Ibrahim Attahiru: Buhari àti Osinbajo kò lọ fún ìsìnkú àwọn ọmọ ogun, ọmọ Naijiria yarí

Buhari ati Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oriṣiriṣi oko ọrọ ni awọn ọmọ Naijiria ti n ju lu Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo, paapaa lori Twitter, nitori bi wọn ko ṣe lọ sibi isinku ọga awọn ọmọ ogun ati awọn ọmọ ogun mẹwa mii to ku ninu ijamba baalu lọjọ Ẹti.

Ọjọ Satide ni wọn sin oku General Ibrahim Attahiru ati awọn yooku ti wọn ba iṣẹlẹ naa rin ni ilu Abuja.

Ọgagun mẹta mii lo tun wa ninu baalu naa.

Botilẹ jẹ pe Buhari sọ ninu atẹjade kan pe iku awọn eeyan naa jẹ iyalẹnu ati ibanujẹ fun oun, minisita fun eto aabo, Ajagunfẹhinti Bashir Magashir, lo ṣoju rẹ nibi ayẹyẹ isinku naa.

Àkọlé fídíò, Mo dúpẹ́ pé ìgbà tí mo wà nínú Jesu ni mo lọ sẹ́wọ̀n, tó bá jẹ́ pé mo wà nínú áyé ni ... - Wòlìí Genesis

Lootọ ni awọn eekan ilu kan wa nibi isinku naa, ṣugbọn aisi nibẹ Buhari jẹ awọn ọmọ Naijiria logun pupọ.

Awọn kan ri iku awọn sọja naa gẹgẹ bi adanu nla ni Naijiria, ti wọn si sọ pe bi Buhari ati Osinbajo ko ṣe lọ fun isinku wọn tumọ si pe ẹni awọn ọmọ ogun ko jamọ nkankan loju wọn.

Ṣugbọn, awọn kan tun sọ pe awuyewuye to n waye naa ko ni itumọ, pe nkan to ṣe pataki julọ fun awọn ọmọ Naijiria ni lati ṣọfọ ki wọn o si gbadura fun orilẹ-ede wọn nitori adanu yii.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

@FaladeTolu_ sọ pe Buhari ko bọwọ fun iku ọga agba nileeṣẹ ologun, ṣe a wa le sọ pe ẹmi awọn to wa loju ogun ja mọ nkankan lọwọ rẹ?

Awọn ọmọ Naijiria kan ṣe atilẹyin fun Buhari.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

@GoziconC sọ pe "ṣe Goodluck Jonathan lọ fun isinku ọga rẹ, Aarẹ Umaru Musa Yar'adua lọdun 2010... ti ko ba ti si ẹni to le fi aworan han pe o wa nibẹ, ẹ kẹ ka sọ nkan mii."

@xndagi ni tiẹ sọ pe kii ṣe ẹṣẹ tabi ọtẹ bi Buhari ko ṣe lọ fun isinku naa. O ni ẹnikẹni ti inu ba n bi, le gbe majele jẹ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Wo àwọn àwòràn láti ibi ìsìnkú àwọn ọmọ ogun Naijiria tó kú nínú ìjàmbá bàálù ní Kaduna

Awọn ọmọ ologun ofurufu duro ti posi oku ọkan lara awọn akẹẹgbẹ wọn to ba ijamba naa lọ.

Oríṣun àwòrán, Nigerian army

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ologun ofurufu duro ti posi oku ọkan lara awọn akẹẹgbẹ wọn to ba ijamba naa lọ.

Eto isinku ti n waye fun awọn ọmọ ogun Naijiria to padanu ẹmi wọn ninu ijamba baalu to waye ni Kaduna lọjọ Ẹti.

Iyawo oloogbe naa lo wọ aṣọ dudu, lasiko to de mọṣalaṣi Grand Central Mosque, Abuja, nibi ti eto isinku ọkọ rẹ ti waye
Àkọlé àwòrán, Iyawo oloogbe naa lo wọ aṣọ dudu, lasiko to de mọṣalaṣi Grand Central Mosque, Abuja, nibi ti eto isinku ọkọ rẹ ti waye
Ọkọ̀ yii ni wọn fi gbe oku ọgagun naa wa si Mọṣalaaṣi nla ti ilu Abuja
Àkọlé àwòrán, Ọkọ̀ yii ni wọn fi gbe oku ọgagun naa wa si Mọṣalaaṣi nla ti ilu Abuja
Awọn iboji yii ni wọn ti gbẹ silẹ fun oku ọgagun naa, ati awọn ọmọ ogun to ku pẹlu rẹ ninu ijamba baalu naa to waye ni Kaduna lọjọ Ẹti.
Àkọlé àwòrán, Awọn iboji yii ni wọn ti gbẹ silẹ fun oku ọgagun naa, ati awọn ọmọ ogun to ku pẹlu rẹ ninu ijamba baalu naa to waye ni Kaduna lọjọ Ẹti.
Awọn to gbe oku lọ si iboji

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad

Awọn to peju sibi isinku

Oríṣun àwòrán, Nigerian army

Bayii ni awọn ọmọ ogun ṣe fi ibọn yinyin dagbere fun awọn akẹẹgbẹ wọn to kú

Oríṣun àwòrán, Nigerian army

Àkọlé àwòrán, Bayii ni awọn ọmọ ogun ṣe fi ibọn yinyin dagbere fun awọn akẹẹgbẹ wọn to kú
Aṣoju aarẹ Buhari n gbe asia orilẹ-ede Naijiria fun ẹbi awọn oloogbe

Oríṣun àwòrán, Nigerian army

Àkọlé àwòrán, Aṣoju aarẹ Buhari n gbe asia orilẹ-ede Naijiria fun ẹbi awọn oloogbe
Diẹ lara ẹbi awọn oloogbe nibi eto isinku naa lasiko ti wọn n tẹwọ gba asia Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigerian army

Àkọlé àwòrán, Diẹ lara ẹbi awọn oloogbe nibi eto isinku naa lasiko ti wọn n tẹwọ gba asia Naijiria

Àdánù àti ìbànújẹ́ ńlá ni iku ọgá àgbà àwọn ọmọgun Nàìjíríà jẹ́ -Ààrẹ Buhari

Aworan aarẹ Buhari ati ọga agba awọn ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency

Minisita feto aabo Naijriia ti kan si aarẹ Muhammadu Buhari lati fi iroyin iku ọga agba awọn ọmọ ogun Naijiria to leti nile ijọba lAbuja.

Lalẹ ọjọ Ẹti ni abẹwo yi waye lẹyin ti ọkọ baalu to n gbe Ọgagun Ibrahim Attahiru ati awọn ọmọ ogun Naijiria mẹwaa mii kagbako ni papakọ ofurufu Kaduna.

Aarẹ Buhari ṣapejuwe iku awọn ọmọ ogun yi gẹgẹ bi adanu ati ibanujẹ nla to ṣi ṣapejuwe wọn ''gẹgẹ bi akinkanju to fi ẹmi wọn lele fun alaafia ati aabo Naijiria''

Aarẹ nikan kọ lo kẹdun iku wọn, Gomina ipinlẹ Kaduna Nasir El Rufai naa ti sọrọ lori iṣẹlẹ yi.

El Rufai ṣapejuwe Ọgagun Ibrahim gẹgẹ bi ''irawọ to n tan ti iku rẹ mu ki Naijiria padanu akin to n ṣapa lati koju ọta ilẹ yi''

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ni bayi, ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria labẹ akoso ọgagun agba ẹka alaabo,Lucky Irabor ti ni ki wọn ṣe agbekal igbimọ iwaii lori iṣẹlẹ naa.

O ni awọn ọmọ ogun ko ni yẹ ko ni gbo nipa kikoju awọn ipenija aabo to n ba ba Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi

Wọn yi lorukọ awọn mii to kọwọrin pẹlu Ọgagun Ibrahim Attahiru:

1. LT GEN I ATTAHIRU.2. BRIG GEN MI ABDULKADIR.3. BRIG GEN OLAYINKA.4. BRIG GEN KULIYA.5. MAJ LA HAYAT.6. MAJ HAMZA.7. SGT UMAR.8. FLT LT TO ASANIYI.9. FLT LT AA OLUFADE.10. SGT ADESINA.11. ACM OYEDEPO.

Aworan ọga agba awọn ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency

Ìròyìn tó n tẹ̀ wá lọ́wọ́ nísìyí ń sọ pé, ọkọ̀ òfurufú ti ọmọ ogun ojú òfurufú wà nínú rẹ̀ já, ni alẹ́ yìí.

Ǹkan tó ṣe okùnfa ìṣẹ̀lẹ̀ kò tí sí ẹni to le fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Nínú àtẹ̀jáde kan ti adari ètò ìròyìn àti ìbá ará ìlú ṣe Edward Gabkwet fọwọ́sí sàlàyé pé ìwádìí sì n lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Ìròyìn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, olórí ọmọ ogun Nàìjíríà Ibrahim Attahiru wà nínú ọkọ̀ ofurufu náà, tí ó sì ti jẹ́ ọlọ́run nipe

Gẹ́gẹ́ bi agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọmọ ogun Yerima Muhammed ṣe fi ìdí rẹ̀múlẹ̀ fún BBC.

Ó ní, ọ̀gá àgbà àti àwọn èèkàn mííràn ń lọ sí Kaduna fún ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde àwọn ọmọogun ni Kaduna

Yerima sọ fún BBC pé ènìyàn mẹ́jọ ló wà nínú ọkọ̀ òfurufu náà.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Tani Ibrahim Attahiru?

A bi Attahiru ni ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹjọ ọdún 1966 ni Doka ìjọba Ibilẹ Kaduna North ìpínll Kaduna, tí ó sì kàwé gboye ni ilé ẹkọ́ àwọn ọmọ Pgun Naìjíríà.

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ẹka ọmọogun ni oṣù kíní ọdún 1984 tí ó sì gba ipì líetinant ni ọdún 1986

Ó kàwé gbá oyè onípò kejì nínú ìmọ̀ ètò ọmọ ògun (Strategic Managbement and Policy Studies)

Ọ̀gágún àgbà naáà ti di oníruuru ipò mú ninu iṣẹ́ tó yà láàyò.

Attahiru sáájú ètò BARASS ninu oṣù kẹsan ọdún 2000 nibi tó ti salaboju tó ètò àwọn ọmọ ogun ilé gẹ́ẹ̀sì.

Bákana náà lo darí NIBATT 19 ECOMOG ni Liberia.