Daniel Eniayeju: Daniel ń bọ̀ wá wò mí nítori mo ṣàìsàn ló dàwátì- Baba Daniel

Missing Person: Daniel ń bọ̀ wá wò mí nítori mo ṣàìsàn ló dàwáti- Baba Daniel

Oríṣun àwòrán, Family

Ọmọkunrin, ẹni ọdun marunlelolgun Daniel Eniayeju lo ti di awati láti ọjọ kọkanla oṣu yii ti wọ ko si ri titi di asiko yii.

Ninu ọrọ rẹ Baba Daniel Olaiya Pius Eniayeju ni ọdọ oun ni ọmọ naa n bọ ni ilu Ibadan ni ọjọ Ẹti ọjọ kọkanla oṣu kẹsan, sugbọn ti ko de ọdọ òun ti ko si pada si ilu Eko.

O ni ati ọdun to kọja ni oun ti n ṣe aisan rọpa-rọsẹ to si jẹ pe oju kan ni oun maa n wa nitori ko si oluranlọwọ.

Ọgbẹni Eniayeju ni nigba ti o to ki o de si ilu ibadan ti oun ko ri ni awọn fi mọ pe wahala ti de.

Ninu iwadii to ni awọn oluranlọwọ kan ti ṣe lati ba oun wa, wọn tọpaṣẹ rẹ, o si daju pe o de ilu Ibadan, sugbọn mọto naa gbe koja ilu Ibadan lo si opopona Iwo, ibẹ ni wọn ri tọpasẹ de lati ara foonu Iphone to mu lọwọ.

Baba ọmọ naa ni titi di asiko yii ajọ ọlọpaa ko ti fun awọn ni idahun to ṣe e tẹle kankan lori ibi ti ọmọ naa rin si.

Lasiko ti Iya ọmọ naa n ba BBC Yoruba sọrọ, O salaye pe ọdun 2018 ni oun ti foju kan ọmọ oun gbẹyin sugbọn nitori ipinlẹ Kogi ni oun wa nigba ti Daniel wa ni ilu Eko.

Sugbọn loji ni oun gba ipe pe igbawo ni oun ti guro ọmọ oun Daniel kẹyin?

Missing Person: Daniel ń bọ̀ wá wò mí nítori mo ṣàìsàn ló dàwáti- Baba Daniel

Oríṣun àwòrán, Family

" Ẹni to pe mi kan sọ fun mi pe o ya ẹ pe nọmba Daniel, nibo lo wa? Mo pe Nọmba rẹ ko ba lọ mọ"

"Lati igba yé ni a ti n wa o, a ko tii ri di asiko yii.

Baba ati Iya Daniel rọ ijọba Ipinlẹ Oyo ati Gomina Seyi Makinde lati dide iranwọ lori akọbi ọmọ wọn ki o le di awari.

Iya Daniel ni ọmọ naa ni akọbi awọn inu iṣẹ ati iya si ni awọn ti tọ de ibi to de, to sọnu lọsan gangan.

Bakan naanni wọn rọ ajọ ọlọpaa lati tẹra mọ iṣẹ iwadii wọn lori ọmọ naa

Igbiyanju BBC lati ba alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọ̀rọ̀ ja si pabo bi se pe aago rẹ titi sugbọn ti ko gbee