NCC IMEI: Irọ́ ni, a kò bèèrè fún nọ́mbà IMEI àwon olùgbé Nàìjíríà- NCC

Aworan obinrin to mu foonu lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Saaju ni iroyin ti jade pe ajo NCC to n mojuto ọ̀na ibaraenisọ̀rọ̀ ni Najiria ti ni ki awon olugbe Naijiria fi nomba International Mobile Equipment Identity (IMEI) to wa lori ẹ̀rọ alagbeka wọn silẹ̀ lati osu keje, ọdun 2021.

Omowe Ikechukwu Adinde to jẹ́ oludari ẹ̀ka ifitonileti ara ilu fun ajo Nigerian Communications Commission ti fi ikede sita pe iroyin to jina si ootọ ni ọ̀rọ̀ naa.

O ni ajọ NCC ko figba kankan beere fun nomba yii lọ́wọ́ awọ́n eeyan ni Naijiria.

O ni gbigba nomba yii waye lati ọ̀dọ̀ awon ẹ̀ka Revised National Identity Policy for SIM Card Registration ti o jẹ́ ọ̀kan lara awon ajotuntun ti Aare Buhari da sile lo fi soju opo itakun agbaye.

Àkọlé fídíò, Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

O ni ajo yii ti setan lati seto Device Management System (DMS). ni eyi to ma je ki o rorun lati ko awon ayederu nọ́mba kuro nilẹ̀

Ikechukwu ni kete ti eeyan ba ti se iforukosile naa ni ẹ̀rọ naa yoo funra re gbe nomba IMEI iru eni bẹ́ẹ̀ sita lai jẹ́ pe eeyan tun sẹ̀sẹ̀ lọ n seto iforukosilẹ̀ miran

O ni fun idi eyi, ki awon eeyan lo fọkan balẹ̀ pe wọ́n yoo tun lọ to seto iforukosilẹ̀ IMEI

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Kí ni IMEI ara fóònù àtí ìwúlò rẹ̀, tí ìjọba fi ń béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ aráàlú?

Wo àǹfààní nọ́mbà yìí àti bo ṣe le ṣàwárí rẹ̀ lára fóònù rẹ

Ikede ti ajọ to n risi eto ibaraẹnisọrọ ni Naijiria NCC gbe jade pe ki awọn ọmọ Naijiria fi nọmba IMEI wọn ṣọwọ, jẹ eyi tawọn eeyan n ran lẹnu.

Gẹgẹ bi awọn ikede miran ti wọn gbe jade ṣaaju, paapa nipa siimu ati nọmba NIN, pupọ lo n beere pe ki ni wọn tun fẹ fi nọmba yii ṣe.

Ninu nkan ti wọn sọ pe awọn fẹ fi nọmba naa ṣe ni idena jiji foonu, didaabo bo onibara ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ, pipawo wọle fun ijọba ati mimu adinku ba ijinigbe tabi lilo foonu lati fi hu iwa ọdaran.

Bo tilẹ jẹ pe awa ko le gbẹnu wọn sọrọ lori erongba wọn lẹkunrẹrẹ, a gbiyanju lati ṣe iwadii ki gan nipa nọmba yii, ati ipa to n ko ninu eto ibaraẹnisọrọ.

Ninu iwadii wa, awọn koko bii meloo kan jẹ jade, ta lero pe yoo wulo fun mutumuwa.

Diẹ ninu wọn ree:

Itumọ Nọmba IMEI:

Ibi lẹbẹ la a ti mu ọọlẹ jẹ nitori naa, ki a kọkọ ṣe alaye lori itumọ IMEI.

Lede Gẹẹsi, IMEI tunmọ si International Mobile Equipment Identity (IMEI) eyi to tumọ si nọmba idamọ foonu alagbeka kọọkan, ta fi ṣe idanimọ foonu rẹ.

Lara batiri foonu ni wọn maa n tẹ nọmba naa si ṣugbọn bi ẹ ba tẹ nọmba *#06# lori foonu yin, yoo jade soju iran rẹ.

Àkọlé fídíò, Bi o ṣe lè mọ̀ tí káádì inú ẹ̀rọ ìléwọ rẹ kọ bá sí nínú àkọsílẹ̀

Mẹẹdogun ni nọmba naa jẹ ati pe awọn foonu to ba laaye ibi taa fi siimu si, lo maa n ni nọmba yii.

Bi foonu ba jẹ sim-less, o ṣeeṣe ki o ma ni nọmba yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbakigba ti eeyan ba pe lori foonu, akọsilẹ a maa wa loju opo ibaraẹnisọrọ nipa nọmba ti eeyan fi pe ati nọmba IMEI foonu to lo.

Koko Pataki nkan ti a n lo nọmba IMEI fun:

Lati le da foonu kọọkan mọ loju opo ibaraẹnisọrọ ni nọmba yii wa fun, nitori pe ọkan ko papọ mọ ekeji.

Ti foonu Tagbaja yatọ si ti Tamẹdun, ko si papọ rara, foonu kọọkan ti eeyan si n lo lo ni nọmba IMEI tiẹ lọkọọkan.

Idaabo bo ni o wa fun ati idanimọ paapa ti foonu ba sọnu tabi ti wọn ba ji foonu gbe.

Tawọn ole ba ji foonu rẹ, IMEI yi ni o le fi da mọ, koda ki wọn yọ siimu rẹ kuro ninu rẹ.

USSD

Bi o ba tete fi to ileesẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ leti pe wọn ji foonu rẹ, wọn le ti foonu rẹ pa, ti elomiran ko ni ribi lo, koda ko fi siimu mi sori rẹ.

Bakan naa, awọn agbofinro le lo irinsẹ itọpinpin foonu lati mọ aaye ibi ti foonu rẹ ba wa .

Ni soki, idaabo lọwọ awọn to ba ji foonu gbe ni koko idi ti nọmba yii fi ṣe pataki.

IMEI ati Ofin orileede nipa ibaraẹnisọrọ:

Nkan ti ijọba sọ nipa ki awọn eeyan fi nọmba IMEI wọn sọwọ sileeṣẹ NCC, nii ṣe pẹlu atunto ilana eto idanimọ iforukọsilẹ siimu, ta mọ si National Identity Policy for SIM Card Registration.

Ninu alaye atẹjade ti wọn fi sita wọn ni awọn fẹ ṣe akojọ nọmba IMEI wọn yii labẹ eto kan ti wọn pe ni Centralised Equipment Identity Register.

Rẹjisita yii ni awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ kọọkan yoo maa kan si, lati le mọ IMEI ati awọn iroyin miran nipa eeyan kọọkan to ba ni foonu ni Naijiria.

Locked phone

Iru nnkan bayii kii ṣe tuntun nitori awọn orileede mii bi ilẹ Gẹẹsi, New Zealand, Saudi to fi mọ Latvia ni agbekalẹ ofin to de gbigba ati lilo IMEI.

Koda ni Amẹrika, ijọba wọn figba kan pọn ni dandan pe ki awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ leto ti wọn yoo fi maa ti foonu pa, ta mọ si blocklisting service.

IMEI rẹ ṣe yi pada:

Pẹlu gbogbo nkan ta a n sọ lori IMEI yii, njẹ o mọ wi pe o le yi nọmba IMEI rẹ pada?

Bẹẹ ni. Bi eeyan ba ni irinṣẹ to le ṣe nnkan yii, o ṣeeṣe ki o yi nọmba naa pada.

Ni awọn orilẹede bi Amẹrika, ko lodi sofin lati paarọ IMEI ori foonu rẹ lopin igba too ba ti fẹ fi ṣe magomago.

Uganda mobile phone user

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Amọ ni ilẹ Gẹẹsi, piparọ IMEI tabi nini irinṣẹ ti eeyan le fi paarọ IMEI jẹ ohun to lodi sofin lawọn aaye kọọkan.

Ni India, ẹwọn ọdun mẹta ni ofin gbe kalẹ fun ẹnikẹni to ba yi nọmba IMEI pada tabi to n lo IMEI nọmba ayederu.

Yatọ si awọn ileeṣẹ to se foonu, ko si igbalaye fun awọn mii lati yi nọmba naa pada.

A ko le sọ boya eyi tako ofin ni Naijiria lati yi IMEI pada tabi ko tako ofin.