Nigeria School resumption Update: Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń wọlé, wo bí o ṣe lè dáàbò bo ọmọ rẹ níléèwé

Oríṣun àwòrán, @Pite
Awọn ipinlẹ kan lorilẹ-ede Naijiria ti buwọlu ipadasi ileewe f'awon akẹkọọ loṣu kẹsan an lẹyin ti ijọba ti ti awọn ileewe pa losu kẹta nitori ajakalẹ arun COVID-19.
Opo awọn ijọba lo ti fowo si ki awọn ileewe alakọbẹrẹ, girama ati ileewe giga o pada si ẹnu iṣẹ ẹkọ.
Bi eyi si ti n waye naa ni ajo idagbasoke awọn ọmọde lagbaye UNICEF ti gbe awọn imọran kan kalẹ fawọn obi lori bi wọn ṣe le bori ipaya tawon ọmọ wọn lee fẹ ni nipa iwọle naa ati ajakalearun ọhun.
Bakan naa ni ajọ UNICEF tun dahun awọn ibeere kan to n jẹyọ lọkan awọn obi nipa iwole naa.
Bi o se lee fi ọkan ọmọ rẹ balẹ lori iwọle:
- Ba omo rẹ sọrọ, gbọ ẹdun rẹ ati idi ti o fi n bẹru ki o si jẹko di mimọ fun pe ko si idi fun ifoya nitori o ti ṣe diẹ to wọ kilaasi ileewe k'ẹyin.
- Awọn ọmọ lee maa fẹ pada mọ nitori o to ọjọ mẹta, paapaajulọ awọn to ti n kọ ẹkọ ori ayelujara lati ile.
- Je tko di ye e pe ko nilo ki oun atawọ ọrẹ rẹ o sunmọra wọn pẹkipẹki, ohun ti wọn nilo ni lati wa awon ona mira lati maa ṣe pọ.
Eyi ṣe pataki nitoripe igbesẹ itakete sira ẹni ṣi lee ṣe ajeji si wọn.
- Lawuyi Ogunniran, àgbà ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé Eégún Aláré dágbére fáyé!
- Bah N'Daw àti Assimi Goita di adarí tuntun láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè Mali ní ọdún kan àti aàbọ̀
- Orílẹ̀èdè Amẹrika ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wo wọlé-wọ̀de Atiku, àwọn ìyàwo rẹ̀ lórí owó tí wọ́n kó lọ sí òkèèrè
- Ìdùnnú subú layọ̀ nípìnlẹ̀ Ọyọ́, àwọn tó dé láti Lebanon sọ ọmọ wọn ní Seyi
- Ìjọba Katsina ní kí àwọn iléèwé wà ṣì ní títìpa nítorí arùn Coronavirus
Imọran miran fun Obi ati Alagbatọ:
Salaye fun wọn nipa awọn igbesẹ idaabobo ti yoo mu ki awon akekọọ ati oluhkọo wa ni alaafia lai si ewu.
Ma si ṣe gbagbe ati maa tẹẹ mọ wọn leti lati fọ ọwọ wọn pẹlu ọṣẹ ati omi loorekoore.

Oríṣun àwòrán, @ACHS
Bi wọn ba fẹ hukọ, ki wọn lo inu igunpa wọn.
Si tun ran wọn leti awọn nkan ayọ to wa nibẹ bi wọn ba lọ si ileewe, bi riri awọn ọrẹ wọn, awọn olukọ wọn at'awọnohun tuntun ti wọn yoo lanfani ati kọ nipa rẹ.
Ọrọ ideyesi naa yoo jẹyọ, nitorinaa, o ṣeese ki awọn adigboluja akẹkọọ kan o maa dide ogun sawọn akẹgbẹ wọn nitori awọn ohun ti wọn ti gbọ nipa COVID-19.
- Hisbah mú ọkùnrin mẹ́ta tó pín fídíò ìfipábánilòpọ̀ ọmọdébìnrin 16 tó fẹ́ ṣèyàwó lórí ayélujára
- Tí ìjọba bá gbé òfin kónílé-ó-gbélé ọlọ́jọ́ pípẹ́ míì kalẹ̀ nítori Covid-19, ǹkan yóò bàjẹ́ ní Naijiria- Dokita
- OPC láwọn mú afurasí agbébọn ajínigbé mẹ́rin l'Oyo, ọlọ́pàá ní àpapọ̀ òṣìṣẹ́ elétò aàbò ló ṣiṣẹ́ náa
- INEC fún Obaseki ní ìwé-ẹ̀rí moyege gẹ́gẹ́ bí gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn
- Daniel ń bọ̀ wá wò mí nítori mo ṣàìsàn ló dàwátì- Baba Daniel
O nilo lati salaye fun un pe ajakalẹ arun yii ko mọ ẹnikẹni. Bi ẹnikẹni ba lu wọn nileewe, ki wọn fi to awọn olukọ wọn leti.
Ọwọ fifọ loorekoore jẹ ọna kan pataki fun didẹkun arun yii ati ririi daju pe alafia to awọn ọmọ wa.
O lee kọ lorin akosori, ijo tabi ọna miran to lee mu ko dun mọ awọn ọmọ naa lati fẹ gbọ.
Jẹ ki won mọ pe wọn ko lee fi oju ri awọn kokoro arun wọnyi nitori naa ki wọn mojuto imọtito ara wọn.
- 'Àwọn oníṣòwò lẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ nìkan ló lè forúkọ sílẹ̀ báyìí fún ìrànwọ́ ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà'
- WASSCE: Ìpínlẹ̀ Delta fòfin de olùkọ́ 41 tó ṣe màgòmágó nínú ìdánwò
- Akọ̀wé-owó wọ gàù ní iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó jí N500,000 lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀
- Ẹgbẹ́ NULGE Oyo dìbò yan olóyè ẹgbẹ́ tuntun èyí tó tako àṣẹ iléẹjọ́
- Ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú sọ orúkọTolulope Arotiba di málegbàgbé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà















