Atiku FinCEN Files: Atiku ní iró ni pé orílẹ̀èdè Amẹrika ń ṣọ́ wọlé-wọ̀de òun àti ìdílé rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Google
Oludije fun ipo aarẹ ninu idibo aarẹ ọdun 2019, Atiku Abubakar ti fesi si iroyin kan to sọ pe ijọba orilẹede Amẹrika ti bẹrẹ si ni wo wọle-wọde rẹ ati iyawo rẹ to fi mọ awọn ẹbi rẹ.
Ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ lori ọrọ iroyin si Atiku, Paul Ibe buwọlu, wọn ni ko si ohun to jọ bẹẹ.
Ibe ṣalaye ninu atẹjade naa pe Atiku ko tapa si ofin kankan yala ni Naijira tabi loke okun, o ni irọ nla lawọn kan n gbe kiri nipa Atiku.
- Ìdùnnú subú layọ̀ nípìnlẹ̀ Ọyọ́, àwọn tó dé láti Lebanon sọ ọmọ wọn ní Seyi
- Akọ̀wé-owó wọ gàù ní iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó jí N500,000 lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀
- Hisbah mú ọkùnrin mẹ́ta tó pín fídíò ìfipábánilòpọ̀ ọmọdébìnrin 16 tó fẹ́ ṣèyàwó lórí ayélujára
- Ọ̀gá iléeṣẹ́ gbé £10 mílíọ̀nù ẹ̀bùn owó fún òṣìṣẹ́, èyí lohun tó pawọ́n pọ̀
- Ọ̀rọ̀ Soyinka àti Obasanjo papọ̀ lórí pé Buhari n ṣe ìpínyà Nàìjíríà
Ọgbẹni Ibe sọ ninu atẹjade ọhun pe ijọba ilẹ Amẹrika ko fẹsun ikowo lọ silẹ okere kan Atiku, bakan ni ẹka eto idajọ orilẹede Amẹrika naa ko fi ẹsun kankan kan Atiku.
O ni bakan naa lawọn kan gbe irufẹ iroyin yii ṣaaju eto idibo aarẹ ọdun 2019.
Ọgbẹni Ibe ni lẹyin naa ni Atiku gba fisa Amẹrika ti o si rinrin ajo lọ si orilẹede naa, ''koda ẹgbẹ ọfiisi ẹka eto idajọ ni ile itura ti Atiku de si wa.''
''Awọn oṣiṣẹ ijọba ilẹ Amẹrika gan an ki Atiku kaabọ nigba to de si Amẹrika,'' Ibe lo sọ bẹẹ.
- Ọ̀gá iléeṣẹ́ gbé £10 mílíọ̀nù ẹ̀bùn owó fún òṣìṣẹ́, èyí lohun tó pawọ́n pọ̀
- Ìjọba Katsina ní kí àwọn iléèwé wà ṣì ní títìpa nítorí arùn Coronavirus
- OPC láwọn mú afurasí agbébọn ajínigbé mẹ́rin l'Oyo, ọlọ́pàá ní àpapọ̀ òṣìṣẹ́ elétò aàbò ló ṣiṣẹ́ náa
- Tí ìjọba bá gbé òfin kónílé-ó-gbélé ọlọ́jọ́ pípẹ́ míì kalẹ̀ nítori Covid-19, ǹkan yóò bàjẹ́ ní Naijiria- Dokita
- INEC fún Obaseki ní ìwé-ẹ̀rí moyege gẹ́gẹ́ bí gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn
Ọgbẹni Ibe ni awọn to n gbe iroyin ofege naa kiri n ṣe bẹẹ nitori igbesẹ orilẹede Amẹrika to fofin de awọn ọmọ Naijiria kan laipẹ yii lati rinrin ajo lọ si Amẹrika ṣaaju idibo gomina Edo.
O ni Atiku pẹlu ẹbi rẹ ko ṣe nkan etufu debi wi pe yoo maa kiyesi ẹkule.
Orílẹ̀èdè Amẹrika ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wo wọlé-wọ̀de Atiku, àwọn ìyàwo rẹ̀ lórí owó tí wọ́n kó lọ sí òkèèrè
Iwadii tuntun ti FINCEN gbe jade pẹlu ajọsepọ awọn oniroyin lagbaye fihan bi igbakeji aarẹ lorilẹede Naijiria tẹlẹri, Atiku Abubakar ṣe n ko owo lọ si oke okun.
Iwadii yii bẹrẹ pẹlu owo to to $1,018,500 ti Atiku fi ranṣẹ si ile ifowopamọsi, Habib Bank Limited ni ilu New York, lorilẹede Amẹrika.
Gẹgẹ bi iroyin ti ileeṣẹ Premium Times to pẹlu awọn ileeṣẹ to ṣe iwadii naa, ni o ti to ọdun mẹjọ ti banki naa ti bẹrẹ si ni wo igbesẹ Atiku pẹlu owo ti wọn fi n ranṣẹ si oke okun.
Atiku fi owo ranṣẹ si ilẹ okeere lati ileeṣẹ rẹ, Guernsey Trust Company Nigeria Limited (GTCN) ati awọn ileeṣẹ miran.
Ni ọdun 1999 ti Atiku da igbakeji aarẹ ni Naijiria ni ileeṣẹ naa gberasọ, amọ ọdun 2012 ni wọn ri iwadii pe wọn bẹrẹ si ni fi owo gọbọi ranṣẹ si oke okun.
Iwadii naa fi ẹsun kan Atiku wi pe o fi owo to le ni miliọnu mẹwa dọla ( USD 10 million) ranṣẹ si oke okun labẹ ileeṣẹ GTCN.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Bakan naa ni Ile Aṣofin Agba ni ilẹ Amẹrika ṣewadii wipe Atiku fi iye owo to to ogoji miliọnu dọla ilẹ okeere, nigba ti iyawo Atiku kẹrin, Jennifer Douglas fi iye owo to to miliọnu marundinlọgbọn ranṣẹ si ile ifowopamọsi to le ni ọgbọn ni ilẹ okeere.
Awọn ti iwadii naa kan ni Atiku Abubakar, Rukaiyatu Atiku Abubakar, Amina Atiku Abubakar, Massimo Del Celo, Uyiekpen Gboyega Giwa-Osagie ati awọn ileeṣẹ Tanjay ati ileeṣẹ GTCN.
Giwa-Osagie n koju ẹsun iwa ibajẹ ati ajẹbanu to lẹ ni miliọnu meji dọla owo ile okeere, eleyii ti Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ,EFCC fi lede wi pe o fi owo naa ra ibo ni ọdun 2019, ti Atiku dibo gẹgẹ bi aarẹ lorilẹede Naijiria, to si kuna.
Bakan naa ni ọdun 2017, ileeṣẹ ofintoto HBLNY ati SAR fi lede wi pe Atiku fi owo ranṣẹ si banki mẹtadinlọgbọn pẹlu iye owo to to $11,140,357 si banki Deutsche Bank Trust Company Americas, DBTCA ni orilẹede Amerika.
- Ọ̀wọ́ngógó búrẹ́dì gbòde kàn lẹ́yìn tí àwọn oníbúrẹ́dì da iṣẹ́ sílẹ̀
- Èèyàn mẹ́jọ jónà ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ akérò tó ṣẹlẹ̀ ní mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan
- Ọlọ́jọ́ Festival 2020:Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ tí wọ ìléèdí ọlọjọ méje tí kò ní rí ẹnikẹ́ni sójú
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ elétò ìlera, ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́- JOHESU
- Bí PDP ṣe na APC lálùbami ní Edo, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣẹlẹ̀ ní Ondo- PDP

















