Seyi Makinde: Àwọn obìrin tó dé láti Lebanon sọ ọmọ wọn tuntun jòjòló ní Seyi Makinde

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Google

Idunnu subu lu ayọ fun awọn ara ipinlẹ Ọyọ lẹyin ti awọn obirin meji ti ori yọ lati ilẹ Lebanon sọ orukọ ọmọ tuntun jojolo ti wọn ṣẹṣẹ bi lorukọ Seyi Makinde.

Oluranlọwọ pataki fun Gomina ipinlẹ Oyo lori ọrọ awọn ọmọ ipinlẹ naa lokeere, Abilekọ Bolanle Sarumi-Aliyu ni inu awọn dun wi pe wọn sọ awọn ọmọ naa ni orukọ gomina Ṣeyi Makinde.

Sarumi-Aliyu to sọju gomina naa ni ibi isọmọlorukọ awọn ọmọ tuntun jojolo naa ni iṣẹ takuntakun ti gomina naa ṣe ko le di igbagbe fun ẹgbẹgbẹrun ọdun si isinyii.

Awọn ọmọkunrin jojolo naa ni wọn sọ ni Oluseyi Fahrihan ati Oluwaseyi Khalid.

Awọn iya awọn ọmọ naa dupẹ lọwọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde.

Koda, wọn gboriyin fun Alaga Ajọ to n risi ọrọ awọn ọmọ Naijiria ni oke okun, (NIDCOM), Abike Dabiri-Erewa ati awọn ajọ miran lagbaye ti wọn jẹ ko ṣeeṣe fun awọn obinrin yii lati pada si Niajiria lẹyin ọpọlọpọ ipọnju ti wọn la kọja ni Lebanon.

Sarumi ninu ọrọ rẹ ni o ṣe oun laanu wi pe ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo n la ipọnju kọja ni oke okun ti wọn wa, ti a ti wale si nira fun wọn.

O gba wọn ni imọran wi pe ko si ohun to dabi ile, ki awọn eniyan ye sa lọ si oke okun nitori wọn n wa ilẹ ọlọra.

Bakan naa ni o fi da awọn eniyan loju wi pe gomina Seyi Makinde n ṣiṣẹ takuntakun lati ri wi pe gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Oyo ti wọn fẹ wale lati okeere ni awọn yoo ranlọwọ lati ṣe bẹẹ.

Oluranlọwọ pataki fun Gomina ipinlẹ Oyo naa fikun wi pe ọpọlọpọ awọn ọmọ ipinlẹ naa ti wọn wa loke okun ni wọn n la ipọnju kọja nitori idẹyẹsini ati owo ẹru ti wọn n fi wọn ṣe.