Social media abuse: Oyedepo ní àlòjù Twitter, Facebook àti Instagram máa ń ṣàkóbá fún àyànmọ́ ẹ̀dá

Oyedepo

Oríṣun àwòrán, Oyedepo

Oludari agba fasiti Covenant to wa niluu Ota, nipinlẹ Ogun, Ọmọwe David Oyedepo ti gbawọn ọdọ ni imọran lati ye wa lori ẹrọ ayelujara ni gbogbo igba.

Biṣọọbu ijọ Living Faith ti ọpọ mọ si Winners Chapel sọrọ yii nibi ayẹyẹ ikẹkọọ jade fasiti Covenant ẹlẹẹkẹẹdogun rẹ lọjọ Ẹti.

Oludasilẹ ijọ Winners Chapel ni aloju oju opo ayelujara maa n ṣakoba nla fawọn ọdọ.

O ni lilo oju opo ayelujara lọna aitọ kii jẹ k'awọn ọdọ le kọju mọ ohun ti wọn n ṣe eyi ti yoo pada ṣakoba fún ọjọ ọla wọn.

"Wiwa loju opo ayelujara ni gbogbo igba ti gba akoko lati ronu, awọn mii le ba ọrẹ wọn sọrọ lori ayelujara lati aarọ di alẹ.

Àkọlé fídíò, Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

Awọn onimọ kan tiẹ sọ pe isọri kan naa ni aloju oju opo ayelujara ati mimu oogun oloro, ọti ati ṣiṣe ṣina jọ wa," Oyedepo ṣalaye.

Biṣọọbu Oyedepo ni wiwa loju opo ayelujara ni gbogbo igba ti gba aye tawọn ọdọ fi le ṣe nkan iyebiye lọwọ wọn.

Pasitọ ijọ Winners sọ pe igbe aye ti ko ba ni afojusun kan gbogii ko ni ìtumọ kankan.

O ni awọn ti wọn ba ni afojusun ibi ti wọn ba n lọ nikan lo le dé ebute ayọ ayanmọ wọn.

Oyedepo ni asiko ti to fawọn ọdọ lati ji giri ki wọn sì ṣiṣẹ lori ọjọ.

Àkọlé fídíò, Down Syndrome Skill centre: Wo bí ọmọ tí ọpọlọ wọn kù díẹ̀ ṣe ń kọ́ iṣẹ́ agẹrun