Amọ, itusilẹ rẹ kii ṣe ọfẹ, nitori pe ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta GHc, tii se owo orilẹ-ede Ghana lo san gẹgẹ bi owo itanran.

Ṣugbọn tako ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan-an, ọpọ eeyan lo gbagbọ pe awọn ọlọpaa mu iya alawo naa nitori pe o n polowo oogun abẹnu-gọngọ "sika gari", to n sogun di ogoji.

Àkọlé fídíò, Àwọn to n bá ẹlẹkun sunkún ní Ghana

Ori amohunmaworan Thunder TV ati Ice TV to da silẹ lo ti maa n ṣe afihan bo ṣe n ṣe etutu ati irubọ, to si ma n sọ pe awọn oriṣa oun le sọ owo di ilọpo meji.

Eyi gan-an lo mu ki o jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ eniyan nigba ti Mama Alawo naa deedee pẹyinda lẹyin awọn oriṣa rẹ, lẹyin to bọ lọwọ ọlọpaa, to si n sọ pe oun ti di atunbi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn, awọn eeyan kan lori ayelujara gbagbọ pe, ikede to ṣe le jẹ ọgbọn ẹwẹ lati fi ẹsin Kristiẹni boju, ko si tẹsiwaju pẹlu oogun sogun di ogoji to n ṣe.

Bakan naa ni Mama Alawo naa tun tọrọ aforiji lọwọ awọn eeyan ti igbesẹ rẹ gẹgẹ bi alawo ba ni ipa ti ko dara ninu igbe aye wọn.

Àkọlé fídíò, Oloye Ìdòwú Olukunle so pe babalawo lo le mo òun ti ọ̀sándòru yóò já sí fun ara ilu.

Nana Agradaa sọ pe Ajihinrere Patricia Oduro Koranteng ni orukọ oun tuntun

Yatọ si pe o yẹyẹ awọn oriṣa rẹ ni gbangba, Agradaa tun sọ pe oun yoo ranṣẹ pe awọn pasitọ lati pa awọn osiṣa to wa ni ojubọ rẹ run.