Niger State Attack: Àwọn agbébọn tún ti jí ènìyàn tó lé ní 100 gbé lọ

Aworan awọn agbebọn kan

Oríṣun àwòrán, other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn olugbe ipinlẹ Niger ti kegbare pe awọn agbebọn ti ṣekọlu si ilu awọn, ti wọn si pa ọpọlọpọ eniyan pẹlu awọn eniyan to le ni ọgọrun ti wọn tun jigbe lọ.

Eyi ko ṣẹyin ikede gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Bello to ni awọn ikọ agbẹsunmọmi Boko Haram ti ṣigun bo ipinlẹ awọn.

Awọn ilu ti wọn ṣekọlu si naa ni Shadadi, ni ijọba ibilẹ Mariga, ti awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni o le ni ẹgbẹrun eniyan to ti sakuro ni agbegbe naa.

Àkọlé fídíò, 'Iṣẹ wá burẹkẹ síi tórí Covid-19, owó ńlá ló wà nínú dídáná sun òkú, ìsìnkú Zoom, Live streaming'

Awọn ara ilu Shadadi ni awọn ti awọn agbebọn naa pa ni Ọjọru le ni ọgọrun, amọ ijọba ipinlẹ Niger ni iye awọn eniyan to ku ati eyi ti wọn jigbe lọ ko to ọgọrun un eniyan.

Ẹlomiran ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni awọn agbebọn naa wa sibẹ ni ọgọọrọ, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn, ti eniyan mẹjọ ku lẹsẹkẹsẹ, ti mẹrin si farapa.

Nibayii, awọn eniyan ti n sakuro ni agbegbe naa lọ si ilu Kontagora to sun mọ wọn lati sa asala fun ẹmi wọn.

Ijọba ipinlẹ Niger ni awọn si n ṣe akojọpọ orukọ awọn eniyan to lugbadi iṣẹlẹ naa ni, ki ijọba apapọ le ṣeranwọ fun wọn lati koju eto aabo to dẹnukọlẹ nibẹ.

Titi di asiko yii, ko ti i si idaniloju pe awọn ikọ agbẹsunmọmi Boko Haram lo ṣe ikọlu naa tabi awọn ọdaran agbebọn lo pa awọn eniyan ni ipinlẹ Niger.

"Ṣé ẹ léró pé ọmọ mi ṣì lè padà wá bá mi láàyè báyìí? Òbí akẹ́kọ̀ọ́ Kaduna

Omije ẹkun, ohun aro, orin ẹhonu lo gbode lasiko ti awọn obi, alagbatọ atawọn ajafẹtọ wọde lọ sile aṣofin apapọ Naijiria nilu Abuja lati pe fun igbesẹ kanmọnkia latọdọ ijọba lori itusilẹ awọn akẹkọọ ileewe ẹkọṣẹ imọ nipa akoso igbodidi, Federal College of Forestry Mechanization, Kaduna.

Ọkan ninu awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe naa ti o pe orukọ ara rẹ ni Rabi Magaji Zakariya, ni kii ṣe ohun to rọrun rara ati pe inira ti ẹbi oun n dojukọ lori iṣẹlẹ naa ko kere rara.

O ni gbogbo oun ti awọn n ri ni wahala ti awọn akẹkọọ naa n dojukọ lori ayelujara, ko si ẹni to ri igbesẹ ti ijọba n gbe lori rẹ.

O ni opo ni oun ati pe ọdun tokọja lo yẹ ki ọmọ oun ti kẹkọjade ni ileewe naa kani pe ajakalẹ arun COVID-19 ko gbaye kan ni.

Arabinrin Zakariyani Ọjọbọ ni yoo pe oṣu meji gbako ti awọn akẹkọọ naa ti wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa.

Awọn obi awọn akẹkọ ti wọn jigbe

"Ọmọ mi ko leeyan niwaju tabi lẹyin lẹyin emi yii. Mo wo iwaju mo wo ẹyin mi o le jẹun, mi o ri ọmọ mi. Bi mo ṣe n pe orukọ rẹ to ko da mi lohun... Ẹ jọọ ṣe ẹ ro pe maa tun lee fi oju kan ọmọ mi mọ bayii?" Arabinrin Zakariya pariwo pẹlu ẹkun.

Arakunrin kan ti ọmọ rẹ pẹlu wa lara awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe ṣalaye fun BBC pe ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira (N500, 000,000) ni awọn ajinigbe naa n beere fun.

O ni igba ti ijọba ti kọ lati dunadura pẹlawọn ajinigbe naa lo mu ki awọn gbe ẹbẹ awọn wa siwaju awọn aṣofin apapọ lati gba ọrọ wọn ro.

Awọn obi awọn akẹkọ ti wọn jigbe

Arabinrin Hellen Sunday Hai ti oun pẹlu jẹ obi ni tirẹ ṣalaye pe awọn o ni ọrọ meji lati sọ ju kawọn rawọ ẹbẹ si ijọba lati ba awọn yẹ gbogbo ọna to ba yẹ fun itusilẹ awọn ọmọ wọn.

Ọkan ninu awọn akẹkọọ naa ti ori ko yọ lẹyin ti wọn ji wọn gbe ṣalaye pe lilu pọ lasiko ti oun fi wa lahamọ awọn ajinigbe naa.

O ni awọn ọkunrin lo lọ n pọn omi nigba ti awọn obinrin aarin wọn n dana ounjẹ fun wọn. Bakan naa lo fi kun pe awọn kan ninu awọn ajinigbe naa gbiyanju lati fipa ba ọkan ninu awọn akẹkọọ naa to jẹ obinrin lo pọ ki ọkan ninu wọn.

Àwọn òbí, akẹ́gbẹ́ àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé ní Kaduna bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de l'Abuja

Awọn oluwọde l'Abuja

Pẹlu bi jiji awọn akẹkọọ gbe ni ipinlẹ Kaduna ti ṣe di eyi ti gbogbo agbaye n ko aya soke sii bayii, awọn obi ati alagbatọ awọn akẹkọọ ileewe giga fun ẹkọ nipa akoso igbo, Federal College of Forestry mechanisation ti bẹrẹ iwọde ni ilu Abuja loni.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC lọwọ, awọn obi ati alagbatọ awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe naa ni awọn n wọde lọ si ileegbimọ aṣofin apapọ orilẹede Naijiria to wa nilu Abuja lati pe fun igbesẹ kanmọnkia lori itusilẹ awọn akẹkọọ naa.

Ileewe Federal College of Forestry mechanisation

Ni oṣu kẹta ọdun 2021 lawọn agbebọn kan ya wọ ileewe naa to wa lagbegbe Mando ni ilu Kaduna nibi ti wọn ti ji ọgbọn akẹkọọ ti ẹnikẹni ko si mọ ibi ti wọn ko wọn lọ.

Lẹyin eyi ni awọn agbebọn naa beere fun owo itusilẹ lori awọn akẹkọọ naa eleyi ti ijọba ipinlẹ Kaduna ni awọn ko lee san owo itusilẹ fun awọn ajinigbe.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ṣalaye nigba to n fesi lori ijinigbe to gogo ni ipinlẹ naa pe sisan owo itusilẹ fawọn ajinigbe di eewọ labẹ iṣakoso oun.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Àkọlé fídíò, Tóò bá fẹ́ràn àti máa pọ́n ọ̀rọ̀ tàbí èèyàn lé, ẹ̀kọ́ ráńpẹ́ yìí yóò wúlò fún ọ