Oyo local government election: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti fòfin de lílọ àti bíbọ̀ ọkọ̀ láti aago mẹ́fà sí mẹ́ta ọ̀sán nítorí ìdìbò ọ̀la

Idibo Oyo

Ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ ti fun awọn alaga ijọba ibilẹ mejilelọgbọn to jawe olubori ni iwe eri iyanisipo.

L'ọjọ Aje ni alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, Aarẹ Isiaka Ọlagunju fi iwe ẹri iyanisipo le awọn alaga ijọba ibilẹ mejilelọgbọn ti awọn ara ilu dibo yan lọwọ.

Awọn to jawe olubori

Ninu ọrọ ti o sọ lẹyin ti o fun wọn ni iwe ẹri naa, Ọlagunju parọwa si awọn alaga tuntun lati ma ja awọn eeyan ilu to fun wọn ni anfani iyansipo kulẹ.

O kesi wọn lati riidaju wi pe wọn mu awọn ileri ti wọn ṣe lasiko ipolongo ibo ṣẹ.

Àkọlé fídíò, Mo dúpẹ́ pé ìgbà tí mo wà nínú Jesu ni mo lọ sẹ́wọ̀n, tó bá jẹ́ pé mo wà nínú áyé ni ... - Wòlìí Genesis

Lara awọn alaga ajọ eleto idibo fun ni iwe ẹri ni: Arakunrin Raheem Akeem Adepoju (Oorelope), Sulaiman Adediran (Irepo), Arabinrin Juliana Oluwakemi Akanni (Olorunsogo), Akanji Kabir Ayoade (Ogbomoso North), Oyeniyi Timothy Oyedokun (Ogbomoso South), Olugbenga Obalowo (Ibarapa East).

Jelili Oyinloye Adebare (Iwajowa), Fasasi Adeagbo (ATISBO), Arabinrin Ramat Adeniran (Saki-East), Sarafadeen Omirinde (Saki-West), Adebare Muraina Afolabi (Kajola), Adesoye Seun Ojo (Ogo-Oluwa) ati Bolaji Ojo Akintola (Itesiwaju).

Awọn to jawe olubori

Awọn omii ni; Olateju Michael Alabi (Oriire), Adegbite Isaiah Alabi (Surulere), Adedoyin Oloyede Adeoye (Ibarapa Central), Lateef Adebayo Lawal (Ibarapa North), Muftau Osuolale (Iseyin) ati Sunday Akindele Ojo (Afijio).

Ajọ naa ti kede rẹ wi pe atundi ibo yoo waye ni ijọba ibilẹ Ido l'Ọjọru.

Ayipada naa waye nitori aikopa ẹgbẹ oṣelu ZLP nibi eto idibo ọjọ Abamẹta nipasẹ iyọkuro ami idanimọ ẹgbẹ oṣelu naa ninu iwe idibo.

Oyo

Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo fòfin de lílọ àti bíbọ̀ ọkọ̀ láti aago mẹ́fà sí mẹ́ta ọ̀sán nítorí ìdìbò ọ̀la

Makinde

Oríṣun àwòrán, @Makinde

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti fi ofin de lilọbibọ laarin aago mẹfa owurọ si mẹta ọsan nitori eto idibo ọjọ Satide

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti kede rẹ wi pe ko ni si anfani fun lilọbibọ awọn eeyan ati igbokegbodo ọkọ laarin aago mẹfa owurọ si mẹta ọsan ọjọ Abamẹta.

Atẹjade ti wọn fi lede lati ọwọ akọwe ijọba ipinlẹ Ọyọ, Arabinrin Olubamiwo Adeosun kede rẹ.

Akowe ijoba ipinle Oyo ni wi pe ofin ti wọn fi de lilọbibọ pọn dandan ki awọn oludibo ni ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to n bẹ ni ipinlẹ Ọyọ le ṣe ojuṣe wọn ni irorun ninu eto idibo ti yoo waye lọjọ kejilelogun oṣu kaarun ọdun yii.

Àkọlé fídíò, Down Syndrome Skill centre: Wo bí ọmọ tí ọpọlọ wọn kù díẹ̀ ṣe ń kọ́ iṣẹ́ agẹrun

Atẹjade naa tọka rẹ wi pe lilọbibọ awọn eeyan ati ọkọ akẹru ko ni waye laarin aago mẹfa owurọ si mẹta ọsan ki awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ naa le ṣiṣẹ wọn lai si idiwo tabi idena.

Àkọlé fídíò, Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

Ajọ naa kesi gbogbo awọn oludibo to ti fi orukọ silẹ lati kopa ninu ibo naa ki wọn si tẹlẹ ofin ijọba, pẹlu afikun wi pe awọn eeyan to fẹ nnkan pataki ti ofin ti lẹyin nikan ni yoo laarin lati rin soke-sodo ni asiko yii.

Makinde ladoja

Oríṣun àwòrán, @others