Police Clash: Ọlọ́pàá kọlu àwọn ọmọ onílẹ̀, ní ìbọn àṣìyìn bá pa ènìyàn méjì

Oríṣun àwòrán, Google
Rogbodiyan bẹ silẹ ni ilu Ikogbo ni ijọba ibilẹ Ado-Odo/Ota ni ipinlẹ Ogun lẹyin ti ibọn aṣiyin pa eniyan meji, ti ọpọlọpọ si farapa.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni ilu Ikogbo ati Imoṣe n ja si ọrọ ilẹ ni iṣẹlẹ naa waye.
Wọn fikun un wi pe ileẹjọ to paṣẹ ki wọn gbe ilẹ naa fun ilu Ikogbo lo da ija silẹ laarin wọn.
Gẹgẹ bi ọrọ awọn to wa ni ibi iṣẹlẹ naa, Onikogbo ti Ikogbo, Oba Nurudeen Osoja, pe awọn ọlọpaa lati wa fidi idajọ ileẹjọ mulẹ,ki wọn si pari aawọ to wa laarin ilu mejeeji.
Amọ, bi awọn araalu ọhun ṣe faraya lo mu ki awọn ọlọpaa bẹrẹ si ni yinbọn to si ba ọlọkada kan to n bọ lati ọja ati awọn ọmọ ileewe to n kọja, ti ọkan lara wọn si ku latari ọta ibọn to ba a.
Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti fi panpẹ ọba mu awọn ọdọ mẹrin ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, ati wi pe iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi idi iṣẹlẹ mulẹ, amọ o ni awọn araalu pe awọn ọlọpaa sibẹ lati pari aawọ to bẹ silẹ.
Amọ o ni awọn ọmọ onilẹ to fẹ gba ibọn lọwọ awọn ọ̀lọpaa lo yin ibọn to ba awọn eniyan meji to ba iṣẹlẹ naa lọ.
- Ẹ gbó òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa bàbá ìsàlẹ̀...
- Èèyàn 125 ní àrùn Coronavirus tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ràn ní Nàìjíríà ní Ọjọ́bọ̀
- Oluwo kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn afọbajẹ tó fẹ́ yọ ọ́ nípò, aráàlú fọ́n síta láti fẹ̀hónú hàn
- APC Ekiti pàṣẹ lọ rọ́ọ́kún nílẹ̀ fún àna Tinubu àti Babafemi Ojudu
Land dispute Delta case: Wọ́n ti yìnbọn pa Onwuka Onyinye, ẹni ọgbọ̀n ọdún tó ń jà sí ogún ilẹ̀ bàbá rẹ̀
Onyinye Onwuka, ẹni ọgbọn ọdun ni wọn ti yinbọn pa lẹyin ti ija lori ẹni to ni ilẹ bẹ silẹ laarin iilu meji, Obodogwugwu ati Ugbolu ni ijọba ibilẹ Oshimili ni ipinlẹ Delta.
Iroyin fi lede wi pe Onyinyeeniyan ti wọn ko mọ yinbọn pa ni Ọjọ Aiku wa lati agbegbe Idigbe-Ocha ni agbegbe Okpanam.

Oríṣun àwòrán, @Police
Awọn ti iṣẹlẹ naa soju wọn ni lasiko ti ija n waye laarin awọn ọdọ lati ilu Ugbolu ti ko jinna si wọn ni wọn yinbọn pa Onyinye.
Ọpọlọpọ ọdun ni ija ti n waye laarin awọn adugbo mejeeji naa ti ko si ni iyanju tit di asiko yii.
Ọdun mẹrin sẹyin ni awọn ara agbegbe Ugbolu gbe ọrọ naa lọ si ileẹjọ ti wọn si jẹbi bọ lẹyin ti adajọ sọ wi pe awọn ara Idigbe-Ocha quarters, Okpanam lo ni ilẹ naa.
Ninu ọrọ tirẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Delta, DSP Onome Onovwakpoyeya sọ wi pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ti awọn si ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
- 'Àwọn oníṣòwò lẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ nìkan ló lè forúkọ sílẹ̀ báyìí fún ìrànwọ́ ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà'
- Èèyàn 176 ní àrùn Coronavirus tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ràn ní Nàìjíríà ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun
- Ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú sọ orúkọ Tolulope Arotiba di mánigbàgbé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà
- Daniel ń bọ̀ wá wò mí nítori mo ṣàìsàn ló dàwátì- Baba Daniel
- OPC láwọn mú afurasí agbébọn ajínigbé mẹ́rin l'Oyo, ọlọ́pàá ní àpapọ̀ òṣìṣẹ́ elétò aàbò ló ṣiṣẹ́ náa
Onovwakpoyeya fikun un wi pe ohun ti awọn gbọ ni wi pe nitori ọrọ ilẹ ni wọn ṣe pa ọkunrin naa.
Ati wi pe nibayii, awọn ko i tii fi panpẹ ọba mu ẹnikẹni, amọ awọn eniyan wa ti bẹrẹ igbesẹ to tọ lati mọ awọn to wa ni idi iṣẹlẹ naa.
















