Greenfield Students Kidnap: Ajínigbé ní òun yóò pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yókù lái sí owó lónìí

Aworan ọlọde to gbe ibọn lọwọ lati koju awọn janduku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ajinigbe to ko awọn akẹkọọ fasiti Greenfield ni Kaduna si ahamọ ti leri lati pa awọn akẹkọọ to ku lọdọ wọn, bi wọn ko ba san owo idoola ẹmi ti wọn beere.

O kere tan eeyan mẹtalelogun to fi mọ awọn olukọ ileewe fasiti aladani to wa lopopona Kaduna si Abuja, ni wọn ji gbe logunjọ osu Kẹrin ọdun yii.

Saaju asiko yii, lawọn ajinigbe naa ti mu ileri wọn sẹ pẹlu bi wọn ti se pa awọn akẹkọọ marun un ninu awọn ti wọn ji gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹwẹ olori awọn janduku ajinigbe naa, Sani Jalingo to ba ileesẹ iroyin ẹka Hausa Voice of Amẹrika sọrọ ni, owo idoola ẹmi ọgọrun miliọnu dọla ati alupupu mẹwaa lawọn n beere fun.

Àkọlé fídíò, 'Bàbá, orúkọ yín rèé nínú ìwé òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì Nàìjíríà tó ti kú, kí 'ló ṣẹ́lẹ̀?'

Jalingo, ti inagijẹ rẹ n jẹ 'Baleri' ni bi ijọba ba kọ lati da awọn lohun lọjọ Isẹgun iyẹn ọla, awọn yoo pa awọn akẹkọọ to ku to wa ni ahamọ lọdọ awọn.

O tẹnumọ pe bi ijọba ba kọ etikun si awọn, n se ni awọn yoo fi ọkọ tirela ko oku awọn akẹkọọ naa wa sigboro.

O ni akẹkọọ mẹtadinlogun, ninu eyi ta ti ri obinrin mẹẹdogun ati ọkunrin meji lo wa ni ahamọ.

Jalingo ni awọn obi awọn akẹkọọ to ku ti san owo miliọnu marundinlọgọta fawọn.

Abawọle fasiti Greenfield

Oríṣun àwòrán, Greenfield University

Lẹyin ti wọn ji awọn akẹkọọ yii gbe, lawọn ajinigbe naa ti kan si awọn obi awọn ọmọ ọhun, ti wọn si ti beere fun ẹgbẹrin miliọnu Naira owo idoola ẹmi.

Jalingo ni awọn ko tiẹ wa beere fun ẹgbẹta miliọnu dọla mọ bi kii se ọgọrun miliọnu Naira lati ọdọ ijọba bayi.

Amọ o se ni laanu pe wọn pa awọn marun un ninu awọn akẹkọọ wọn yii lẹyin igba naa.

Titi di asiko yii, ijọba Kaduna ko ti yi ipinu rẹ pada pe awọn ko ni san owo idoola ẹmi fawọn ajinigbe naa.