Samsung Galaxy S9: Aworan ti jade ki foonu to jade.

Aworan Samsung Galaxy S9

Oríṣun àwòrán, XDA

Àkọlé àwòrán, Ẹrọ to n mu kọmputa sisẹ, MWC app, lo gbe aworan naa jade nigba ti foonu naa ko tilẹ tii jade

Aworan ẹrọ ilewọ tuntun lati ile-isẹ Samsung ti jade lati ọwọ ẹrọ to n mu kọmputa sisẹ, MWC app, to jẹ ti ile-isẹ Samsung fun ra rẹ.

Aworan naa jade gba ọna ẹburu ti awọn kan fi wọ ẹrọ ti wọn fi pe awọn eniyan wa sii bi ti wọn ti fẹse ifilọlẹ ẹrọ ilẹwọ Samsung naa lọjọ Aiku ni ilu Barcelona.

Awọn onimọ nipa ẹrọ ilẹwọ fi lede wipe, fifi aworan naa sita nigba ti wọn ko tii bẹrẹ sini ta fonnu naa, tako ọna ti wọn fe gba gbe ẹrọ ilewọ naa jade fun awọn eniyan.

Aworan ẹrọ to n mu kọmputa sise, MWC app

Oríṣun àwòrán, SAMSUNG

Àkọlé àwòrán, MWC app yii ni won fi pe awon eniyan sibi ifilole foonu naa sugbon ko seni ti kole sookale lori komputa

Aworan to jade naa fi idi iroyin to sọwipe ẹrọ ilewọ tuntun ti wọn fẹ gbe jade naa farajọ Galaxy S8 pẹlu iyatọ diẹ diẹ mulẹ.

Ninu ọrọ rẹ, agbẹnusọ fun ile-isẹ Samsung sọwipe awọn ko ni gbolohun lati sọ si ọrọ tabi iroyin ti ko lẹsẹ n lẹ.