Tolulope Arotile kú ṣùgbọ́n òrúkọ rẹ̀ kò parẹ́ mọ́ láí níléeṣé ọmọogun Nàìjíríà

Tolulope Arotile kú ṣùgbọ́n òrúkọ rẹ̀ kò parẹ́ mọ́ láí níléeṣé ọmọogun Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Others

Gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe ipinu lati ṣe ẹyẹ pataki ni iranti ajagunwakọ ofurufu akọkọ ni Naijiria to gbẹmi mi loṣu diẹ sẹyin fun iṣẹ ribi ribi rẹ lati doju ija kọ awọn adigunjale atawọn ọdaran mii lorilẹede Naijiria.

Ileeṣẹ ogun oju ofurufu ti ṣeranti oloogbe Tolulope Arotile lonii

Lọjọ kejilelogun oṣu kẹsan ni ileeṣẹ ogun oju ofurufu tun awọn yara ikọ ọmọogun to n jẹ "Crew Room" ṣe to wa ni 115 Special Operations Group ni ilu Port Harcourt ti wọn si sọ lorukọ Ajagun Tolulope Arotile.

Tolulope dagbere faye lọjọ kẹrinla oṣu karun ọdun 2020 lẹni ọdun mẹrinlelogun.

To fi mọ gbogbo yara idana, baluwẹ, ile ijẹun, yara iwọṣọ awọn awakọ ati ọpọlọpọ ile igbọnsẹ ni wọn tunṣe ti wọn fi sọ ọ lorukọ Tolulope Arotile.

Ileeṣẹ ogun oju ofurufu ti ṣeranti oloogbe Tolulope Arotile lonii

Oríṣun àwòrán, Nigeria Airforce HQ

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ iranti yii, ọga awọn ọmọ ogun oju ofurufu, Ọgagun Sadique Abubakar ni awọn ṣe ẹyẹ yii fun oloogbe Arotile, kii ṣe ni iranti rẹ nikan ṣugbọn lati ṣe moriya fun awọn ọdọbinrin ni Naijiria lati kawe, ṣiṣẹ takun takun lati mu ala ire wọn ṣẹ.

Ileeṣẹ ogun oju ofurufu ti ṣeranti oloogbe Tolulope Arotile lonii lati mu ileri rẹ ṣẹ lẹ́yìn ikú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Nigeria Airforce HQ

"O wu ni lori lati sọ pe lẹyin iku oloogbe Tolulope, ọpọ ọdọbinrin lo ti fifẹ han lati darapọ mọ ọlogun ofurufu". Ọgagun Abubakar sọ bẹẹ.O ni awọn tun ṣe eyi lati fihan pe iṣẹ ire awọn eeyan ko gbudọ lọ lasan.

O tẹnu mọ ọ pe titi lai ni iranti Tolulope Arotile yoo wa lọkan awọn ologun.

Ninu atẹjade ti Ibikunle Daramola fọwọ si, awọn eeyan jankan jankan ninu iṣẹ ologun ati ni Naijiria lo peju sibi ayẹyẹ iranti naa.