Phone stealing: Iléẹjọ́ ní kí Yakubu gé oko àgọ́ ọlọ́pàá fọ́jọ́ méjì lẹ́yìn tó jí fóònù N8,700

Ileẹjọ majisireeti to wa ni Gwagwalada niluu Abuja ti dajọ pe ki ọmọkunrin kan Akeem Yakubu ge oko fun ọjọ meji ni agọ ọlọpaa to wa ni Gwagwalada.
Adajọ majisireeti Aliyu Shafa paṣẹ pe eyi ni iya ẹṣẹ Yakubu lẹyin to ji foonu ẹgbẹrun mẹjọ ati ẹdẹẹfbẹrin naira, N8,700.
Yakubu sọ fun ileẹjọ pe oun jẹbi ẹsun ole ti wọn fi kan oun, o ni lootọọ loun ji foonu, oun si ta a ni ẹgbẹrun marun un naira.
- Akọ̀wé-owó wọ gàù ní iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó jí N500,000 lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀
- Wọ́n ti yìnbọn pa ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún tó ń jà sí ogún ilẹ̀ bàbá rẹ̀
- Ìdùnnú subú layọ̀ nípìnlẹ̀ Ọyọ́, àwọn tó dé láti Lebanon sọ ọmọ wọn ní Seyi
- Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà
- Ọ̀gá iléeṣẹ́ gbé £10 mílíọ̀nù ẹ̀bùn owó fún òṣìṣẹ́, èyí lohun tó pawọ́n pọ̀
Yakubu ṣalaye pe aṣọ loun fi ẹgbẹrun marun un ti oun ta foonu ra.
Adajọ Shafa paṣẹ pe aago mẹwaa aarọ ni ki Yakubu maa bẹrẹ oko gige ni agọ ọlọpaa naa ki o si maa ṣiwọ iṣẹ laago meji ọsan.
Adajọ tun paṣẹ pe ki Yakubu pada si ọdọ awọn obi rẹ niluu Okene, nipinlẹ Kogi to ba ti pari ijiya ẹṣẹ rẹ.
Adajọ majisireeti wa rọ Yakubu pe dẹkun iwa ibajẹ ti o ba ti bọ ninu eyi tan.
Nibi ti wọn ti fi foonu sina ko le gba ina sori batiri ni Yakubu ti jii gbe.
Agbẹjọro to ṣoju Yakubu nile ẹjọ, Yusuf Jibril rọ ileẹjọ lati jeburẹ lori ijiya ti wọn ba fẹ fun un.
- INEC fún Obaseki ní ìwé-ẹ̀rí moyege gẹ́gẹ́ bí gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn
- OPC láwọn mú afurasí agbébọn ajínigbé mẹ́rin l'Oyo, ọlọ́pàá ní àpapọ̀ òṣìṣẹ́ elétò aàbò ló ṣiṣẹ́ náa
- 'Àwọn oníṣòwò lẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ nìkan ló lè forúkọ sílẹ̀ báyìí fún ìrànwọ́ ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà'
- WASSCE: Ìpínlẹ̀ Delta fòfin de olùkọ́ 41 tó ṣe màgòmágó nínú ìdánwò
Agbẹjọro Jibril sọ fun ileẹjọ pe Yakubu le di ọdaran nla ti ileẹjọ ba ran lẹwọn.
O ṣeeṣe ko jẹ wi pe ẹbẹ agbẹjọro rẹ lo jẹ ki adajọ fun ni ijiya ti ko pọju fun ẹṣẹ to ṣẹ.
- Orílẹ̀èdè Amẹrika ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wo wọlé-wọ̀de Atiku, àwọn ìyàwo rẹ̀ lórí owó tí wọ́n kó lọ sí òkèèrè
- Ọ̀gá iléeṣẹ́ gbé £10 mílíọ̀nù ẹ̀bùn owó fún òṣìṣẹ́, èyí lohun tó pawọ́n pọ̀
- Ìjọba Katsina ní kí àwọn iléèwé wà ṣì ní títìpa nítorí arùn Coronavirus
- Hisbah mú ọkùnrin mẹ́ta tó pín fídíò ìfipábánilòpọ̀ ọmọdébìnrin 16 tó fẹ́ ṣèyàwó lórí ayélujára
- Tí ìjọba bá gbé òfin kónílé-ó-gbélé ọlọ́jọ́ pípẹ́ míì kalẹ̀ nítori Covid-19, ǹkan yóò bàjẹ́ ní Naijiria- Dokita















