Albinism: Èèmọ̀ rèé o! Kí ló lè mú kí àfín 114 di àwátì?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan lapa gusu ilẹ Afirika ti sọ pe ọpọ awọn afin lo si n tun di awati lorilẹede Mozambique di akoko yii.
Ajọ naa ṣalaye pe ẹjọ to niṣe pẹlu awọn afin to di awati le ni marunlelaadọta to wa nile ẹjọ bayii.
Ajọ ajafẹtọ naa sọ pe o kere tan, afin mẹrinlelaadọfa lo ti di awati ni ọdun bii meje sẹyin.
- Taye jẹ́ eni dúdú, Kehinde jẹ́ àfín; báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
- Sunday Igboho ṣẹ̀ sí òfin ète ìdìtẹ̀ gbàjọba, ó sì le fojú winá òfin - Amofin
- Afurasí olóṣèlú tí ọlọ́pàá mú lórí ikú ọmọ mi, ló jẹ́ alátakò rẹ̀ nínú PDP - Baba Aborode
- Jimoh Odutola, akọni oníṣòwò tí kò kàwé, àmọ́ táwọn Ààrẹ orílẹ̀-èdè ń ké sí láti wá dá iléesẹ́
- Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Samia Suluhu Hassan tó di aarẹ Tanzania lẹ́yìn ikú Magufuli
- Ọ́lọ́pàá gbé èèkàn PDP l‘Oyo lọ ileẹjọ́ lórí ikú Fatai Aborode
Awọn eeyan kan maa n pa awọn afin lapa ila oorun ati gusu Afirika.
Igbagbọ awọn eeyan ni pe wọn maa n lo ẹya ara afin fun oogun owo ati oogun ifẹ.
Ajọ to n ri si ẹtọ ọmọniyan ni Mozambique, CNDH ṣe agbekalẹ ijiroro kan niluu Maputo lati fọrọ jomitoro ọrọ lori iwa idẹyeṣi tawọn afin bi ẹgbẹrun lọna ogun n doju kọ.
Sheila Massuque to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ CNDH ṣalaye pe ọpọ afin lawọn ẹbi wọn ti kọ silẹ nigba ti awọn mii ti ṣagbako iku ojiji.

Ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ eto idajọ sọ pe ijọba n gbiyanju lati daabo bo awọn afin.
Awọn afin to wa lorilẹede Mozambique sọ awọn ile iwosan maa n dẹyẹ si awọn lasiko ajakalẹ arun coronavirus.
Wọn ni ọpọ igba ni wọn maa n da awọn pada.












