Elegushi Romance Fraud: Ọwọ́ tẹ abánikunlé tó fi orúkọ Ọba Elegushi lu obìnrin kan ní jìbìtì ₦51m

Awn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Afurasi meji to fi orukọ ọba Elegushi nipinlẹ Eko lu eeyan ni jibiti, ti wa ni ahamọ ọlọpaa

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti ṣa fihan ọkùnrin kan, Moses Olaitan ati ẹnikeji rẹ, Segun Omoshola fun ẹsun pe wọn fi orukọ ọba Elegushi lu jibiti.

Iroyin sọ pe nise ni àwọn eniyan naa n pe ara wọn ni Ọba Saheed Elegushi fun obinrin kan ti wọn pade lori ayelujara Facebook, titi wọn fi lu u ni jibiti miliọnu marundinlọgọta naira.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọga Agba ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu sọ lasiko to fi ojú awọn afurasi naa han ni olu ileesẹ ọlọpaa to wa ni Ikeja pe, lẹyin ti wọn fi ẹjọ wọn sùn nileesẹ ọlọpaa, lẹyin oṣu mẹta tí wọn da ọ̀ràn naa, ni ọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ tẹ Segun ati Olaitan.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Ọkan lara awọn afurasi naa, Olaitan sọ pe oun fi orukọ ọba naa ṣi oju opo ibanidọrẹ lori Facebook, ti oun si bẹrẹ si ni fi àwọn aworan rẹ sibẹ lati fa oju awọn to n wa ọkọ mọ́ra.

Nipasẹ bẹẹ si ni obinrin ti wọn lu ni jibiti fi bọ si panpẹ wọn.

Olaitan ṣalaye pe, obìnrin naa ba oun sọrọ lori Facebook pe oun fẹ ẹ fẹ ọba ni ọkọ.

"Mo sọ fun pe to ba fẹ ẹ fẹ ọba, o gbọdọ ṣe àwọn nkan ibilẹ diẹ, o si gba lati ṣe bẹ ẹ.

" O sọ fun mi pe ki n fi nọmba apo asunwọn banki mi ránṣẹ si oun, sugbọn mi o ni. Eyi si lo mu mi fi ọrọ lọ Segun, to wa nọmba akanti ta fi gba owo naa."

Olaitan sọ pe miliọnu meji aabọ Naira ni wọn san fun oun, ati pe nígbà ti ọwọ tẹ ẹ, ni oun to mọ pe miliọnu mọkanlelaadọta ni obinrin naa san.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

O sọ pe nọ́mbà foonu oun ni awọn ọlọpaa tọpinpin rẹ, ti ọwọ fi tẹ oun lasiko ti oun n palẹmọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi oun.

Ni ti Segun to wa akanti ti wọn fi gba owo naa, o sọ pe lootọ ni oun mu lọ si ọdọ awọn to pese akanti naa.

Sugbọn o ni miliọnu mẹta aabọ Naira ni wọn fun oun, iyalẹnu si lo jẹ fun oun nigba ti awọn ọlọpaa sọ pe miliọnu mọkanlelaadọta Naira ni obìnrin naa fi ránṣẹ.

Bẹẹ ba gbagbe laipẹ yii ni Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi naa figbe bọnu pe, awọn eeyan kan n gba awọn obinrin to nifẹ lati di ayaba ni aafin oun lori Facebook pẹlu orukọ oun.